Ilé-ẹjọ́ dá gbajúmọ̀ Dókítá oníṣẹ́-abẹ ìdí lẹ́bi l’Ekoo

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/MEDCONTOUR
Ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa n’Ikoyi, nipinlẹ Eko ti da gbajumọ obinrin oniṣẹ-abẹ idi ati ọmu, Aanu Adepọju tawọn eeyan mọ si Dokita Aanu lẹbi lori ẹsun pe akoba ni iṣẹ abẹ to n ṣe n fa fawọn onibaara rẹ.
Ọgba agba tẹlẹ fun ajọ to n ri si idaboo bo awọn onibaara lorilẹ-ede yii, ‘Federal Competition and Consumer Protection Commission’ (FCCPC), Amofin Babatunde Irukera lo sọ eyi di mimọ lọjọ Ẹti, loju opo X rẹ.
Ẹsun marun-un ọtọọtọ ni ajọ FCCPC fi kan Dokita Aanu ti orukọ ileeṣẹ rẹ n jẹ MedContour Services Ltd.
Ninu rẹ ni pe ilana to n gba ṣiṣẹ abẹ ti yoo mu idi ati ọmu tobi ko tọna.
Ati pe inira lo n ko ba gbogbo ẹni to ba ṣiṣẹ abẹ fun.
Lọdun 2020 ni wahala bẹrẹ fun Dokita aanu, ọdun naa si tun ni ọkan ninu awọn obinrin to ṣiṣẹ abẹ idi nla fun jade laye latari iṣẹ abẹ naa.
Yatọ Nneka Onwuzuligbo, onibaara Aanu to ku, awọn onibaara rẹ mi-in tun jade lati ṣalaye pe aye awọn ko ri bakan naa mọ latigba tawọn ti sanwo nla ṣiṣẹ abẹ lọdọ Dokita Aanu.
Wọn ni inira alailẹgbẹ to n pa aye awọn lara ni gbogbo ọna lawọn n koju.
‘’Oje oríṣìíríṣìí ló ń jáde lára mi lẹ̀yìn tí mo ṣiṣẹ́ abẹ ìdí ńlá lọ́dọ̀ Dókítà Aanu’’

Oríṣun àwòrán, X/FCCPC
Ọkan ninu awọn eeyan ti wọn kede aikunju oṣuwọn Dokita Aanu lọdun 2020 ni alafẹ obinrin kan, Ọmọtọla Taiwo tawọn eeyan mọ si Omohtee.
Omothee ṣalaye fun BBC nigba naa pe lẹyin oṣu mẹfa toun ti ṣiṣẹ abẹ idi nla lọdọ Dokita Aanu, alaafia ko si foun.
O ni oje ati omi oriṣiiriṣii lo n ti ara oun jade lẹyin iṣẹ abẹ naa, bẹẹ ni irora ti ko ṣee ṣalaye loun n ba ja latari aimọṣẹ Dokita Aanu.
Ọmọbinrin naa fi kun un pe oun kabaamọ iṣẹ abẹ naa.
O ni o ko ba gbogbo igbesi aye oun pata ni.
Bo tilẹ jẹ pe ijọba ti ileeṣẹ MedContour pa lori awọn iṣẹlẹ yii nigba naa, sibẹ, Dokita Aanu pe Omohtee lẹjọ fun ẹsun ibanilorukọ jẹ.
Miliọnu mẹẹeẹdọgbọn naira (25m) lo n beere lọwọ Omohtee lọdun 2020 naa.
Bẹẹ lo fi idaniloju sọrọ nigba naa pe akọṣẹmọṣẹ oniṣẹ abẹ ati ti aṣaraloge loun.
Dr Aanu sọ pe iṣẹ abẹ toun ti ṣe le ni ẹgbẹrun kan, gbogbo rẹ lo si yọri si rere.
Èmi kì í ṣe Dókítà tó ń yí ẹ̀yà ara padà- Dókítà Aanu
Nigba to n ba BBC sọrọ lọdun 2020, Dokita Aanu ṣalaye pe oun ki i ṣe dokita to n yi ẹya ara pada (Plastic surgeon).
O ni dokita aṣaraloge (Cosmetic surgeon ) loun, ati pe iṣẹ abẹ ti yoo mu idi tobi si i ti yoo si duro soke wamu (Liposuction) loun n ṣe.
‘’ Ẹni to ba fẹẹ jẹ oniṣẹ abẹ aṣaraloge gbọdọ niwe-ẹri ta a n pe ni MBBS.
‘’ Emi ti kẹkọọ lati gba iwe-ẹri, mo si kunju oṣunwọn lati ṣiṣe abẹ nilana iṣaraloge’’
Bẹẹ ni Dokita Aanu ṣalaye fun BBC lọdun 2020.
Bawo lọrọ ṣe dele-ẹjọ?

Oríṣun àwòrán, Babatunde Irukera@X
Oṣu keje ọdun 2020 ni ijọba Naijiria mu Dokita Aanu, ẹsun ti wọn fi kan an ni pe ko fọwọsọwọpọ pẹlu ijọba lori ẹsun aikunju oṣunwọn tawọn eeyan fi n kan an.
Wọn fi kun un pe Aanu ko dahun ohun ti wọn n beere lọwọ rẹ, ko si jẹ ki iwadii rọrun lati ṣe.
Ṣaa, lẹyin ọdun mẹrin ti ọrọ naa ti wa nilẹ, Amofin Irukera ti i ṣe ọga FCCPC tẹlẹ, sọ lọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlogun oṣu karun-un 2024, pe kootu ti fidi ẹ mulẹ pe Dokita Aanu jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
Irukera sọ pe, ‘’Idajọ le pẹ, ṣugbọn dandan ni ka ri opin ẹ. Dokita Aanu Adepoju ati ikọ̀ oniṣẹabẹ rẹ ti jẹbi ẹsun marun-un tile-ẹjọ fi kan wọn’’














