"Ta ni ọ́ láti dá wa lẹ́jọ́ pé ara wa dọ̀tí torí a ya Tatoo, ìwúrí ni fún ọ̀pọ̀ èèyàn?"
Ni aye atijọ, eewọ ni fun awọn obinrin Thai lati ya aworan Tattoo sara.
Sugbọn lasiko yii, ọpọ wọn lo ti n ya aworan yii si ara, ti ko si dun mọ awọn eeyan kan ninu.
Lara awọn ohun tawọn obinrin naa ya si ara ni akọ maalu, agbanrere, ọpọlọ, alangba ati bẹẹ lọ.
Awọn obinrin naa, ti diẹ lara wọn ba BBC sọrọ ni ko yẹ ki awọn eeyan maa da awọn lẹjọ tori pe awọn ya tattoo.

"Ọpọ̀ awọn to n bu wa lo ni ẹgbin ni tattoo ti a ya sara nitori pe o dabi ẹgbin lori awọ pupa wa.
Amọ awọn eeyan miran ni aworan ti a ya si ara naa jẹ iwuri fun awọn, ti wọn si ni ka mu awọn lọ sibi ti a ti ya a."
Ọ̀pọ̀ àwọn obinrin yii lo ni o ti to ọdun mẹrinla , mẹjọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ti awọn ti ya Tattoo naa.
Bakan naa ni wọn ni o si wu awọn lati ya ọpọ Tattoo naa si ara awọn sugbọn ko si aaye mọ ni agọ ara awọn.







