Èèyàn kan sin ọmọ ìkókó láàyè, ó rò pé ìṣù ni

Aworan ọmọ ikoko ti wọn sin laaye

Oríṣun àwòrán, KINGSLEY IDONGESIT/BBC

Ori ti ko ọmọ ikoko kan yọ lẹyin ti eeyan kan gbe sinu ilẹ laayẹ pẹlu erongba pe iṣu ni ọmọ naa jẹ.

Abule Anshav Kusuv ni iṣẹlẹ naa ti waye nigba ti awọn ọdẹ aṣọgbo sawari ọmọ naa.

Abule yii jẹ abule kan to wa ni Tyowanye nipinlẹ Benue ni apa ariwa orilẹede Naijiria.

Awọn ọdẹ yii lo hu ọmọ sita nigba ti awọn aja ti wọn mu dani gbọ oorun pe nnkan n mi ninu ilẹ ti wọn gbin iṣu si.

Ohun iyalẹnu ni pe wọn ba ọmọ naa laaye, sugbọn ti ko mii daada.

"Bi aja ṣe n gbo tori oorun eemi ọmọ ninu ilẹ, ni awọn ọlọdẹ bẹrẹ si hu ilẹ pẹlu erongba pe wọn n hu iṣu sita"

Ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa ni Tyowanye, ASP Tooga Lorlumun ni wọn ko ti wa fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti sugbọn ọrọ naa ti n lọ kaakiri ori ayelujara.

Tooga sọ fun BBC pe bi aja ṣe gbọ oorun ọmọ ni awọn ọlọdẹ bẹrẹ si ma hu ilẹ pẹlu erongba pe wọn n hu iṣu sita.

“Nigba ti wọn ri pe ohun ti awọn n hu yii ki ṣe iṣu ni wọn fi farabalẹ gbẹlẹ, ti wọn si ri pe eeyan ni,”

Ọmọ ikoko naa ti ko ni orukọ lo ti n gba itọju ni ile iwosan abẹle kan ni abule naa, to n si gbiyanju lati wa laaye.

Ọkan lara awọn to n tọju ọmọ naa, Emmanuel Numbur ni obinrin ni ọmọ jẹ, to si bu ẹnu atẹlu ile iwosan ti ọmọ naa ti n gba itọju pe o ku diẹ kato.

O ni irufẹ itọju ti ọmọ naa nilo ni wọn ko le fun ni ile iwosan.

Numbur ṣalaye bi o ṣe nira lati ṣe itọju ọmọ nitori ai si owo lọwọ rẹ.

“Ipo ti ọmọ naa wa ko dara rara,” Numbur ṣalaye bi o ṣe n pr iranlọwọ kiakia fun ọmọ naa.