₦48,000 owó oṣù tó kéré jùlọ tíjọba fẹ́ san fún òṣìṣẹ́ tàbùkù wá - Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fọnmú

Oríṣun àwòrán, NIGERIA LABOUR CONGRESS/X
Ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria NLC ati TUC ni wọn ti koroju si aba ijọba apapọ, ti wọn si binu jade lasiko ipade wọn to waye lọjọru.
Ohun to fa ibinu naa wa nipa iye ti owo oṣu osisẹ to kere ju lọ yoo jẹ.
Ẹgbẹrun mejidinlaadọta Naira ni iye owo oṣu to kere ju ti ijọba apapọ gbe kalẹ fun awọn ẹgbẹ osisẹ pe oun lagbara lati san.
Amọ awọn osisẹ koro oju si igbesẹ naa, ti wọn si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii iwọsi, ti wọn si binu jade.
Aarẹ NLC, Joe Ajaero ṣalaye pe ijọba apapọ ko ti ṣetan lati duna dura nipa iye owo oṣu to kere ju yoo jẹ.
O fikun pe ijọba apapọ ko ni oye to kun to lati ba ẹgbẹ oṣisẹ sọrọ.
Ajaero wa jẹ ko di mimọ pe, ẹgbẹ osisẹ ko ni yi ohun rẹ pada, ti ijọba apapọ si ni di ipari oṣu ti a wa yii lati gbe igbesẹ to yẹ.
“Awọn ileeṣẹ aladani OPS pinnu lati san N54,000, bo tilẹ jẹ pe owo oṣu to kere ju ni ileeṣẹ aladani ni N78,000"
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ osisẹ NLC ati TUC buwọlu fun awọn akọroyin lẹyin ipade naa, wọn ni;
“Owo oṣu to kere ju ti ijọba apapọ pinnu lati san ni N48,000, eyi tabuku si wa gẹgẹ bii osisẹ Naijiria, ti ko si le tan iṣoro awọn osisẹ lasiko yii
“Awọn ileeṣẹ aladani OPS pinnu lati san N54,000, bo tilẹ jẹ pe owo oṣu to kere ju ni ileeṣẹ aladani ni N78,000.
“Siwaju sii, ijọba apapọ kuna lati pese awọn ẹri fun ohun ti wọn gbe kalẹ nipa owo oṣu to kere ju.
“Gẹgẹ bii aṣoju osisẹ Naijiria, a ko le tẹwọgba awọn owo nitori ko pon wa le.”
Ki lo ti saaju laarin ijọba apapọ ati ẹgbẹ osisẹ?
Ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Naijiria fun ijọba apapọ ni gbedeke ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Karun un yii lati fẹnuko lori N615,000 t'awọn oṣiṣẹ n beere fun.
Awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ sọrọ yii nibi ayajọ ọjọ awọn oṣiṣẹ lọjọ kinni oṣu Karun un ọdun 2024.
Lasiko ti ayẹyẹ ayajọ ọjọ oṣiṣẹ n lọ lọwọ niluu Abuja ni ẹgbẹ oṣiṣẹ sọ koko mejidinlogun ti awọn n fẹ ki ijọba ṣe, eyi ti N615,000 gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ jẹ ọkan gboogi lara wọn.
Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, Joe Ajaero ati Festus Osifo ti ẹgbẹ TUC fi aidunnu wọn han lori bi igbe aye awọn oṣiṣẹ ko ṣe rọrun ni bii ọdun kan sẹyin.
Wọn ni N30,000 owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ ti ijọba n san tẹlẹ ti dopin lati ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹrin to kọja labẹ ofin.
Wọn ni o ti yẹ ki ijọba ti bẹrẹ si ni san owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ bayii.
Awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ naa ni awọn ko ni gba owo to din ni N615,000 gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.
"N615,000 ni owo to le to fun awọn oṣiṣẹ lati gbe iye aye to gbadun pẹlu bi nnkan ṣe wọn gogo bayii.
A ti jiroro lori bi nnkan ṣe ri ni Naijiria, a ṣi ti ri pe N615,000 lo le to oṣiṣẹ ti ipo rẹ kere julọ na loṣu kan.
Awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ ni arumọjẹ lasan ni afikun 25% ati 35% ti ijọba apapọ kede, wọn ni owo osu to kere julọ tawon n beere fun lo ṣe koko.















