Mi ò jẹ̀bi ẹ̀sùn fífi owó N18.96bn tẹ N684m – Emefiele

Emefiele joko si aarin awọn agbẹjẹro

Oríṣun àwòrán, others

Gomina banki apapọ Naijiria tẹlẹ, Godwin Emefiele, ti sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun pe oun na owo ti iye rẹ to N18.96bn lati tẹ owo to jẹ N684m.

Emefiele tun ti foju bale ẹjọ lọjọru, ọjọ karundinlogun, oṣu Karun un, ọdun 2024 yii lori ẹsun ti EFCC fi kan an.

Ẹsun ti Emefiele n jẹjọ rẹ lọtẹ yii niwaju adajọ Maryann Anenih ni titẹ owo naira lọna ti ko ba ofin mu ati gbigba owo jade lọna aitọ.

Gẹgẹ bii ẹsun ti EFCC fi gomina CBN ana ọhun, o tapa si ofin to gbe CBN kalẹ latari pe o tẹ owo naa lai gba aṣẹ lọwọ Aarẹ Naijiria.

Ṣugbọn agbẹjọro afurasi naa ti rọ ile ẹjọ ko gba beeli rẹ nitori ẹni iyi ti ko le salọ lawujọ ni.

O ni ẹsun ti wọn fi kan onibara oun kii ṣe eyii ti wọn ko le gba beeli rẹ, ati pe kii ṣe ọdaran labẹ ofin titi di igba ti ile ẹjọ ba ṣedajọ rẹ, to si pe e ni arufin.

O fi kun pe ko si igba ti ẹjọ ba kan Emefiele ti kii yọju sile ẹjọ, nitori naa, ko ni na papa bora ti wọn ba fun ni beeli.

Ẹsun yii kii ṣe igba akọkọ ti ijọba yoo fi kan Emefiele to wa nipo gomina CBN fun nnkan bii ọdun mẹwaa gbako.

Ọkunrin kan ṣoṣo, ẹsun mẹrin, beeli N350 miliọnu

Ẹsun akọkọ ti wọn fi kan Emefiele ni pe o ni ohun ija oloro bii ibọn lọwọ lọna aitọ.

Lẹyin atotonu nilẹ ẹjọ, adajọ gba beeli rẹ pẹlu ogun miliọnu naira amọ ajọ DSS kọ lati tu silẹ ni ahamọ.

Nigba ti yoo di inu oṣu Kejila, ọdun 2023, EFCC fi ẹsun kan afurasi naa pe o ra ọkọ ayọkẹlẹ mẹtalelogoji laarin ọdun 2018 si 2020, ti iye owo awọn ọkọ naa to N1.6b, wọn gba beeli rẹ pẹlu N300m.

Ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2024, EFCC tun fi ẹsun mii kan ọkunrin ọhun ati ẹlomii ti orukọ rẹ n jẹ Henry Omoile lori magomago owo ti iye rẹ to $4.57b, wọn gba beeli rẹ pẹlu N50m.

Ẹsun kẹrin ti wọn fi kan Emefiele ni eyii to jẹjọ rẹ lonii Ọjọru nile ẹjọ giga to wa ni Maitama, niluu Abuja.

Ẹwẹ, ọpọ ọmọ Naijiria ni oju wọn koro si Emefiele latari bo ṣe ko owo naira pamọ lẹyin to tẹ owo tuntun mii ni ipari ọdun 2022 si ibẹrẹ ọdun 2023.

Àkọlé fídíò, Oníbẹ̀jù ní àwọn fẹ́ sọ ojúbọ àwọn igi náà di ilẹ̀ mímọ̀ àti ibúdó ìgbafẹ́
Aworan Gomina banki apapọ tẹlẹ, Godwin Emefiele

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ajọ to n gbe ogun ti iwabajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC tun ti wọ gomina tẹlẹ fun banki apapọ CBN lorilẹede Naijiria, Godwin Emefiele lọ siwaju ileẹjọ giga to n jokoo ninu Abuja fun awọn ẹsun ọdaran mii.

Emefiele yoo tun ma wi tẹnu rẹ niwaju Onidajọ Maryann Anenih sugbọn lasiko yii, yoo ma jẹjọ lori ẹsun ọdaran mii lori pe o tẹ owo sita lọna aitọ, to si gbe owo sita lọna ti ko ba ofin mu .

Gẹgẹ bii EFCC ṣe salaye, Gomina Banki apapọ tapa sofin banki apapọ CBN nigba to buwọlu titẹ owo to to N684.5m fun owo to le ni bilọnu mejidinlogun naira lai gba aṣẹ lọwọ Aarẹ orilẹede Naijiria.

Eyi kii ṣe ẹsun akọkọ to wa lọrun Emefiele to jẹ ọga agba fun banki apapọ CBN lati oṣu kẹta ọdun 2014 si oṣu kẹfa ọdun 2024.

Ọkunrin kan, ẹsun ọdaran mẹrin ati ọpọlọpọ owo beeli

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹsun akọkọ ti wọn fi kan Emeifiele ni pe o n ṣe iṣakoso awọn ohun ija oloro, ti Ajọ DSS si wọ lọ siwaju Onidajọ Nicholas Oweibo ni ile ẹjọ to ga ju lorilẹede Naijiria to wa niluu Eko lọdun 2023.

Wọn fa ẹjọ naa gun ti Onidajọ Oweibo ti buwọlu beeli Emefiele pẹlu ogun milọnu sugbọn ajọ DSS kọ lati fi silẹ ni ahamọ.

Nigba to di ninu oṣu kọkanla ọdun 2023, Ajọ EFCC fẹsun mẹfa kan Emefiele niwaju Onidajọ Hamza Muazu ni ile ẹjọ giga niluu Abuja, nibi ti wọn ti fẹsun kan pe o ra ọkọ ayọkẹlẹ mẹtalelogoji laarin ọdun 2018 si ọdun 2020, ti apapọ owo rẹ si jẹ N1.6bn.

Onidajọ Muazu naa gba beeli Emefiele pẹlu owo toto N300m atI oniduro meji.

Nigba to di ninu oṣu kẹrin, Emefiele tun fi=oju ba ile ẹjọ niluu Eko niwaju Onidajọ Rahamn Oshodi nibi ti EFCC ti fẹsun kan oun ati Henry Omoile pe owo ilu to le bilọnu mẹrin dọla ati owo mi to tun le ni bilọnu meji naira mọkumọku.

Lẹẹkan si, Onidajọ Oshodi gba beeli Emefiele pẹlu Aadọtaa milọnu naira.

Ẹsun kẹrin ni Emefiele yoo jẹjọ niwaju ile ẹjọ lonii niwaju Onidajọ M. Anenih NILUU Abuja.