Akọ̀wé ìjọba Améríkà, Blinken, balẹ̀ sí Ukraine bí Russia ṣe fẹ́ ya wọ ìlú ńlá míì

Aworan Anthony Blinken ati Volodymyr Zelensky

Oríṣun àwòrán, Reuters

Akọwe ijọba orilẹede Amerika, Anthony Blinken ti balẹ si Ukraine bi Amẹrika ṣe n ko nnkan ijagun wọlé lati ṣe iranwọ fun Ukraine.

Asiko ti Blinken n ṣabẹwo si Ukraine yii ni asiko ti awọn ọm'ogun Russia fẹ wọ Kharkiv ti i ṣe ilu to tobi ṣikeji lorilẹede Ukraine.

Ija to n waye laarin awọn ọm'ogun Ukraine ati Russia ni ibode ilu Kharkiv jẹ ọkan lara gbagede ija to le julọ lati igba ti ogun naa ti bẹrẹ.

Ẹwẹ, akọwe ileeṣẹ ologun orile-ede UK, Grant Shapps sọ fun BBC pe o dabi ẹni pe gbogbo agbaye ti gbagbe pe Ukraine nilo iranwọ ohun ija.

O ti pe ọsẹ mẹta bayii ti ile aṣòfin agba ilẹ Amẹrika buwọlu $61bn gẹgẹ bi owo iranwọ fun Ukraine.

Leyin to balẹ si Ukraine tan, Blinken ti ṣepade pọ pẹlu aarẹ orilẹede naa, Volodymyr Zelensky.

Blinken sọ fun Zelensky pe orilẹede Ukraine to duro daadaa jẹ ibawi fun aarẹ Wladimir Putin Russia.

Ni ileeṣẹ aarẹ, Bankova, to wa niluu Kyiv ni ipade ọhun ti waye laarin awọn mejeeji lonii ọjọ Isẹgun ọjọ kẹrinla oṣu Karun un ọdun 2024.

Aarẹ Zelensky ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe asiko to le ni asiko fawọn ọmogun Ukraine papaa julọ awọn to wa lẹkun ila oorun orilẹede naa.

Zelensky dupẹ lọwọ Blinken fun iranwọ ti ile asofin Amẹrika buwọlu fun Ukraine laipẹ yii.