Àwọn obìnrin fọ́nmú bí Alfa obìnrin, Kafilat Kaola ṣe wọ́ Saheed Shittu lọ sílé ẹjọ lórí ẹ̀sùn àgbèrè àti ríra ọmọ

Oríṣun àwòrán, Facebook/KAOLA MEDIA
L’Ọjọ, Aje, Mọnde, ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, nile-ẹjọ Upper Area, to fi ilu Ilọrin ṣe ibujokoo tẹsiwaju lori ẹjọ ti Alhaja Kafilat Ahmad Rufai, ti ọpọ mọ si Iya Kaola, pe Saheed Shittu.
Saheed Shittu ni Alhaja Kafilat ti ọpọ mọ Kaola pe lẹjọ fun ẹsun ibanilorukọjẹ, ti Ileẹjọ si ni ki olujẹjọ wa dahun awọn ibeere lori ẹsun naa, ko si tun wa wi tẹnu rẹ.
Iyalẹnu lo jẹ nigba ti ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan kan, ti wọn pe orukọ ara wọn ni Alliance Against Domestic Abuse and Sexual Violence, ya bo ile ẹjọ, ti wọn si se ifẹhonuhan ninu ọgba ile-ẹjọ lati ṣe atilẹyin fun Alhaja Kafilat.
Gẹgẹ bi iwe ipẹjọ ṣe gbe e kalẹ, Saheed Shittu lo lọ sori ayelujara to si n sọ fun gbogbo aye pe alagbere ni Alhaja Kafilat ati pe o lọ ṣagbere nilu Abuja.

"A fẹ ki Saheed Shittu wa sọ igba ati asiko ti Alhaja Kaola ṣe agbere ni Abuja ibi to ti n ra ọmọ"
Bakan naa ni o tun sọ pe ọmọ mejeeje ti olupẹjọ bi saye, ki i ṣe oun lo bi gbogbo wọn, o ra wọn ni.
Ninu iwe ipẹjọ naa, Alhaja Kafilat, ni ki Saheed Shittu, wa ṣalaye ọjọ ti oun ṣe agbere nilu Abuja, ẹni ti oun ba ṣe agbere ati akoko ti oun ṣe agbere naa.
O tun ni ki olujẹjọ naa wa ṣalaye lẹkunrẹrẹ ọdọ ẹni ti oun ti n ra ọmọ.
Nigba to n ba BBC News Yoruba, ṣọrọ, alaga ẹgbẹ Alliance Against Domestic Abuse and Sexual Violence, Dokita Ibadat Ranti Lawal, ni ijọba gbọdọ mu Saheed Shittu ni gbogbo ibikibi to ba farapa mọ si, ko si wa ṣalaye ara rẹ lori bo ṣe n ba olupẹjọ, Alhaja Kafilat lorukọ jẹ.
O ni awọn fẹ ki Saheed Shittu wa sọ igba ati asiko ti olupẹjọ ṣe agbere niluu Abuja, ko si ṣalaye lẹkunrẹrẹ nibi ti Alhaja Kafilat ti n ra ọmọ.
" Ẹ wa saheed Shittu jade nibi to ba wa"
O wa rọ ijọba ipinlẹ Kwara ati ijọba apapọ lati wa Saheed Shittu jade ni gbogbo ibi to ba wa ko si foju wina ofin.
Tẹ o ba gbagbe, ṣaaju ni ile-ẹjọ ti paṣẹ fun awọn ọlọpaa lati mu Saheed Shittu, ki wọn si wọ ọ wa si ile-ẹjọ nigba ti ko ti yọju fun ara rẹ
Bakan naa ni ibi igbẹjọ to waye ni ọjọ Aje, Saheed Shittu ko tun yọju si ile-ẹjọ, ti agbẹjọro rẹ naa ko si tun yọju lati duro fun un ṣugbọn o ran ẹni kan wa.
Lẹyin awuyewuye àwọn agbẹjọro, Onidaajọ Sunday Adeniyi, sun igbẹjọ mi-in si ogunjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii.
Saheed Shittu yii kan naa lo tun n jẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti ẹgbẹ Association of Proud Sons and Daughters of Ilorin (Ogo Ilorin) fi kan-an.
















