Ọwọ́ tẹ 32 awakùsà lọ́nà àìtọ́ l'Oyo

Oríṣun àwòrán, Oyo Deouty Gov Media
Ijọba ipinlẹ Oyo ti kede sita pe ọwọ ti tẹ eeyan mejilọgbọn pẹlu awọn ọmọ ilẹ China meji mii lori ẹsun pe wọn n wa kusa lọna aitọ ni ọja Sooro niluu Kishi nijọba ibilẹ Irepo.
Olori ikọ Operation Burst nipinlẹ Oyo, Col James Oladipo Ajibola lo kede eyii fun awọn akọroyin lẹyin ipade to ṣe pẹlu igbakeji Gomina ipinlẹ Oyo, Amofin Bayo Lawal ni ọọfisi Gomina ni Agodi.
Saaju ni Igbakeji Gomina ti kọkọ lọ si Kishi lati bẹrẹ ipolongo pe awọn ko fẹ awọn awakusa lọna aitọ mọ ni agbegbe naa ati ninu ọja Sooro lọjọ Kejila oṣu karun un ọdun 2024.
Ajibola ṣalaye pe ifọwọsowọpọ awọn olori ilu ati awọn ẹsọ alabo yooku ni o jẹ ki mimu awọn awakusa lọna aitọ ṣeeṣe , ti alaafia si ti jọba pada ni agbegbe naa.
“O le ni eeyan mejilelọgbọn pẹlu awọn meji lati orilẹede China ti ọwọ tẹ to n wa kusa lọna aitọ ni Ọja Sooro ni Kishi, ti iwadii ti bẹrẹ lori wọn.”

Oríṣun àwòrán, Oyo Deouty Gov Media
"Ẹ yago fun didabobo awọn awakusa lọna aitọ to n dunkoko mọ ẹmi ati dukia ni agbegbe yin"
Ijọba ipinlẹ Oyo tun wa ṣe ikilọ fun awọn olugbe agbegbe Kishi ati ayika rẹ lati yago fun didabo bo awọn awakusa lọna aitọ to n dunkoko mọ ẹmi ati dukia ni agbegbe naa ati nipinlẹ Oyo lapapọ.
Oluranlọwọ agba fun Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lori eto abo, CP Sunday Odukoya lo sọ eyi lẹyin to ṣe ipade pọ pẹlu awọn agbagba ilu Kishi.
CP Odukoya ni ijọba ipinlẹ Oyo pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ẹsọ alabo yoo fopin si bi iwakusa ṣe wọpọ nipinlẹ Oyo.
“A ṣe ipade lori eto abo lori ohun to n ṣẹlẹ nipa iwakusa ni agbegbe Oke-Ogun, paapa ni Sooro ni ijọba ibilẹ Irepo.
“Ijọba ti n gbe igbesẹ, ti o si jẹ pe gbogbo eeyan lo ni lati dide ja lati fopin si bi iwa yii ṣe wọpọ ni agbegbe Kishi.”
Iba ti ilu Kishi, Oba Mashoud Lawal ṣe ileri fun awọn araalu pe gbogbo ohun to n jẹ iwakusa lọna aitọ yoo jẹ ohun igbagbe laipẹ niluu Kishi.
O jẹ ko di mimọ pe ijọba ko ni dẹkun riri pe iwa ibajẹ ati iwa ọdaran fori sanpọn ni agbegbe Kishi.

Oríṣun àwòrán, Oyo Deouty Gov Media















