Wo igi mẹ́ta tí wọn ń bọ ní Ibeju-Lekki, ó máa ya lulẹ̀ bí Ọba bá wàjà, ẹni tó bá fọwọ́ kàn -àn, yóò gbẹ, àdúrà tàbí èpè níbẹ̀ yóò wá sí ìmúṣẹ
Amọ bi ilu yii ti gbajumọ to, igi mẹta kan wa nilu naa, ti wọn kii fi wọn sere, ti wọn si maa n bọ wọn bii orisa.
Lasiko ti BBC Yoruba se abẹwo silu Ibeju-Lekki, a gbọ pe awọn igi mẹtẹẹta naa ti le ni igba ọdun.
Amọ ko sẹni to le sọ boya awọn eeyan to da ilu naa silẹ lo gbin awọn igi ọhun tabi wọn ba awọn igi naa nilu naa lasiko ti wọn rin de ibẹ lati ilu Ile Ife.
Awọn igi naa si lo maa n wa ninu oriki awọn ọmọ bibi ilu Ibeju Lekki.
Wọn a ki wọn ni “Ọmọ igi mẹta, ikan n sowo, ikan n so iyun, ọkan n so Alaari baba asọ.
Onibẹju ti Ibeju-Lekki ati awọn eeyan ti itọju awọn igi ọhun kan ba BBC Yoruba sọrọ nipa awọn ohun abami nipa awọn igi yii ati idi ti wọn fi se pataki si ilu naa.

Ẹni to ba fi ọwọ kan igi yii, yoo gbẹ ni, awọn oyinbo to wa dan wo, wọn gbẹ ni – Onibẹju
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Kabiyesi Onibẹju ti Ibẹju-Lekki, Ọba Waliu Razak salaye pe igi mẹtẹẹta yii lo se apejuwe ilu Ibeju Lekki ati oriki rẹ.
Ọba Razak ni oun ko mọ boya awọn babanla awọn lo lọ awọn igi naa tabi wọn ba wọn nibẹ.
“Igi kan wa laarin awọn igi mẹtẹẹta yii, ti ẹnikẹni ko gbọdọ fi ọwọ kan, ẹni to ba fi ọwọ kan, ọwọ naa yoo lẹ mọ igi naa lara, ti yoo si gbẹ ni.
Bi wọn ba si lẹ oko mọ igi naa, oko yẹn maa lẹ mọ lara ni.
Koda, mo ti gbadura nidi igi naa ri, ti ohun ti mo beere si sẹ.
Ọkunrin India kan wa wo igi naa, to si ni a ko mọ iyi ohun ti a ni. O wa gbaaye lọwọ mi lati maa gbadura labẹ igi naa.
Afojusun wa lọjọ iwaju ni ka sọ igi naa di ilẹ mimọ, ti awọn eeyan too ti maa gbadura sawọn igi naa.
A si tun n gbero lọjọ iwaju lati fi ibudo awọn igi mẹtẹẹta naa se ibudo igbafẹ ti awọn arinrinajo afẹ yoo maa ya wa wo."

Bi ọba ba waja, tabi ti isẹlẹ nla kan ba fẹ waye, ẹka igi naa yoo la lulẹ lati kede isẹlẹ naa – Adelaja Adedayo
Ninu ọrọ tiẹ naa pẹlu BBC Yoruba, Ọmọọba Adelaja Adedayo salaye pe awọn igi mẹta yii duro fun idile mẹta to n jọba nilu Ibeju Lekki.
Awọn idile mẹtẹẹta naa ni idile Abejoye, Oniwọnlu ati Ladesesan.
Bakan naa ni Ọmọba Adelaja fikun pe ti ọba ilu naa ba waja tabi to fẹ papoda, ẹka igi naa yoo ya silẹ, ti gbogbo oju yoo si ri.
“Bi ẹka igi naa ba ti ya silẹ, o n kede fun wa pe isẹlẹ nla kan fẹ sẹlẹ ninu ilu naa ni tabi pe Kabiyesi wa fẹ waja.”

Eewọ ni lati de idi igi yii tabi fi ọwọ kan tabi sọ oko lu, ọmọ to se bẹẹ , se etutu, ko to ma ku – Adeniran Agbabiaka, Odimoro ti Ibaju
Se ẹni to moju ogun, lo n pa obi nire. BBC Yoruba ba ọkan lara awọn to n se akoso ojubọ awọn igi yii sọrọ lati mọ eewọ ati anfaani wọn.
Odimoro ti ilu Ibeju Lekki, Adeniran Agbabiaka salaye fun BBC Yoruba pe aaro mẹta ni awọn igi naa, ti wọn ko si gbọdọ da ọbẹ nu.
O ni ọkan n so owo, ikeji n so iyun, ikẹta si n so Alaari, baba asọ.
“Eewọ ni lati de idi igi ipọn yii, ẹni to ba de ibẹ maa gbẹ, aye igba tawọn oyinbo wa lati dan wo, wọn gbẹ sidi rẹ ni.
Wọn ko gbọdọ sọ oko lu tori rẹ la fi mọ odi yii ka. O jẹ eewọ fun ilu, awọn ọmọde naa ko si gbọdọ sere nidi igi yii.
Ọmọde kan sọ ikarahun igbin lu igi naa, se lo n gbọn pẹpẹ, awọn obi rẹ tọ awọn baba to n sakoso igi naa wa, ti wọn si se etutu fun, ni ikarahun naa fi jabọ.
Ọmọ mii to na ọwọ si igi naa wipe iwọ igi yii.., n se radarada ni afi igba ti wọn se etutu fun ni aye rẹ to ni ojutu.
Koda, bi eeyan ba sẹ, ti wọn ba mu wa sidi igi yii, yoo fi ẹnu rẹ jẹwọ ohun to se.
Koda, bi eeyan ba sepe, tabi gbadura si igi yii, ohun to ba beere yoo sẹ kankan.,”







