Ijọba àpapọ̀ fún ẹbí Alàgbà Akinkunmi tó ṣe asia Naijiria ní mílíọ́nù lọ́nà ọgbọ̀n náírà

Sowedowo ti ijọba apapọ fun ẹbi Oloogbe Akinkunmi

Oríṣun àwòrán, National Orientation Agency/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti fi ẹbun owo ti iye rẹ jẹ ọgbọn Milliọnu Naira ṣọwọ si mọlẹbi Oloogbe Taiwo Akinkunmi, to ṣe agbekalẹ asia orilẹede Naijiria, lẹyin ọdun meji to jade laye.

Alakoso ẹka ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si Ilanilọye, 'National Orientation Agency, NOA', Lanre Issa-Onilu; to kọwọrin pẹlu alaga ajọ naa n'ipinlẹ Ọyọ, Olukemi Afolayan, lo kede ẹbun owo naa l'Ọjọbọ, lorukọ ijọba apapọ orilẹede Naijiria.

Eyi waye nile Oloogbe to n wa lagbegbe Ẹlẹbu, niluu Ibadan.

Ninu ọrọ ọga agba NOA, o ni owo ti ijọba apapọ fun mọlẹbi Oloogbe naa ki i ṣe owo ọya fun awọn iṣẹ to ṣe nigba aye rẹ, bi ko ṣe lati ṣe iranlọwọ fun ẹbi rẹ nitori ipa rere to ko lorilẹede yii.

Wọ́n fún wa lówó náà lóòótọ́ - Ọmọ Olóògbé

Aworan awon to gbe Sowedowo naa dani, ati aworan Oloogbe Taiwo Akinkunmi

Oríṣun àwòrán, NOA /X Akinwumi Samuel/ Facebook

BBC Yoruba kan si ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe, Ọgbẹni Akinwunmi Akinkunmi, lori igbesẹ ijọba apapọ.

Alaye to ṣe fun akọroyin wa ni pe, "Loootọ ni wọn fun wa lowo. A tiẹ ti ro pe wọn ti gbagbe wa ni. A dupẹ lọwọ ijọba gidi gan an".

Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ ọdun 2023 ni Alagba Akinkunmi jade laye, ni ẹni ọdun mẹtadinlaaadọrun-un.

Ọjọ kẹrin, oṣu Kẹsan an ọdun kan naa si ni Aarẹ Bọla Tinubu ran Minisita fun iroyin ati ilaniọyẹ, Mohammed Malagi, lati lọọ ṣe abẹwo ibanikẹdun sile oloogbe naa.

Lasiko abẹwo yii ni ijọba apapọ ṣeleri lati fun Oloogbe ni eto isinku to wuyi, ati owo iranwọ fun mọlẹbi rẹ.