Òkú fọ́n ká ojú pòpò bí ìkọlù ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀ ṣe ń peléke ní DR Congo

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ààrẹ orílẹ̀ èdè Democratic Republic of Congo, Félix Tshisekedi ti ní òun kò ní kópa nínú ìtàkurọ̀sọ lórí fífi òpin sí ìkọlù àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ sí ìlà oòrùn ìlú Goma.
Ààrẹ Kenya, William Ruto ló ti ṣáájú ránṣẹ́ pe Tshisekedi àti ààrẹ Rwanda, Paul Kagame fún ìtàkurọ̀sọ lórí ayélujára láti jíròrò lórí bí wọ́n ṣe máa fòpin sí ìkọlù àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ M23.
Níṣe ni òkú àwọn èèyàn sùn ní ojú pópó ní ìlú Goma látàrí ìjà ńlá tó wáyé láàárín iléeṣẹ́ ológun àtàwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ náà.
Àwọn aláṣẹ DR Congo ń fẹ̀sùn kàn Rwanda pé àwọn ló ń ṣe àtìlẹyìn fáwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ M23 tó ti gba àkóso àwọn agbègbè tó pọ̀ ní ìlú náà tó fi mọ́ pápákọ̀ òfurufú tó wà níbẹ̀.
Iléeṣẹ́ ológun Rwanda nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi sórí ìkànnì X wọn sọ pé àwọn ológun aládàni 280 láti Roman tí wọ́n ń ṣègbè lẹ́yìn iléeṣẹ́ ológun DR Congo tẹ́lẹ̀ ni wọ́n ti juwọ́ sílẹ̀ fún M23.
Agbẹnusọ ìjọba Rwanda, Yolande Makolo sọ fún BBC pé Rwanda yóò kópa níbi ìtàkurọ̀sọ náà àmọ́ kò sọ bóyá ààrẹ Kagame máa wà níbẹ̀.
Àjọ ìṣọ̀kan àgbàyé, UN ní àwọn ẹ̀rí tó fojú hàn wà pé Rwanda ń ṣàtìlẹyìn fún M23 ṣùgbọ́n Rwanda fífún àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ náà ní àtìlẹyìn.
Níṣe ni ọ̀pọ̀ agbègbè ní Goma pa lọ́lọ́ ní ọjọ́rú pẹ̀lú ìròyìn pé níṣe ni ìrọ ìbọn ń dún lákọlákọ láwọn ẹkùn kan.
Ọ̀pọ̀ àwọn ará ìlú tó ti fara pamọ́ síbì kan fún ààbò wọn jáde láti wá oúnjẹ tó ti ń di ọ̀wọ́ngógó látàrí ìjà tó ń wáyé ní ẹkùn náà.
Nígbà tó ń bá BBC Newshour sọ̀rọ̀, igbákejì adarí ikọ̀ ọmọ ogun UN, Vivian van de Perre ní àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ M23 ti gbilẹ̀ sí Goma àmọ́ tí ìjọba ṣì ń kọjú oro sí wọn.
Ó ní lẹ́yìn tí òun bá àwọn M23 jíròrò, àwọn apẹ̀tù sááwọ̀ àjọ UN ti bẹ̀rẹ̀ rìn káàkiri agbègbè èyí tó ní ó wáyé kíákíá nítorí ọ̀pọ̀ àwọn ibùdó UN ni kò ti sí oúnjẹ àti omi mọ́ fáwọn èèyàn tó wà níbẹ̀.
Iléeṣẹ́ ìròyìn Reuters ní àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò kan ń sọ pé M23 tún ti ń gbìyànjú láti mú ìgbòòrò bá ẹkùn tí wọ́n ń ṣe àkóso rẹ̀, tí wọ́n sì ti ń sún wọ Bukavu, ìlú kejì tó tóbi jùlọ ní ìlà oòrùn DR Congo. BBC kò ì tíì fìdí ìròyìn yìí múlẹ̀.
Iléeṣẹ́ ìròyìn DR Congo ní Tshisekedi kò ní kópa níbi àpérò àwọn olórí ìlú tí ààrẹ Kenya pè, wọn kò sọ ìdí tí Tshisekedi kò fi ní kópa níbi àpérò náà.
Van de Perre ní òun gbèrò pé ìjà náà kò ní di ohun ẹlẹ́yàmẹ̀yà.
"A ti rí bí ìjà yìí ṣe ń fa inú fu àyà fu láàárín àwọn ẹ̀yà, èyí tó ń dá ìbẹ̀rù bojo sọ́kàn àwọn èèyàn."
Àwọn ẹ̀yà Tutsi ló ń ṣáájú ikọ̀ M23, tí wọ́n sì sọ pé àwọn nílò láti gbé ìbọn lójùnà àti dá ààbò bo ẹ̀tọ́ àwọn ẹ̀yà kéréje ní DR Congo.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ẹ̀yà Tutsi ni ààrẹ Rwanda, tó sì ń fẹ̀sùn kan ìjọba DR Congo pé wọ́n ń kó àwọn alájàǹgbilà Hutu tó ṣokùnfà ìpànìyàn tó wáyé ní Rwanda lọ́dún 1994 sábẹ́.
Àjọ UN ní láti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ yìí, ìkọlù tó wáyé láàárín M23 àtàwọn ológun ti mú kí àwọn ilé ìwòsàn kún fọ́fọ́ látàrí àwọn tó farapa níbi ìkọlù ọ̀hún àti pé òkú èèyàn ti sùn láwọn òpópónà káàkiri.
Ọ̀pọ̀ àwọn ibi tí wọ́n ń kó oúnjẹ pamọ́ sí àti ohun èlò ìlera ni wọ́n ti lọ já.
Láti ìgbà tí ìkọlù náà ti ń wáyé ni kò ti sí àwọn ohun amáyédẹrùn bíi omi, iná mọ̀nàmọ́ná àti ayélujára.
Ìkọlù àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ náà mú kí àwọn olùfẹ̀hónúhàn máa ṣe ìkọlù sáwọn iléeṣẹ́ ilẹ̀ òkèrè tó wà ní olú ìlú Kinshasa.
Kò dín ní àwọn iléeṣẹ́ ilẹ̀ òkèrè mẹ́wàá táwọn olùfẹ̀hónúhàn náà ṣe ìkọlù sí, tí wọ́n sì ń bèèrè kí àwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé dá sí ọ̀rọ̀ náà láti fòpin sí ìkọlù àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ náà.
Iléeṣẹ́ ológun Rwanda ní àwọn ti kó àwọn ọmọ ogun Roman lọ sí Kigali lẹ́yìn tí wọ́n ti sọwọ́ sílẹ̀ fún M23 lẹ́yìn tí wọ́n gba àkóso Goma.
Àmọ́ aṣojú UN kan sọ fún BBC pé àwọn èèyàn Roman náà ṣe àtìpó ní ẹ̀ka UN tó wà ní Goma kí wọ́n tó kó wọn lọ sí Rwanda.
Alákòso àwọn ọmọ ogun Roman, Constantin Timofti sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ òun bíi mẹ́rin ló farapa nínú ìkọlù náà àmọ́ tí ìfarapa náà kò lágbára jùlọ.
Iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè ní Roman lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ní àwọn ọmọ ogun tó lé ní 250 ló ń ṣiṣẹ́ fún ìjọba DR Congo láti ṣe ìdanílẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọmọ ogun wọn.















