Niger, Mali àti Burkina Faso kúrò ní ECOWAS lónìí, wo ohun tí ó yàtọ̀ láàrin wọn àtàwọn orílẹ̀èdè ECOWAS

Olori ologun ni orilẹede Burkina Faso, Ibrahim Traoré, ọgagun Assimi Goita ti Mali ati ọgagun Abdourahmane Tchiani ti Niger

Oríṣun àwòrán, Collage

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Bi orilẹede Niger, Mali ati Burkina Faso ṣe kuro patapata ninu ajọ ECOWAS lonii Ọjọbọ ti di ohun ti o n kọ ọpọ eeyan lominu bayii.

Lonii ọjọ kọkandinlọgbọn osu Kinni ọdun yii ni awọn orilẹede mẹtẹẹta eyi ti ijọba ologun n dari wọn, kede wi pe awọn ti fi ajọ ECOWAS silẹ patapata.

Amọ, ohun to wa ninu òfin ECOWAS ni pe, orilẹede to ba fẹ kuro ninu ajọ naa ti gbọdọ sọ ṣaaju bi ọdun kan si asiko to fẹ kuro ninu ajọ ọhun.

Ọjọru yii gan an ni o pe ọdun kan, ati pe awọn orilẹede mẹtẹẹta yii ti kọ eti ikun si imọran ajọ ECOWAS to ni ko wọn si wa ninu ajọ naa fun osu mẹfa lati le wa ojutuu si aawọ to ṣẹlẹ.

Ni bayii, Niger, Mali àti Burkina Faso ti jọ da ajọ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni AES silẹ eyi t'awọn mẹtẹẹta jẹ ọmọ ẹgbẹ ajọ naa.

Awọn olori ologun orilẹede mẹtẹẹta fẹsun kan ECOWAS pe o n fiya jẹ awọn lọna aitọ nítori awọn ologun gbajọba l'awọn orilẹede naa.

Wọn tun sọ pe ajọ ECOWAS n gbabọde fun orilẹede France to ko wọn lẹru.

Iditẹgbajọba to waye loṣu Keje lọdun 2023 ni Niger mi ECOWAS titi.

Ajọ ECOWAS dunkooko lati lo ọm'ogun gba ijọba pada fun Aarẹ Bazoum Mohammed ti araalu dibo yan.

Bakan naa ni ajọ ECOWAS tun fofin de Niger lẹka ọrọ aje, wọn ti gbẹsẹ kuro lori ofin naa bayii.

"A gba awọn eeyan Mali, Niger ati Burkina Faso laaye lati maa ko ọja wọle tabi se okoowo lawọn orilẹede to wa ninu ECOWAS"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nibayii, olu ileesẹ ajọ ECOWAS lẹkun iwọ oorun Afirika ti kede pe oun ti n gbe igbesẹ lati jiroro pẹlu awọn ologun to n dari orilẹede Burkina Faso, Mali ati Niger, ti wọn n kuro ninu ajọ naa loni.

Atẹjade kan ti ajọ ECOWAS fisita ni owurọ ọjọbọ ni oun ti n seto lati yago fun idarudapọ ati gbigba ẹmi pẹlu biba dukia ati okoowo jẹ laarin awọn eeyan to n gbe lawọn orilẹede to wa ninu ajọ ECOWAS ati awọn to n orilẹede to n kuro ninu ajọ naa.

"Orilẹede Burkina Faso, Niger ati Mali ti kuro ninu ajọ Ecowas ti fidi mulẹ lati oni ọjọ kọkandinlọgbọn osu Kinni ọdun 2025.

Amọ nitori ẹmi ifẹ araalu ati ẹmi ifẹ to n jọba ati ipinnu awọn alasẹ ajọ ECOWAS lati silẹkun rẹ silẹ, gbogbo awọn olori to yẹ lati awọn orilẹede to wa ninu ajọ naa, tabi ti ko si ninu ajọ ọhun, la rọ lati jẹ ki awọn orilẹede mẹtẹẹta to n kuro ninu ECOWAS maa wọle tabi jade lai gba fisa, ki wọn maa gbe tabi se okoowo lawn orilẹede ti wọn wa nibamu pẹlu ilana Ajọ naa."

Atẹjade naa tun salaye pe ajọ ECOWAS yoo tẹsiwaju lati maa faramọ iwe irinna to ni ami idamọ ECOWAS ti awọn eeyan orilẹede mẹtẹẹta to n ya lọ naa ba gbe dani.

ECOWAS fikun pe oun yoo maa lo ofin to wa nilẹ labẹ ofin ominira okoowo ati idokowo pẹlu awọn ọja to ba n wa lati awọn orilẹede yii.

O ni ilana yii yoo wa nilẹ titi ti awọn olori orilẹede ati alasẹ ECOWAS yoo fi ẹnu ọrọ jona lori igbesẹ awọn orilẹede mẹtẹẹta to yapa naa.

"ECOWAS ko lagbara mọ"

Wayi o, awọn orilẹ-ede mẹtẹẹta yii yoo bẹrẹ si ni maa lo iwe irina tiwọn lati Ọjọru, bakan naa ni wọn ti kede ikọ ologun apapọ ti yoo ni ẹgbẹrun marun un ọm'ogun lati kọjú ija sawọn alakakiti ẹsin.

Ọgbẹni Gilles Yabi to jẹ adari ẹgbẹ awọn akọṣẹmọṣẹ sọ pe bi awọn orilẹede mẹtẹ yii ṣe kuro ninu ajọ ECOWAS yoo sakoba fun eto oselu ẹku iwọ oorun Afrika.

Fun àpẹẹrẹ, Niger ti kọ lati ṣi ibode rẹ pẹlu Benin silẹ lẹyin to fẹsun kan orilẹede naa pe o gbabọde fawọn janduku agbebọn.

Orilẹede Niger tun fẹsun kan Naijiria pe o dabi oju ogun ẹyinkule to le ṣakoba nla.

Amọ, Naijiria ati Benin ti sọ pe irọ nla ni ẹsun yii.

Togo ati Ghana fẹ ni ibaṣepọ pẹlu ajọ AES

Orilẹede Togo lo ṣi ibudokọ omi rẹ fawọn orilẹede mẹta ajọ AES.

Ogbeni Yabi ni Togo ni iran nipa eto ọrọ aje eyi to le ṣakoba fun ECOWAS.

Laipe yii ni minisita ilẹ okeere Togo sọ pe o ṣee ṣe ki orilẹede naa darapọ mọ ajọ AES.

Rinaldo Depagne to jẹ igbakeji adari ajọ apẹtusija ni Afirika, ICG, sọ pe o le mu ewu dani fún ECOWAS ti o ba padanu Togo pẹlu bi Togo ṣe ni anfaani igbokegbodo ọkọ lori omi.

Aare tuntun Ghana naa, John Mahama n gbero lati b'awọn orilẹede AES sọrọ.

Ọgbẹni Depagne sọ pe aarẹ tuntun Ghana yatọ si awọn to ti jẹ ṣaaju rẹ lori iha ti wọn kọ si ologun ditẹ gbajọba.

Ibeere tawọn eeyan n beere ni pe ṣe o ṣee ṣe ki orilẹede jẹ ọmọ ẹgbẹ ECOWAS ati AES papọ?

"Ajọ ECOWAS tuntun"

Yabi ni ọpọ eeyan lo fẹ ki ECOWAS pada si ẹsẹ aarọ ti o gbajumọ ọrọ aje, eto ofin ati ijọba awaarawa.

Minisita kan lati orilẹ-ede kan lẹkun iwọ oorun Afrika sọ pe gbogbo eeyan lo mọ pe ajọ ECOWAS nilo atunṣe.

Minisita naa to n ba awọn olori ologun ijọba orilẹ-ede AES sọrọ ṣalaye pe ajọ AES le jẹ idanrawo fun ECOWAS.

Bo tilẹ jẹ pe ECOWAS ko fi bẹẹ lagbara mọ, Yabi ni o ṣe pataki lati jẹ ki ibaṣepọ to rinlẹ wa laarin AES ati ECOWAS fun anfaani eto ọrọ aje ati lati wa ojutuu si eto abo to mẹhẹ.

Awọn janduku agbebọn ti pa ẹgbẹẹgbẹrun eeyan ni Mali, Niger ati Burkina Faso laarin ọdun mẹwaa sẹyin.