Ka bí àwọn ọmọ ogun Nazi ṣe pa èèyàn 1.2m lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Child survivors of Auschwitz

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Nazi concentration camp at Auschwitz
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọgọrin ọdun sẹyin ni awọn ọmọ ogun Soviet ṣe itusilẹ awọn eeyan to wa ni agọ Auschwitz-Birkenau.

Awọn eeyan diẹ to wa nibẹ lọpọ ọdun naa sẹyin ti wọn si wa laaye lonii ti ṣe ayẹyẹ iranti miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan to padanu ẹmi wọn nibẹ.

Pupọ ninu awọn eeyan naa lo ti di arugbo bayii, o si ṣeeṣe ki ọdun yii jẹ igba ikẹyin ti awọn eeyan naa yoo le yọju sibi ayẹyẹ ọhun.

Laarin ọdun mẹrin abọ pere ni awọn ọmọ ogun Nazi Germany ṣekupa o kere tan, miliọn kan eeyan o le ni Auschwitz, eyii to wa nilẹ Poland, lẹba ilu Oswiecim.

Auschwitz yii lo wa ni aringbungbun afojusun awọn ọmọ ogun Nazi lati pa ẹya Jew to wa ni Yuroopu run, ti milọnu kan awọn ẹya Jew naa si jade laye.

Nigba ti awọn ọmọ ogun Red Army wọ Auschwitz lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 1945, nnkan bii ẹgbẹrun meje ẹlẹwọn pere lo ku sibẹ.

Ki ni Holocaust?

Nigba ti awọn Nazi gba agbara ni Germany lọdun 1933, wọn bẹrẹ si n gba gbogbo dukia awọn ẹya Jew ati ẹtọ wọn labẹ ofin.

Lẹyin ti Germany kogun ja Poland n i 1939, awọn Nazi bẹrẹ si n le awọn Jew kuro ni Third Reich lọ si awọn apa kan ni Poland, nibi ti wọn ti ya wọn sọtọ kuro lara awọn araalu.

Ni 1941, nigba ti Germany kogun ja USSR, awọn Nazi bẹrẹ si n pa ẹya Jew run nibẹ.

Awọn Nazi naa sọ pe ogun ẹya ni ogun ọhun, afojusun awọn si ni lati pa ẹya Jew run.

Hetty Verolme, wa lara awọn ti ko ku ni Bergen-Belsen

Awọn ọmọ ogun Germany kan ti wọn n pe ni Einsatzgruppen ya bo awọn ilẹ ti wọn ṣẹṣẹ gba ni ila oorun Europe lati bẹrẹ si n pa araalu.

Nigba ti yoo di igbẹyin ọdun 1941, wọn ti gbẹmi eeyan 500,000.

Nigba ti yoo di ọdun 1945, wọn ti ṣekupa eeyan bii miliọnu meji, ti miliọnu kan o le ẹgbẹrun lọna ọgọrun si jẹ Jew.

Lasiko naa lawọn adari ikọ ogun Nazi n kọ wọn bi wọn ṣe le pa ọgọrọ eeyan lẹẹkan ṣoṣo.

Wọn woye pe fifi ibọn pa eeyan yoo ṣoro fun awọn ọmọ ogun wọn, wọn si n wa ọna mii to rọrun lati pa eeyan.

Lara awọn nnkan ti wọn ṣeda rẹ ni awọn gaasi to le gbẹmi eeyan.

Ni 1941 wọn ti kọ ile gaasi ti wọn n ko awọn ti wọn ba fẹ ṣekupa si, wọn tun ṣe ibi ti wọn yoo ti maa jo oku wọn ni Auschwitz.

Lọdun 1942, awọn adari nazi ṣe ipade Wannaasee Conference, nibi ti wọn ti jiroro lori bi wọn yoo ṣe pa miliọnu mọkanla awọn ẹya Jew.

Ki ni Auschwitz?

Lakọkọ, Auschwitz jẹ ibi ti awọn ologun Poland n gbe.

Ṣugbọn lẹyin ti awọn ọmọ ogun Nazi kọlu Poland ninu oṣu Kọkanla ọdun 1939, wọn sọ ibẹ di ẹwọn ti wọn n ko awọn ti wọn gbamu loju ogun si.

Auschwitz Nazi concentration camp from above
Àkọlé àwòrán, Agọ Auschwitz Nazi

Ni bi ogun ati ifẹmiṣofo naa ṣe n tẹsiwaju, ijọba Nazi fẹ ẹwọn naa loju.

Ọdun 1941 ni wọn kọkọ fi afẹfẹ gaasi gbẹmi awọn ologun Poland ati Soviet nibẹ.

Yatọ si Auschwitz, wọn tun kọ awọn ọgba ẹwọn mii ni Birkenau Belzec, Sobibor ati Treblinka.

Ki lo n ṣẹlẹ ni Auschwitz?

Wọn maa n ko awọn eeyan kaakiri Europe sinu ọkọ ti ko ni ferese, ile igbọnsẹ, ounjẹ tabi ijoko, wọn yoo si ko wọn lọ si Auschwitz.

Wọn maa n ya awọn to le ṣiṣẹ sọtọ, wọn yoo si tun ya awọn ti wọn yoo pa lẹsẹkẹsẹ sọtọ.

Lẹyin naa ni wọn yoo bọ aṣọ awọn ti wọn fẹ pa ti wọn yoo si wẹ wọn.

The gas chamber at Auschwitz I

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ile gaasi ti wọn ti n pa awọn eeyan
Crematorium ovens at Auschwitz

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ibi ti wọn ti n jo oku awọn ti wọn ba pa

Lẹyin naa ni wọn yoo fi afẹfẹ gaasi sinu ile ti wọn ko awọn eeyan naa si, wọn yoo si maa ṣọ ile naa titi ti awọn eeyan ọhun yoo fi jade laye.

Ogiri ile naa nipọn to bẹẹ ti ẹni to ba wa nita rẹ ko ni gbọ ariwo ẹkun awọn to wa ninu rẹ bi wọn ṣe n pòhunrere ẹkun ti wọn si n reti iku.

Lẹyin eyii ni awọn ẹlẹwọn mii ti wọn n pe ni "Sonderkomandos" yoo yọ ẹyin awọn oku naa ati irun wọn ki wọn to lọ jo oku wọn.

Awọn wo ni wọn n sekupa nibẹ?

Iwadii fi han pe nnkan bii 1.3 miliọnu eeyan lo lọ si Auschwitcz, ṣugbọn eeyan to le ni 1.1 miliọnu lo ku sibẹ.

Awọn ọmọ ẹya Jew kaakiri agbegbe ti awọn Nazi n ṣakoso ni Europe lo pọ ju ninu awọn to padanu ẹmi wọn sibe.

Nnkan bii miliọnu kan eeyan Jew ni aye wọn pin si Auschwitz.

Apẹrẹ ni awọn ẹya Jew to wa ni Hungary.

Laarin oṣu Karun un si oṣu Keje ọdu 1944, Hungary fi ẹya Jew 420,000 ninu awọn 437,000 rẹ sọwọ si Auschwitz.

Hungarian Jews arriving at Auschwitz in June 1944

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ki lo ṣẹlẹ lẹyin ominira Auschwitz?

Ijọba Germany fopin si bi wọn ṣe n fi gaasi pa awọn eeyan ni Auschwitz.

Bẹẹ ni ijọba naa ni ki wọn wo ile ti wọn ti n jo oku awọn ẹlẹwọn ni ipari ọdun 1944.

Ninu igbiyanu rẹ lati fi ẹri iwa ifẹmisọfo naa pamọ, ijọba Nazi ni ki awọn ẹlẹwọn Auschwitz ti iye wọn to 56,000 fi ẹsẹ rin lọ si awọn agọ mii bii Bergen-Belsen, Dachau ati Sachsenhausen.

Wọn fi awọn ti ko le rin nitori wọn n ṣaisan silẹ ni ọgba ẹwọn naa, bẹẹ ni wọn ṣekupa awọn to n ṣubu loju ọna ti wọn ko le rin mọ.