Ilé ẹjọ́ gba onídùúró Sowore pẹ̀lú mílíọ́nù mẹ́wàá náírà

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ile ẹjọ giga kan ilu Abuja ti fi aaye beeli silẹ fun Omoyele Sowore, ondupo aarẹ Naijiria ni 2023, pẹlu miliọnu mẹwaa naira ati oniduuro kan niye kan naa.

Ẹsun to ni i ṣe pẹlu lilo ayelujara nilokulo ni wọn fi kan an.

Ọjọbọ, ọgbọnjọ oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 ni Adajọ Musa Liman, fi anfaani beeli naa silẹ pẹlu alaye pe oniduuro naa gbọdọ jẹ ọmọluabi.

O fi kun un pe ni ẹni naa gbọdọ ni awọn ile lagbegbe kootu naa.

Ile ẹjọ faaye beeli naa silẹ lẹyin ti agbejọro Sowore, Marshall Abubakar, pe fun beeli rẹ.

Adajọ paṣẹ pe oniduuro naa gbọdọ fi iwe irinna rẹ silẹ fun kootu, o si gbọdọ bura fun kootu pẹlu.

Nigba to n dahun ibeere lori ẹsun mẹrindinlogun ti ọga ọlọpaa, Kayode Egbetokun, fi kan an, Sowore sọ pe oun ko jẹbi.

Kí ni Sowore ṣe?

Aworan Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore/ Facebook.

Ninu ẹsun ti ọga ọlọpaa Egbetokun fi kan Omoyele Sowore ni pe logunjọ, oṣu Kejila ọdun 2025, Sowore pe ọga ọlọpaa Naijiria ni ayederu loju opo X rẹ.

Ẹsun mi-in ti wọn fi kan an ni pe o gbe fọto Egbetokun soju opo X rẹ, o si pe e ni: alaikunju oṣuwọn, jẹgudujẹra.

Wọn lo tun kọ ọ sibẹ pe orilẹede ti awọn ti ko niwa ba n dari rẹ ko le ni ilọsiwaju.

Awọn ọlọpaa tun sọ pe Sowore kọ ọ soju opo X rẹ, pe ''Ọga ọlọpaa Egbetokun ni yoo ba Naijiria jẹ bi a ko ba tete gbe igbesẹ bayii."

Lẹyin to ni ohun ko jẹbi awọn ẹsun wọnyi ni adajọ sun igbẹjọ naa siwaju.

Kí ló dé tí Sowore fi kọ̀ láti kúrò ní àhámọ̀ ọlọ́pàá?

Aworan Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, Facebook/ Omoyele Sowore

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oludije sipo aarẹ ni ọdun 2023 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Action Congress ati ajafẹtọ ọmọniyan, Omoyele Sowore lo ti dero ahamọ ọlọpaa niluu Abuja lẹyin to kọ lati gba awọn eroja beeli itusilẹ rẹ.

Sowore kede ni alẹ ọjọ Aje lori opo ayelujara rẹ pe oun wa ni atimọle, ti ileeṣẹ ọlọpaa si kọ lati tu silẹ nitori o kọ lati se ohun ti wọn beere fun un.

Ileeṣẹ ọlọpaa, lọjọ Aje, fun Sowore ni beeli lẹyin ti wọn fọrọwalẹnu wo ni ileeṣẹ ọlọpaa niluu Abuja.

Ṣugbọn Sowore ni ohun ti awọn ọlọpaa n beere fun bii wiwa oṣiṣẹ ijọba to wa ni ipele mẹtadinlogun gẹgẹ bi oniduro, ko si tun fi iwe irinna rẹ silẹ jẹ ohun to lodi si ofin.

O ni oun ko ni tẹwọgba ohun ti awọn ọlọpaa n beere fun ninu ọrọ kan to gbe sori ayelujara lọjọ Aje.

"Awọn ọlọpaa ti wọn wa lori ẹjọ mi sọ fun mi pe olori ileeṣẹ ọlọpaa DIG ti FID, Dasuki Galandachi ti se atunse si beeli mi.

Eyi to tumọ si pe ki n lọ wa oṣiṣẹ ijọba to wa ni ipele mẹrindinlogun wa, ki n si tun fi iwe irinna mi silẹ, eyi jẹ ohun ti mo ni n ko le gba rara .

N ko ni ba wọn lọwọ ninu ohun ti yoo tabuku si aṣọ apọnle mi."

Ki lo gbe Sowore lọ ileeṣẹ ọlọpaa?

Fọnran kan lu sita lori ayelujara nibi ti Sowore ti kọ lati jẹ ki awọn ọlọpaa kan se ayẹwo ọkọ.

Awọn ọlọpaa naa ni ki Sowore duro ṣugbọn o kọ lati duro, to si ni ki wọn lọ pe ọga wọn wa.

Sowore fẹsun kan awọn ọlọpaa naa pe wọn duro sọna lati maa gba owo lọwọ araalu ni ọna paapakọ ofurufu.

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni Sowore kede pe oun gbọ pe awọn ọlọpaa n wa oun, ti oun si setan lati jẹ ipe wọn.

Sowore de ileeṣẹ ọlọpaa niluu Abuja ni deede ago mẹwaa ni owurọ ọjọ Aje.

To si bẹrẹ si ni ma dahun ibeere lori fọnran to gbe sita, nibi ti o ti n fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa niluu Eko.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa n beere fun lọwọ Sowore?

Ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu aṣẹ igbakeji ọga agba Naijiria, Dasuki Galandachi ni pe ki Sowore wa oniduro to jẹ oṣiṣẹ ijọba to wa ni ipele mẹtadinlogun, ko si tun fi iwe irinna rẹ silẹ.

Ko pẹ ni ileeṣẹ ọlọpaa tun mu adikun ba ohun ti wọn n bere fun si pe ki Sowore wa oṣiṣẹ ijọba to wa ni ipele mẹrindinlogun.

Sowore ni oun ko ṣekan lati se eyi, to si o san pe ki oun wa niu ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Mo gbagbọ ninu ohun ti Sowore duro le – Falana, agbẹjọro Falana

Agbẹjọro Omoyele Sowore, Femi Falana ni ohun ti Sowore duro le jẹ ohun ti o ba ofin mu ninu lẹta kan to kọ si igbakeji ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa, Dasuki

Falana dupẹ lọwọ igbakeji ọga ọlọpaa naa fun bi o se mu adikun ba ohuin beeli Sowore ṣugbọn o jẹ ko di mimọ pe ohun ti ileeṣẹ ọlọpaa n bere fun lọwọ Sowore jẹ ohun to lodi si ofin.

O ni eyi jẹ ohun ti ko waye nibi kibi ni ofin lorilẹede Naijiria.