Aráàlú yìnbọn pa ọmọ ilẹ̀ Iraq tó dáná sun Quran, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Salwan Momika

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Wọn ti yinbọn pa ọkunrin kan lorilẹede Sweden lẹyin to dana Quran.

Ṣaaju iku ọkunrin naa, ni awọn eeyan ti kọkọ fẹhonuhan lori ohun to ṣe, ti ọpọ awọn Musulumi si bu ẹnu atẹ lu iwa to wu.

Ikọ oluwadii sọ fun BBC pe inu ile kan lagbegbe Södertälje, ni Stockholm ni wọn ti ri oku rẹ.

"Wọn gbe oloogbe naa, to jẹ ọmọ orilẹede Iraq, amọ to n fi Sweden ṣebugbe, ati ọkunrin mii lọ ile ẹjọ lori ẹsun pe wọn n gbogun ti awọn ẹya kan"

Ọdun 2023 ni oloogbe naa dana sun iwe mimọ awọn Musulumi niwaju mọṣalaṣi nla Stockholm Central Mosque.

Ọlọpaa Stockholm sọ pe awọn ti fi ṣikun mu ọkunrin marun lori ẹsun pe wọn lọwọ ninu iku ọkunrin tiwọn yinbọn pa.

Nnkan bii aago mẹwaa kọja iṣẹju mọkanla alẹ ni araalu pe ọlọpaa pe awọn funra pe awọn kan ti ṣina ibọn fun ẹnikan lọjọru.

Ọlọpaa ko darukọ ọkunrin ti wọn yinbọn pa amọ wọn ni ọkunrin naa dakẹ laarọ Ọjọbọ.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle ilẹ naa sọ pe ori ẹrọ ayelujara ni Momika ti n ṣe fidio lasiko to fara gbọta ibọn.

Ninu oṣu Kẹjọ, ọdun to kọja ni wọn gbe oloogbe naa, to jẹ ọmọ orilẹede Iraq, amọ to n fi Sweden ṣebugbe ati ọkunrin mii lọ ile ẹjọ lori ẹsun pe wọn n gbogun ti awọn ẹya kan.

Wayi o, ile ẹjọ ti sun idajọ rẹ to yẹ ko waye siwajau lẹyin to gbọ pe wọn ti yinbọn pa ọkan lara awọn olujẹjọ.

Lọpọ igba igba ni Momika maa n ṣe awọn nnkan to tako ẹsin Islam, eyii to fa ifẹhonuhan lọpọ awọn orilẹede ti Musulumi pọ si.

Ṣaaju ko to dana sun Quran, o ti kọkọ lọ gba aṣẹ lọwọ awọn ọlọpaa pe o n fẹ fẹhonunhan, ti wọn si sọ pe o le tẹsiwaju ninu ifẹhonuhan rẹ.