Wọn rí òkú èrò 19 nínú ìjàmbá bàálù méjì tó forí sọra l‘ófurufú, tó já bọ́ sínú odò

Baalu meji to jabọ sinu odo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Baalu meji ti fori sọ ara wọn ni papakọ ofurufu Reagan Washington ni deede aago mẹsan alẹ Ọjọru.

Atẹjade kan ti ẹka ileesẹ to n mojuto eto irinna ofurufu nilẹ Amẹrika fisita salaye pe baalu akero ilẹ Amẹrika kan lo fori sọ baalu kekere ẹlikopita ologun kan lori afẹfẹ .

Isẹlẹ naa lo waye lasiko ti baalu akero naa fẹ ba lopopona baalu kẹtalelọgbọn, ti iwadi si ti n lọ nipa ohun to fa isẹlẹ naa.

Lọwọlọwọ bayii, o le ni ọkọ panapana mejila ati ọkọ itọju pajawiri fawọn alaisan to ti wa nikalẹ nibi isẹlẹ naa.

Papakọ ofurufu ti isẹlẹ ti waye

"Ikọ adoola ẹmi sawari oku eeyan mọkandinlogun to ja latinu baalu naa sinu odo"

Ọkọ baalu naa si lo jabọ sinu odo Potomac to gba aarin ilu Washington kọja, ti awọn aluwẹ si ti bẹ sinu odo naa lati maa wa awọn eeyan inu baalu ọhun jade.

Baalu ẹlikopita to fori sọ baalu akero nla naa si wa lẹba baalu nla ọhun, to dorikodo sinu odo.

Gomina ipinlẹ Virginia, Glenn Youngkin oun n rọ gbogbo eeyan lati maa gbadura fawọn eeyan to fori sọta isẹlẹ yii, awọn osisẹ inu baalu naa ati ẹbi wọn.

Ileesẹ Ọlọpaa nilẹ Amẹrika ti wa fidi rẹ mulẹ fun BBC pe awọn ikọ adoola ẹmi ti sawari oku eeyan mọkandinlogun to ja latinu baalu naa sinu odo.

Bakan naa ni wọn sọ pe wọn ko ti ri ero baalu to ja ọhun, to ye isẹlẹ naa.

Ileesẹ Ologun Amẹrika ti wa fidi rẹ mulẹ pe baalu Ologun ni ẹlikopita to fori sọ baalu akero naa.

Awọn alasẹ papakọ ofurufu Ronald Reagan ti gbẹsẹle gbogbo baalu lati fo lati papakọ ofurufu naa

Awọn alasẹ papakọ ofurufu Ronald Reagan ti gbẹsẹle gbogbo baalu lati le fo lati papakọ ofurufu naa.

Iroyin lati ọdọ awọn alasẹ papakọ ofurufu naa ti wa fidi rẹ mulẹ pe ero ọgọta ati osisẹ mẹrin lo wa ninu baalu nla to ja naa.

O si le ni ida mẹrin awọn ero to n wọ baalu to maa n rinrinajo lati ipasẹ baalu naa to jẹ tilẹ Amẹrika, eyi to pọ pupọ ju tileesẹ baalu aladani lọ.

O si le ni ero miliọnu mẹfa to maa n wa si papakọ ofurufu naa laarin ọdun kan.