Gbogbo èèyàn mẹ́jọ tó wà nínú bàálù tó já ní Port Harcourt ló pàdánù ẹ̀mí wọn

Aworan Baalu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn alaṣẹti fi di rẹ mulẹ pe gbogbo ero to wa ninu ọkọ ofurufu to ja ni agbegbe Bonny ni ipinlẹ Rivers lo ti jade laye.

Awakọ baalu meji ati ero ọkọ baalu mẹfa lo ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ẹka ijọba to n risi irinajo ofurufu lo gbe iroyin sita laana lasiko ti baalu naa ja.

Ọkọ ofurufu naa, to jẹ ti ileeṣẹ East Wind Aviation pẹlu nọmba idanimọ Sikorsky SK76, 5NBQG lo n kuro lati ilu Port Harcourt lasiko ti ijamba naa waye.

Wọn ni ọkọ baalu naa ja si inu omi to wa ni ẹgbẹ Bonny Finima ninu okun nla.

Odulayo Oluseyi, agbẹnusọ ajọ kọkọ ni eeyan mẹta lo jade laye.

Ṣugbọn, lẹyin ọpọ wakati ti wọn bẹrẹ si ni ma wa awọn eeyan naa, ileeṣẹ ọlọpaa ni gbogbo awọn ero baalu naa lo ti jade laye

Ọkọ̀ òfúrufú já ní Port Harcourt, èèyàn mẹ́ta jáde láyẹ

crash in port harcourt

Oríṣun àwòrán, @NaijaGossipHub

Wọn ti ri oku eeyan mẹta yọ lẹyin ti baalu ẹlikọpita Sikorsky SK76 ja lulẹ ni niluu Port Harcout.

Ọkọ ofurufu naa, to jẹ ti ileeṣẹ East Wind Aviation, ni a gbọ pe o n bọ lati ileeṣẹ ọmọ ogun to wa niluu Port Harcourt, to si n lọ si ibi ti wọn tin wa epo NUIMANTAN.

Ero mẹjọ ni a gbọ pe o wa ninu ọkọ naa ki isẹlẹ laabi ọhun to waye.

Ṣaaju ni minisita to n ri si irinajo ofurufu ni Naijiria, Festus Keyamo ti kọkọ paṣẹ fun awọn adoola ẹmi lati lọ sibẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ẹrọ Emergency Locator Transmitter (ELT) ọkọ naa ko ranṣẹ pajawiri, awọn adoola ẹmi bẹrẹ iṣẹ lati mọ ibi pato to ja si.

Lara awọn adoola ẹmi to n ṣiṣẹ idoola ẹmi nibẹ ni ajọ Nigerian Safety Investigation Bureau.

Keyamo ti fi da awọn araalu loju pe ijọba ko ni kawọ gbera ninu idoola awọn ti ọrọ naa kan.,

O fi kun pe digbi ni ijọba wa lẹyin mọlẹbi awọn ti ọrọ naa kan, yoo si ṣe atilẹyin to yẹ fun wọn.

Iroyin ni lara awọn to wa ninu ọkọ ofurufu naa ni oṣiṣẹ ajọ NNPCL.

Wayi o, eto idoola ẹmi ṣi n lọwọ nibi ti ọkọ ofurufu naa ja si.