Nígbà tí àdó olóró Israel bẹ̀rẹ̀ sí ń dún lákọlákọ, àwọn ọ̀gá mi sá fi èmi nìkàn sílẹ̀ nínú ilé - Ọmọ Áfíríkà ní Lebanon

Àkọlé fídíò, Nígbà tí àdó olóró Israel bẹ̀rẹ̀ sí ń dún lákọlákọ, àwọn ọ̀gá mi sá fi èmi nìkàn sílẹ̀
Nígbà tí àdó olóró Israel bẹ̀rẹ̀ sí ń dún lákọlákọ, àwọn ọ̀gá mi sá fi èmi nìkàn sílẹ̀ nínú ilé - Ọmọ Áfíríkà ní Lebanon

Nigba ti ado oloro awọn ọmọ ogun orilẹede Israel kanba ile awọn ọga to gba a siṣẹ ni ẹkun gusu lebanon, Andaku, (kii ṣe orukọ rẹ tootọ o) ba ara rẹ ni oun nikan, ti awọn ọga rẹ si ti ilẹkun mọ ọ mọle. Ẹru to n ba pọ pupọ ṣugbọn ko si bi o ṣe le jade.

Ẹni ọdun mẹrinlelogun ni Andaku, mọ orilẹede Kenya to n ṣe iṣẹ ọmọ ọdọ lorilẹede Lebanon lati nnkan bii oṣu mẹjọ sẹyin.

O ni oṣu to kọja lo nira fun oun julọ pẹlu bi iklu Israel ṣe bẹrẹ kikankikan lori awọn ibuba ikọ Hezbollah kaakiri orilẹede naa.

Awọn eeyan ti wọn ko si awọn ibudo ogunlende kan ni Lebanon.

“Ikọlu ado oloro yii pọ pupọ. Awọn ọga mi ti mi mọle wọn si sa asala fun ẹmi tiwọn.”

Ko tilẹ le ka iye ọjọ ti awọn ọga rẹ fi ti i mọle ki wọn to pada wa.

Andaku ṣalaye siwaju sii pe, “Nigba ti wọn pada de, wọn le mi jade. Wọn ko san owo oṣu mi, bẹẹni mi o ni ibi kankan ti mo le lọ.”

O ni iwọnba owo to ku lọwọ oun loun fi wọ bọọsi lọ si ilu Beirut to jẹ olu ilu orilẹede Lebanon.

Andaku nikan kọ lo wa ninu hilahilo yii.

Eruku sọ lala lẹyin ti ado oloro bọ si agbegbe kan ni Lebanon

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ni ọsẹ to kọja ni ajọ iṣọkan agbaye, UN kede pe nnkan bii ẹẹdẹgbẹrun ibudo ogunlende ti awọn ijọba kọ lo ti ku akunfaya lẹyin ti ina ogun fẹju toto laarin Israel ati Hezbollah, ti o si kọminu lori bi ọkẹ aimoye eeyan, pupọ ninu eyi to jẹ awọn ọmọ ọdọ lorilẹede naa, ṣe n di alarinkiri ati alainilelori.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ti ajọ to n ri si awọn aṣatipo lagbaye ṣe sọ, ẹgbẹrun lọna aadọsan, (170, 000) awọn oṣiṣẹ ti wọn jẹ aṣatipo lo wa ni Lebanon. Pupọ wọn lo jẹ obinrin lati orilẹede Kenya, Ethiopia, Sudan, Sri Lanka, Bangladesh ati Philipines.