Bianca Ojukwu: Ta ni arẹwà obìnrin yìí tí Ààrẹ Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò mínísítà?

Aworan Bianca Ojukwu

Oríṣun àwòrán, IG/biancaodumegwuojukwu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ Bola Tinubu kede orukọ awọn minisita tuntun ti wa ninu ijọba rẹ, to si gba iṣẹ lọwọ minista kan.

Lara awọn minisita tuntun ni a ti ri iyawo aja fun ominira ilẹ Igbo to di oloogbe, Ikemba Ojukwu, Bianca Ojukwu.

Minisita fun ọrọ oke okun ti ipinlẹ ni ipo ti Aarẹ Tinubu fun Iyawo Ojukwu.

Ni aarin awọn ẹya Igbo lorilẹede Naijiria, ko si ẹni ti ko fẹẹ mọ Bianca Ojukwu, koda ohun ti pọ mọ ọ si ni ẹni kan ti o n fi ipo rẹ dide sọrọ nipa awọn to ku diẹ kaa to fun lawujọ.

Bianca Ojukwu

Oríṣun àwòrán, Bianca Ojukwu/facebook

Yatọ si pe awẹlẹwa obinrin ni, awọn nnkan miran wa to jẹ aigbọdọ ma mọ nipa rẹ.

Eyi ti ọpọlọpọ ko fẹrẹ ni gbagbe nipa rẹ, paapa julọ laarin awọn to n woye ọr oṣelu ni Naijiria ni iṣẹlẹ kan to ṣẹ ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹta ọdun 2022 lasiko ti okiki kan nipa ija to waye laarin oun ati iyawo gomina ipinlẹ Anambra to n fi ipo silẹ nigba naa. Ifọti to fun iyawo gomina naa nigba naa jẹ eyi to gba oju gbogbo iwe iroyin lasiko naa.

Eeyan le sọ pe Bianca kii ṣe ajeji si ọ̀rọ oṣelu atawọn awuyewuye to rọ mọ ọ.

Ta a ni Bianca Ojukwu?

Aworan Bianca ati ọkọ rẹ Chukwuemeka Ojukwu.

Oríṣun àwòrán, bianca ojukwu/instgram

Ọdun 1968 ni wọn bi Bianca Odinakachukwu Olivia Odumegwu-Ojukwu ni ọjọ karun un oṣu kẹjọ.

Bianca ni ikẹfa ninu awọn ọmọ ti awọn obi rẹ bi; awọn yoku ni Lilian, Josephine, Nuzo, Gabriel, ati Joseph.

Baba rẹ, Christian Onoh, ti fi igba kan ri jẹ gomina ipinlẹ Anambra, , iya rẹ, Carol Onoh pẹlu jẹ ọga agba ile ẹkọ girama.

Bianca dagba si ilu Ngwo to jẹ ilu abinibi rẹ ni ipinlẹ Enugu bayii.

Carol Onoh, iya Bianca.

Oríṣun àwòrán, Bianca Ojukwu/Facebook

Odumegwu Ojukwu lo gbogbo igba kekere rẹ ni ilu Ngwo pẹlu awọn ẹgbọn ati aburo rẹ.

O lọ si ile ẹkọ Actworth schoo Pontefract, St Andrews College, Cambridge .

O kawe gba gboye ninu imọ oṣelu, isiro ati ofin ni fasiti Buckingham, ko to pada si fasiti Naijiria ni Nsukka.

Bianca nigba to jáwé olubori idije omidan to rẹwa julọ ni Naijiria lọdun 1988.

Oríṣun àwòrán, Bianca Ojukwu

Ni ọdun 1988, Bianca Odinakachukwu Odumegwu-Ojukwu, jawe olubori ninu idije omidan to rẹwa ju lorilẹede Naijiria, (MBGN).

Bakan naa lo gba obinrin to rẹwa ju ni ilẹ adulawo ni ọdun 1989.

Bianca jẹgbajugbaja obinrin lágbo oṣelu lorilẹede Naijiria.

Igbeyawo rẹ pẹlu Ojukwu

Bianca ati Chukwuemeka Ojukwu lasiko igbeyawo wọn.

Oríṣun àwòrán, Bianca Ojukwu/Facebook

Bianca Odinakachukwu Odumegwu Ojukwu fẹ gbajugbaja aṣiwaju ẹya igbo, Ikemba Chukwuemeka Odumegwu Ojukwu.

Ojukwu ni Ọgagun agba fun ikọ ọmọogun Biafra lasiko ti wọn fi da ogun abẹle sile laarin ọdun 1967 si 1970 ki o to da ẹgbẹ oṣelu APGA silẹ labẹ iṣakoso iṣejọba alagbada to bẹrẹ lọdun 1999 lorilẹede Naijiria.

Ọmọ mẹta ni Bianca Ojukwu bi fun Ojukwu ko to di pe o jade laye ni ọdun 2011.

Ni ọdun 2011, Aarẹ orilẹede Naijiria lasiko naa, Goodluck Jonathan yan Bianca gẹgẹ bii oluranlọwọ pataki fun ọrọ oke okun.

O tun jẹ aṣoju Naijira lọ si Ghana ati orilẹede Spain.

Bakan naa ni Bianca Ojukwu jẹ aṣoju Naijiria si ajọ to n ri si ọrọ irinajo afẹ labẹ ajọ iṣọkan agbaye, United Nations World Tourism Organization.