Ìjọba àpapọ̀ wọ́gilé gbogbo ẹ̀sùn tó fi kan adarí iléeṣẹ́ Binance ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, @W3Vibes
Ijọba Naijiria ti wọgile gbogbo ẹsun iwa ọdaran to fi kan adari ileeṣe Binance Holdings, Tigran Gambaryan, latari ilera rẹ ti ko ṣe dede.
Ṣaaju asiko yii ni Gambaryan ti kọkọ n koju ẹsun kiko owo pamọ lọna aitọ lati inu oṣu Kẹrin ọdun yii.
Agbẹjọro fun ajọ EFCC lo kede pe ijọba ko ba afurasi naa ṣe ẹjọ mọ niwaju adajọ Emeka Nwite.
Igbẹjọ ti ọrọ yii ti jade lo waye lọjọ meji ṣaaju ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹwaa to yẹ ki igbẹjọ naa tẹsiwaju gan.
Nigba to n kede pe ijọba ko ṣe ẹjọ mọ, agbẹjọro EFCC sọ pe oṣiṣẹ lasan ni ọmọ ilẹ Amẹrika naa jẹ ni Binance.
Agbẹjọro afurasi ọhun, Mark Mordi ni oun gba ọrọ ti agbẹjọro EFCC sọ wọle, ati pe onibara oun ko lọwọ ninu pupọ ninu ohun ti ileeṣẹ naa n ṣe.
Adajọ to n gbọ ẹjọ ọhun, Emeke Nwite ti kọkọ kọ beeli afurasi naa lori ilera rẹ, o ni ipo ti ilera rẹ wa ko to lati tu silẹ ahamọ.
Ọjọ kọkanla inu oṣu Kẹwaa yii lo kọ lati gba beeli naa, ọjọ naa lo si sun igbẹjọ ọhun si ọjọ karundinlọgbọn oṣu yii kan naa.
Wayi o, igbẹjọ to yẹ ko waye lọjọ karundinlọgbọn oṣu yii ko ni waye mọ latari pe ijọba ni oun ko ba afurasi ṣe ẹjọ mọ.















