'A gbàwẹ̀, gbàdúrà, ṣe ìtọrẹ àànú nítorí oko wà, síbẹ̀ gbogbo oko wa l'ẹ̀kún omi kó lọ'
Ọpọ awọn agbẹ lorilẹede Naijiria ni wọn ti n kebosi bayii lori ọṣẹ ti ojo arọọrọda to n waye lẹnu lọwọlọwọ yii n ṣe fun eto ọgbin eleyii ti wọn ni o le ṣe okunfa ọwọngogo ounjẹ lọdun to n bọ.
Lapa ariwa orilẹede Naijiria ni ọwọja ẹkun omi ti waye ju bayii lọdun 2024.
Awọn agbẹ olohun ọgbin ni ẹkun naa si ti n kerora bi ẹkun omi naa ṣe n ba ire oko jẹ ti o si n sọ awọn ilẹ oko di ilẹ omi lọ san-kan-oru-kan.
Idaji miliọnu kan saare ilẹ oko ni ẹkun omi bajẹ lasiko ojo lọdun yii.

Pupọ ounjẹ t’awọn eeyan n jẹ lorilẹede Naijiria lo jẹ pe apa ariwa lo ti n jade wa. Ṣaaju asiko yii, ida mẹtadinlogoji ninu ọgọrun ni ọwọja ọwọngogo ounjẹ ni Naijiria.
Milinu mejilelogun eeyan si lo n koju ebi ọpapanla lọdun 2024 nikan.
Àyípadà ojú ọjọ́
Awọn onimọ n sọ pe, ayipada oju ọjọ lo n fa awọn arọrọda ojo to n ṣokunfa ẹkun omi yii, o si ti n da gbese nlanla si ọrun awọn agbẹ lorilẹede Naijiria bayii.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oúnjẹ tó jẹ́ èrè oko ló máa ń wá láti ẹkùn àríwá orílẹ̀ èdè yìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìrẹsì, àgbàdo àti ẹ̀gẹ́ tí à ń jẹ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ló ń wá láti ẹkùn àríwá.
Láti ọdún díẹ̀ báyìí, àyípadà ojú ọjọ́ ń ṣe àkóbá fún àwọn èèyàn ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àti ààrin gbùngbùn Áfíríkà.
Aṣojú àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé lẹ́ka ètò ọ̀gbìn àti oúnjẹ ní Nàìjíríà, Kouacou Dominique Koffy sọ fún BBC News pé gbogbo ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ni omíyalé dààmú lọ́dún yìí.
Ó ní àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù méjìléláàádọ́ta ni kò rí oúnjẹ jẹ ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà àti pé ogun àti àyípadà ojú ọjọ́ ló ṣokùnfà rẹ̀.

Ní Nàìjíríà, àyípadà ojú ọjọ́ ti ṣàkóbá fún òun ọ̀gbìn àti èrè oko. Ní ọdún 2022, omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù ṣekúpa èèyàn tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún, sọ ọ̀pọ̀ di aláìnílé lórí mọ́, tó sì ba ọ̀pọ̀ nǹkan oko jẹ́.
Omíyalé ọdún yìí tún ṣọṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ mọ́kànlélọ́gbọ̀n, tó sì ṣàkóbá fún ìjọba ìbílẹ̀ ọgọ́sàn-án.
Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ní tó lé ní èèyàn mílíọ̀nù kan ló fara kásá omíyalé náà.
Bákan náà ni Nàìjíríà ń kojú ọ̀wọ́n gógó tó lágbára bí owó oúnjẹ ṣe ti gbówó lórí wọ ìdá 37.5%. ìlàjì àwọn tó ń gbé ní Nàìjíríà ni ìṣẹ́ àti òṣì ń bá fínra.



