Wo bí ìjàmbá ẹ̀kún omi àti ọ̀gbẹlẹ̀ torí àyípadà ojú ọjọ́, ṣe ń ṣokùnfà ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma/BBC
- Author, Azeezat Olaoluwa, BBC News Yola and Jalingo
- Role, Broadcast Journalist
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Mema Fwa, àgbẹ̀ alágbàdo àti ilá kò gbàgbọ́ pé òun máa pàdánù gbogbo èrè oko rẹ̀ tó gbìn lọ́dún yìí sọ́wọ́ ọ̀gbẹlẹ̀ àti àgbàrá òjò.
Láti ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n sẹ́yìn ni Fwa ti jẹ́ àgbẹ̀ ní ìlú kan ní ìpínlẹ̀ Adamawa, ìlà oòrùn àríwá Nàìjíríà. Ó ní ọdún márùn-ún sẹ́yìn yìí ni òun rí ìpèníjà tó lágbára jùlọ pàápàá nítorí omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù tó ń wáyé lásìkò yìí.
“Ọdún yìí ni ó burú fún mi jùlọ láti ìgbà tí mo ti ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀,” ó sọ.
Oko ìyá ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́ta náà ni ó ti kún fún omi báyìí tó sì jẹ́ pé èèyàn nílò ọks ojú omi kí ó tó dé ibẹ̀. Nígbà tó dé oko náà, tó rí nǹkan tó wà níbẹ̀, ó mí kanlẹ̀ ọgbẹ́ ọkàn.
“Ní ìbẹ̀rẹ̀ àsìkò ọ̀gbìn ọdún yìí lóṣù Kẹrin, àwọn nǹkan tí a gbìn ni ó bàjẹ́ nítorí pé kò sí òjò àti oòrùn.
“Nígbà tó di oṣù Keje , òjò bẹ̀rẹ̀ sí ní rọ̀ padà ni a ṣe pinnu láti tún dá oko, tí gbogbo rẹ̀ sì ń yọmọ àmọ́ omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù tún ti ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ báyìí.
“Ní ọjọ́ tí mo ri pé omíyalé wọnú oko mi, mi ò lè sùn, wọ́n sáré gbémi lọ sí ilé ìwòsàn. Mo ti ní ẹ̀jẹ̀ rúru. Inú mi kò dùn nítorí mi ò lè pèsè fáwọn ẹbí mi.”
Bíi Fwa, ọ̀pọ̀ àwọn àgbẹ̀ ní agbègbè rẹ̀ ni wọ́n pàdánù èrè oko wọn lọ́dún yìí nítorí àyípadà ojú ọjọ́. Àwọn tí wan ní àǹfàní láti gbin nǹkan sáré kó èrè òkò wọn látara ìbẹ̀rù omíyalé mìíràn.
Kọmíṣánnà fétò àyíká ní ìpínlẹ̀ Adamawa, Muhammed Sadiq Muhammed ní àwọn kò mọ̀ pé nǹkan tó lágbára tó báyìí má wáyé ní ìpínlẹ̀ náà.
Muhammed ní àsìkò ọ̀gbìn tó burú jùlọ ní ìpínlẹ̀ Adamawa ni àsìkò yìí jẹ́, tí àwọn ń rí ọ̀gbẹlẹ̀ àti òjò lásìkò kan náà.
“A ò lè pèsè oúnjẹ tó máa tó àwa fúnra jẹ débi tí a máa rí kó lọ sáwọn ìpínlẹ̀ mìíràn,” Muhammed sọ.
Ní ìpínlẹ̀ Taraba, tó súnmọ́ Adamawa, níṣe ni ọ̀gbẹlẹ̀ ti ba àwọn nǹkan oko wọn jẹ́, tó sì ti ṣàkóbá fún ọ̀pọ̀ àwọn àgbẹ̀.
Rabiu Musa ti rò wí pé òun máa rí ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àpò àgbàdo lọ́dún yìí lẹ́yìn tó gba ẹ̀yáwó ní ilé ìfowópamọ́ kan.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma/BBC
Àmọ́ òjò tí kò rọ̀ dáadáa kò jẹ́ kí òun rí èrè oko tó pọ̀ bó ṣe rò.
Ó ní òun kò rí ju ogún àpò àgbàdo lọ nínú gbogbo nǹkan tó gbìn.
“A gbàwẹ̀, gbàdúrà, kódà á tún pín àgbàdo fáwọn èèyàn láti fi wá àánú Ọlọ́run kí òjò le rọ̀ àmọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló pàdánù okoòwò wọn kódà àwọn mìíràn pàdánù ẹ̀mí wọn látára dúkìá tí wọ́n pàdánù,” Musa sọ.
Musa ní òun kò mọ bí òun ṣe máa dá ẹ̀yáwó tí òun gbà padà, tí òun sì máa bọ́ èèyàn tó lé ní ogójì tí òun ń tọ́jú.
“Inú mi kìí dún nígbà tí mo bá ń lọ sí okò, orí máa ń fọ́ mi nígbà tí mo bá ma fi padà sílé. Níṣe ló dàbí ẹni pé gbogbo nǹkan ń dàrú fún mi. Mi ò mọ bí mo ṣe fẹ́ rí àwọn nǹkan tí mo pàdánù padà.
Àyípadà ojú ọjọ́
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oúnjẹ tó jẹ́ èrè oko ló máa ń wá láti ẹkùn àríwá orílẹ̀ èdè yìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìrẹsì, àgbàdo àti ẹ̀gẹ́ tí à ń jẹ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ló ń wá láti ẹkùn àríwá.
Láti ọdún díẹ̀ báyìí, àyípadà ojú ọjọ́ ń ṣe àkóbá fún àwọn èèyàn ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àti ààrin gbùngbùn Áfíríkà.
Aṣojú àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé lẹ́ka ètò ọ̀gbìn àti oúnjẹ ní Nàìjíríà, Kouacou Dominique Koffy sọ fún BBC News pé gbogbo ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ni omíyalé dààmú lọ́dún yìí.
Ó ní àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù méjìléláàádọ́ta ni kò rí oúnjẹ jẹ ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà àti pé ogun àti àyípadà ojú ọjọ́ ló ṣokùnfà rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma/BBC
Ní Nàìjíríà, àyípadà ojú ọjọ́ ti ṣàkóbá fún òun ọ̀gbìn àti èrè oko. Ní ọdún 2022, omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù ṣekúpa èèyàn tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún, sọ ọ̀pọ̀ di aláìnílé lórí mọ́, tó sì ba ọ̀pọ̀ nǹkan oko jẹ́.
Omíyalé ọdún yìí tún ṣọṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ mọ́kànlélọ́gbọ̀n, tó sì ṣàkóbá fún ìjọba ìbílẹ̀ ọgọ́sàn-án.
Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ní tó lé ní èèyàn mílíọ̀nù kan ló fara kásá omíyalé náà.
Bákan náà ni Nàìjíríà ń kojú ọ̀wọ́n gógó tó lágbára bí owó oúnjẹ ṣe ti gbówó lórí wọ ìdá 37.5%. ìlàjì àwọn tó ń gbé ní Nàìjíríà ni ìṣẹ́ àti òṣì ń bá fínra.
Àkànṣe ohun ọ̀gbìn
Fún ọ̀pọ̀ àwọn àgbẹ̀ tí ọ̀gbẹlẹ̀ àti omíyalé bá fínra lọ́dún yìí, ohun tó jẹ wọ́n lógún jùlọ ni bí wọ́n ṣe máa pèsè oúnjẹ tó máa tó fún ẹbí wọn.
Nínú oṣù Kejì ọdún yìí, ìjọba ìpínlẹ̀ Taraba kéde láti mú ìgbèrú bá ètò ọ̀gbìn àti láti mú kí oúnjẹ pọ̀ lọ́pọ̀ yanturu ní agbègbè rẹ̀.
Koffy ní àwọn àgbẹ̀ nílò láti wá ọ̀nà ti wan yóò fi máa ṣe àmójútó omi sínú oko wọn dípò gbígbé ara lé iyẹ̀pẹ̀ bíi ti àtijọ́.
Kọmíṣánnà fétò àyíká ní Adamawa, Muhammed Sadiq Muhammed ní ìjọba ti gbé ìgbìmọ̀ tí yóò rí sí ààbò oúnjẹ dìde láti kojú ìṣòro náà.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma/BBC
Ó ní àwọn máa ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn àgbẹ̀ nípasẹ̀ àjọ tó ń rí sí ìwádìí tó wà ní Ibadan lójúnà àti pèsè àwọn èso tí ọ̀gbẹlẹ̀ kò lè bàjẹ́ fáwọn àgbẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé àwọn èso bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ti ń lò ní ìlà oòrùn Áfíríkà ti ṣàfihàn pé ó lè mú ìgbèrú bá èrè ní ìdá ọgbọ̀n bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àgbẹ̀ nílò láti máa rà á ní ọdọọdún.
Mema Fwa àti Rabiu Mus ań dúrò láti mọ̀ bóyá wọn le jẹ àǹfàní ètò yìí lórí oko wọn.
Fwa sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò lágbára láti dá oko bíi ti ìgbà kan mọ́, òun máa dá oko díẹ̀ kí àwọn ẹbí òun le rí oúnjẹ jẹ. Ó ní òun yóò máa gbára lé àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ láti ran òun lọ́wọ́.
Yusuf Akinpelu, Gift Ufuoma àti Buhari Muhammad Fagge ṣe àfikún sí ìròyìn yìí















