Mọ̀ nípa ohun tó ń mú 'national grid' bàjẹ́ àti ipa rẹ̀ lórí aráàlú

Aworan opo ina pupọ

Oríṣun àwòrán, Google

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Opo ina agbara to n pese ina mọnamọna lorilẹede Naijiria tun bajẹ lọjọ Aje, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹwaa ọdun 2024 yii, okunkun si gba gbogbo orilẹede yii kan.

Gẹgẹ bi atẹjade ti ajọ apinnanka, Electricity Distribution Company (AEDC), fi kede iṣẹlẹ naa loju opo X wọn, wọn ni opo agbara naa kọṣẹ ni aago meje alẹ ku iṣẹju meji.

AEDC ṣalaye pe kinni kan lo daṣẹ silẹ lara opo ọhun, eyi to pa gbogbo ina Naijiria pii.

Wọn ni ki araalu fọkan balẹ, wọn yoo yanju iṣoro naa laipẹ.

Onka fi han pe gbogbo ẹka apinnaka mejilelogun to wa ni Naijiria ni iṣẹlẹ naa kan, eyi to fa a ti ina ko fi si nibi kankan

Igba kẹfa ree ti opo ina agbara Naijiria yoo bajẹ ninu ọdun 2024 yii.

Ki ni òpó ina National grid?

Opo ina agbara to n pin ina kari ileeṣẹ, ibugbe ati gbogbo ibi ti wọn ba ti n lo ina mọnamọna ni Naijiria ni a n pe ni National grid.

Naijiria ni ileeṣẹ mẹfa to n pese ina ati ibudo mejidinlọgbọn mi-in.

Mẹta ninu awọn mejidinlọgbọn yii ni wọn n lo omi lati pese ina, nigba ti awọn yooku n lo afẹfẹ gaasi.

Gbogbo awọn ileeṣẹ onina mẹfa yii ni wọn jẹ ti aladaani, wọn n ko ida ọgọta ninu ọgọrun-un, nigba ti ijọba apapọ n ko ida ogoji.

Ileeṣẹ kan ṣoṣo naa lo jé ti ijọba nipa pinpin inaka lorilẹede yii.

Bawọn ileeṣẹ yii ba pese ina tan, awọn ajọ apinnaka lo ku ti yoo maa ṣeto pinpin rẹ.

Wo iye ìgbà tí òpó iná agbára Naijiria ti bàjẹ́ ni 2024

*Ọjọ kẹrin, oṣu keji.

Ọjọ kejiidinlọgbọn, oṣu kẹta

*Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹrin.

* Ọjọ kẹfa, oṣu keje.

*Ọjọ karun-un, oṣu kẹjọ.

*Ọjọ kẹrinla, oṣu kẹwaa.

Lọjọ kin-in-ni oṣu karun-un ọdun 2024, ileeṣẹ apinnaka (Transmission Company of Nigeria (TCN) sọ pe bi opo agbara naa ṣe n bajẹ ti dinku.

Agbẹnusọ TCN, Ndidi Mbah, sọ pe ogun igba (20 times) ni opo naa ti bajẹ lati 2020 titi di ọjọ akọkọ ninu oṣu karun-un ọdun yii.

Yatọ si igba marundinlaadọrun (85) to fi bajẹ laaarin 2015 si 2019.

Àkóbá wo ni òpó ina to n dẹnukọlẹ naa n ṣe lórí ọrọ̀ ajé Naijiria?

Awọn onimọ nipa ọrọ aje fidi ẹ mulẹ, pe akoba to pọ maa n koju ọrọ aje nigba ti opo ina agbara ba dẹnukọlẹ.

Wọn ni eyi ri bẹẹ nitori orilẹede to ṣẹṣẹ n gunke agba ni Naijiria, idagbasoke ọrọ aje rẹ si duro lori bi ina ba ṣe wa si.

Eyi lawọn akoba naa:

*Ipese ohun eelo yoo dawọ duro lawọn ileeṣẹ.

* Owo to n wọle yoo dinku jọjọ.

*Owo gọbọi ti wọn ba fi ra epo rọbi yoo mu ki wọn fowo kun ọja ti wọn n ta, inira rẹ yoo kan awọn araalu to n ra a.

* Awọn mọlẹbi yoo ni lati wa ọna ipese ina miran ti ko dẹrun.

*Awọn to ba ni ẹrọ amunawa yoo ni lati fi owo to yẹ ki wọn fi ṣe nnkan mi-in ra epo bẹntiroolu.

*Ọpọ eeyan ti ko ni ẹrọ amunawa yoo wa lokunkun birimu nikan kọ, iṣẹ aje wọn paapaa yoo dẹnukọlẹ pẹlu.

*Ọrọ aje Naijiria funra rẹ maa n ṣojojo laaarin asiko ti ina ọba ko ba si, nitori ọpọ ibi towo ti n wọle ko ni i ṣiṣẹ lai si ina.

Ǹjẹ́ àwọn apínnáká náà ń jẹ̀rora bí òpó agbára bá daṣẹ́ sílẹ̀?

Nigba ti opo agbara ina ọba ba bajẹ, kalulu lo maa n mọ ibi to ti kan oun.

Awọn araalu lo saaba n kan ju, boya awọn oṣiṣẹ apinnaka naa n jẹ ninu iya ọhun ko kan araalu kankan.

Lati tan imọlẹ si eyi, BBC ba Adari ẹka iroyin nileeṣẹ apinnaka IBEDC, n’Ibadan, Busolami Tunwase, sọrọ.

Tunwase salaye pe ko si bi opo naa yoo ṣe dẹnukọlẹ ti ina yoo wa.

‘’Ti opo naa ba ti bajẹ bẹẹ yẹn, o maa n kan awa naa, nitori ko si araalu to maa sanwo ina ti ko si.

‘’Afi ti ina ba de pada ni inu awa naa too le dun. Inu wa ki i dun rara ti National grid ba bajẹ.

‘’O tiẹ maa n dun wa pe awọn onibaara wa ko ni i rina lo, awa naa ti a wa lọfiisi paapaa, o kan wa.

’’Bo ṣe maa tan pada la maa n ba kiri to ba di pe opo naa tun bajẹ’’

Bayii ni Busolami Tunwase wi.