Ọ̀kan lára ìyàwó Rashidi Ladoja jáde láyé

Aworan Tinuade Ladoja

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Agba oye Rashidi Ladoja, tii se Otun Olubadan ati Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Oyo, ti padanu ọkan lara awn iyawo rẹ.

Orukọ aya Ladoja to di oloogbe naa ni Tinuade Ladoja.

Agbẹnusọ feto iroyin fun Oloye Ladoja, Adeola Oloko lo fi idi iku iyawo Ladoja naa mulẹ fawọn akọroyin.

Ọdún mọkanlelaadọrin ni oloogbe Tinuade Ladoja lo laye ko to jade laye.

Oloogbe naa si jẹ ọmọlẹyin Kristi tootọ bi o tilẹ jẹ pe Musulumi ni ọkọ rẹ.

Koda, ogbontarigi ni Tinuade Ladoja ninu ijọ Celestial, to si jẹ ọmọ igbimọ alakoso fun ijọ naa.

Ilu Eko ni Tinuade fi se ibujoko, ko to jade laye.

Ki lo pa Mama Tinuade Ladoja?

Aworan oloogbe Tinuade Ladoja

Oríṣun àwòrán, Others

Bakan naa ni ijọ Celestial to wa ni agbegbe Ikeja nilu Eko, ti Oloogbe Tinuade Ladoja n lọ, naa ti kede iku eekan ọmọ ijọ rẹ naa.

Nigba to n salaye bi mama naa se jade laye, Benjamin Olukoya, tii se olori ijọ Celestial ni Ikeja wa salaye aayan ti wọn se lati doola ẹmi mama naa.

"A gbe Mama Tinuade Ladoja lọ sile iwosan nigba to ku ọjọ meji ti wọn yoo jade laye, ti ara wọn si ti n ya, ko to di pe Ọlọjọ de ni aarọ ọjọ Aje.''

Ninu ọrọ tiẹ, alaga igbimọ awọn obinrin ni ijọ CCC, Victoria Omodudu, sọ pe oun si ranti igba toun ṣabẹwo si oloogbe naa kẹyin lọjọ karun un oṣu kẹwaa ọdun 2024 yii.

O ni oun ko ri apẹẹrẹ wi pe bo ya o aarẹ tabi aisan kan n ṣe e nigba naa.

Loṣu Kẹrin ọdun yii ni Arabinrin Tinuade ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mọkanlelaadọin loke eepẹ.

"Mama Tinuade Ladoja wà lara igbimọ to n dari ijọ amọ a gba fun Ọlọrun lori iku rẹ"

Bakan naa ni ijọ Celestial Ikeja sọrọ nipa bi iku oloogbe naa se ka lara si ati ipa to n ko ninu idagbasoke ijọ naa, ko to jade laye.

Oju opo ayelujara Facebook rẹ ni ikede iku aya Ladoja ọhun ti waye.

Ijọ naa si fidi rẹ mulẹ pe oloogbe Tinuade wa lara awọn agba ọmọ ijọ to wa ninu igbimọ to n se ipinnu fun ijọ naa.

Ijọ Celestial Ikeja fikun pe ọmọ ijọ ti ko se fi ọwọ rọ sẹyin ni mama Tinuade amọ oun gba fun Ọlọrun lori iku rẹ.