Èèyàn mẹ́fà jáde láyé nínú ìjàmbá ọkọ̀ ní Ibadan

Ibi tí ìjàmbá ọkọ̀ náà ti wáyé

Oríṣun àwòrán, Ademola Adegbite/The Punch

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹwàá ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ́ gba ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èèyàn ní agbègbè Oke-Eleshin, agbègbè Amuloko, ìjọba ìbílẹ̀ Ona Ara, Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo.

Ìròyìn ní òpópónà tó lọ sí oríkò ìjọba ìbílẹ̀ ọ̀hún ni ìjàmbá ọkọ̀ náà ti wáyé tó sì ṣokùnfà ikú ọ̀pọ̀ èèyàn.

Ọkọ̀ ńlá kan àti ọkọ̀ mìíràn tó kó ọtí ẹlẹ́rìmdòdò ni wọ́n ní ó kọlu ara wọn níbi òpópónà náà.

Èèyàn mẹ́fà ni ìjàmbá ọkọ̀ náà gbẹ̀mí lọ́rùn wọn, táwọn márùn-ún mìíràn sì farapa.

Ìròyìn ní ọmọdé kan lára àwọn tó farapa ló pàdánù ìyá lásìkò ìjàmbá ọkọ̀ ọ̀hún.

Àwọn tí ìjàmbá náà ṣojú wọn ṣàlàyé pé ọkọ̀ ńlá náà ló pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì lọ kọlu kẹ̀kẹ́ kan.

Ó ní níbi tí ọkọ̀ tó ń gbé ọtí ẹlẹ́rìndòdò tó ń bọ̀ lẹ́yìn ọkọ̀ ńlá náà ṣe ń gbìyànjú láti má kọlu ọkọ̀ tó pàdánù ìjánu rẹ̀ ni òhun náà lọ kọlu kẹ̀kẹ́ mìíràn.

Ó sọ pé èèyàn mẹ́fà ló jáde láyé táwọn òṣìṣẹ́ ààbò sì ti gbé wọn kúrò níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Àwọn èèyàn tó wà ní agbègbè náà bu ẹnu àtẹ́ lu dẹ́rẹ́bà ọkọ̀ tó wa ọkọ̀ ńlá náà pé kò bá ti wa ọkọ̀ rẹ̀ wọnú gọ́tà tó wà níbi agbègbè náà dípò bó ṣe lọ kọjú sí kẹ̀kẹ́ tó sì dá ẹ̀mí àwọn èèyàn légbodò.

Wọ́n ní ilé ìwòsàn kan Amuloko City Hospital tó wà ní agbègbè náà ni wọ́n kó àwọn tó farapa lọ fún ìtọ́jú.