‘Gbìyànjú tàbí ko dágbére fáyé’ - ìpinnu láti dé Canary Islands

Mouhamed Oualy
    • Author, Blanca Munoz, Chris Alcock & Mame Cheikh Mbaye
    • Role, For BBC Africa Eye
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Àkọlé fídíò, Àláyé lórí báwọn èèyàn ṣe ń wá ayé ìrọ̀rùn lọ sí òkè òkun

Àgbẹ̀ ọmọ orílẹ̀ èdè Senegal, Mouhamed Oualy kò dè odò ńlá rí àmọ́ ó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò kan lórí alagbalúgbú omi – èyí tó ti sọ odò Atlantic Ocean di ibojì òkú.

“Awọn ọlọ́kọ̀ ojú omi náà ti pè mí – wọ́n ní ki ń máa múra sílẹ̀. Mò ń rọ̀yín láti máa gbàdúrà fún mi – àsìkò náà ti tó báyìí,” ó sọ.

BBC Africa Eye ti ríbi wọ àwọn tó ń ṣe ìrìnàjò lọ sí ilẹ̀ Yúróòpù gba orí omi láàárín ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà àti Spain tí ọ̀gbẹ́ni Oualy sì wà lára àwọn tó ń gbèrò láti lọ sí ọ̀kan lára àwọn tó fẹ́ ṣe ìrìnàjò náà.

Ìjọba ẹkùn àwọn erékùsù tí wọ́n ń gbèrò láti lọ ọ̀hún ti ṣèkìlọ̀ pé kò sí nǹkankan fún àwọn tó fẹ́ ṣe ìrìnàjò wá sí ọ̀dọ́ àwọn náà àmọ́ kò sí nǹkan tó lè yí ọkàn Oulay padà.

Wọ́n lè lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ nínú nínú ọkọ̀ ojú omi táwọn apẹja máa ń lò, tí wọ́n fi pákó kàn lórí alagbalúgbú omi.

Láti orílẹ̀ èdè Senegal, ìrìnàjò náà tó ìrìn kílómítà ẹgbẹ̀rún kan (máìlì ẹgbẹ̀fà) sí kílómítà ẹgbàá tí wọ́n tí wọ́n máa lò lórí omi. Bákan náà ló jìnà ní ìwọ̀n ẹ̀ẹmẹ̀wá sí ti àwọn tí wọ́n máa ń gba orí omi Mediterranean.

Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn arìnrìnàjò yìí máa ń kojú ìṣòro àìrí omi mu àti àárẹ̀ lójú ọ̀nà.

Àwọn arìnrìnàjò tó ń fi alẹ́ wọ El Hierro
Àkọlé àwòrán, Iye àwọn arìnrìnàjò tó ti dé El Hierro ti lé ní iye aráàlú

Ní ìlú Tambacounda, tó wà ní ìlà oòrùn Senegal, àwọn ọmọ Oualy àti ẹbí rẹ̀ ni wọ́n máa ń wojú rẹ̀ fún jíjẹ látara owó tó bá pa níbi iṣẹ́ oko tó ń dá.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oualy, ẹni ogọjì ọdún náà kò ì tíì fojú kan àwọn ẹbí rẹ̀ láti bíi ọdún kan tó ti fi ilé sílẹ̀ láti súnmọ́ ìlú tó wà ní agbègbè etídò tí wọ́n máa gbà ṣe ìrìnàjò ọ̀hún.

Iṣẹ́ ọ̀kadà gígùn ló ń ṣe níbẹ̀ láti kó ẹgbẹ̀rún kan dọ́là jọ tó máa fún àwọn àwọn tó máa fi ọkọ̀ ojú omi gbé wọn lọ sí Canray Islands.

Ó ní nítorí òun kò fẹ́ kí gbá òun, òun ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọnawakọ̀ náà pé ó dìgbà tí òun bá dé orílẹ̀ èdè tí àwọn ń lọ ni òun tó máa san owó wọn pé.

“Kò sí ẹni tó mọ nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ sí mi lórí omi yìí. Àwọn ẹ̀mí àìrí tó wà nínú odò le ṣekúpa mí,” ó sọ fún BBC láti orí àga tó wà.

“Ọkọ̀ lè dànù kó pa gbogbo wa papọ̀, tí èèyàn bá jábọ́ sínú omi, kò sí ohun tí ẹni bẹ́ẹ̀ lè dìmú, ikú ló kàn bẹ́yẹn àmọ́ èèyàn gbọ́dọ̀ fẹ̀mí ara rẹ̀ wéwu.

Tí Oualy bá fi lè móríbọ́ lásìkò ìrìnàjò yìí , ó fẹ́ lọ ṣiṣẹ́ láti lè fi bọ́ àwọn ẹbí rẹ̀ àmọ́ kò fi inú han ẹnìkan báyìí kí àwón èèyàn rẹ̀ má filè dàámú.

Gẹ́gẹ́ bí ilé ìfowópamọ́ àgbáyé ṣe sọ, ìdá kan nínú ìdámẹ́ta àwọn èèyàn tó ń gbé ní Senegal ló wà nínú ìṣẹ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè náà ti gbèèrú si láti ọdún 2010.

Oualy ṣàlàyé pé kò sí iṣẹ́ tí òun kò ṣe tán àmọ́ nǹkan kò yàtọ̀ fún òun àti pé ẹni tí kò bá ti lówó lọ́wọ́ kò já mọ́ nǹkankan.

Bíi Oualy, ọ̀pọ̀ àọn tó fẹ́ ṣe ìrìnàjò kúrò ní Sub-Saharan African ni wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ láti bọ́ lọ́wọ́ ìṣẹ́ àti òṣì, wàhálà tí àyípadà ojú ọjọ́ ń fà.

Canary Islands ti dàbí ọ̀nà tí àwọn tó bá fẹ́ ṣe ìrìnàjò lọ sí Yúróòpù lọ́nà àìtọ́ máa ń gbà pàápàá lẹ́yìn tí Italy àti Greece ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti mú àdínkù bá bí àwọn arìnrìnàjò ṣe ń gba odò Mediterranean láti Libya àti Tunisia wọ orílẹ̀ èdè wọn.

Èèyàn tó fẹ́ẹ̀ ltó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì ló wọ Canary Island ní ọdún 2023 nìkan. Ní ọdún yìí nìkan èèyàn tó ti lé ní 30,800 ló ti wà ní ẹnubodè ibẹ̀.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú BBC Africa Eye, ààrẹ ìjọba Canary Islands, Fernando Clavijo ní àwọn ọlọ́pàá, àwọn òṣìṣẹ́ pàjáwìrì àtàwọn adóòlà ẹ̀mí inú odò ní wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ kọjá agbára wọn.

Fernando Clavijo
Getty Images
Every 45 minutes, a migrant dies trying to reach our beaches. This means trafficking mafias are increasingly becoming more powerful."
Fernando Clavijo
President of the Canary Islands

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú BBC Africa Eye, ààrẹ ìjọba Canary Islands, Fernando Clavijo ní àwọn ọlọ́pàá, àwọn òṣìṣẹ́ pàjáwìrì àtàwọn adóòlà ẹ̀mí inú odò ní wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ kọjá agbára wọn.

Ó ní ohun tó túmọ̀ sí ni pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló ṣì máa kú si, tí àwọn kò ní lè ṣe ìrànwọ́ fún wọn bó ṣe yẹ.

“Ní báyìí, Yúróòpù ti gbé odò Mediterranean Sea tì pa, èyí tó túmọ̀ sí pé Atlantic, tó léwu ju Mediterranean lọ ni àwọn èèyàn ń fàbọ̀ sí báyìí.

BBC bá àwọn òṣìṣẹ́ pàjáwìrì Spain sọ̀rọ̀ tí wọ́n ní àwọn kò fẹ́ kí a dárúkọ wọn ní ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ni ó ti sú bí wan ṣe ń rí àwọn òkú ní gbogbo ìgbà.

Ní El Hierro, àwọn arìnrìnàjò tó ti wọ ibẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2023 ti lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n, èyí tó ti fẹ́ ju iye àwọn ará ìlú tó wà níbẹ̀ lọ.

Clavijo ní ọ̀pọ̀ àwọn ọkọ̀ tó wà fún ará ìlú ni wọ́n fi ń gbé àwọn àjòjì tí ìbẹ̀rù sì wà pé ó lè fa kí àwọn ará ìlú bẹ̀rẹ̀ ìjà pẹ̀lú àwọn àjòjì náà.

Ó wòye pé ìjọba Yúróòpù àti ti Spain nílò láti dá sí ọ̀rọ̀ náà nítorí wọ́n kò lè fi Canary Islands sílẹ̀ láti máa kojú wàhálà náà fúnra wọn.

Láti bíi oṣù mélòó kan, bí àwọn arìnrìnàjò ṣe ń yawọ orílẹ̀ èdè Spain lọ́nà àìtọ́ ti ń mú kí ìjọba máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n nílò láti fi kojú ìṣòro náà.

Padà ní Senegal, àwọn onífàyàwọ́ tí wọ́n máa ń kó àwọn èèyàn rinm ìrìnàjò orí omi náà ti pe Oluay láti pàdé ní àhámọ́ wọn kan.

“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa la wà níbí, a kún inú ilé náà fọ́fọ́. Àwọn èèyàn láti Mali, Guinea pẹ̀lú wa. Ọkọ̀ ojú omi kékeré ni wọ́n fi ń kó wa ní mẹ́wàá mẹ́wàá lọ sínú ọkọ̀ ojú omi ńlá.”

Oluay ló kó omi àti àwọn ìpápátè tí yóò máa jẹ dání lásìkò ììnàjò rẹ̀.

Ó ní òun kò gbádùn fún ọjọ́ méjì àkọ́kọ́ àti pé omi òun padà tán nígbà tó yá tó jẹ́ pé omi odò ni òun ń bù mu.

Àkọlé fídíò, WATCH: Wo bí ojú ojú omi ṣe gbé Oluay

Gẹ́gẹ́ bí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ṣe sọ, odò Atlantic jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó burú táwọn arìnrìnàjò ń gbà báyìí. Èèyàn 807 ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn sínú odò náà ní ọdún 2024 nìkan.

Wọ́n ní ó ṣeéṣe kó jù bẹ́ẹ̀ lọ nítorí ọ̀pọ̀ ìjàmbá tó ń wáyé níbẹ̀ ni kò ní àkọ́ọ́lẹ̀.

Bákan náà ni ẹ̀ka tó ń rí sí oògùn àti ìwà ọ̀daràn ní àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ní àwọn máa ń rí owọ tó lé ní $150m ní ọdún kan ní ọ̀nà náà.

Wọ́n ní wọ́n máa ń gbé àwọn arìnrìnàjò náà bí ẹni tó ń kó ẹrù láì bìkítà kan.

Láti mọ bí àwọn ọ̀daràn náà ṣe ń ṣiṣẹ́, BBC bá ọ̀kan lára àwọn onífàyàwọ́ Senegal sọ̀rọ̀, ó ní tí àwọn bá ń gba $500 dọ́là lọ́wọ́ èèyàn kọ̀ọ̀kan, táwọn sì gbé èèyàn 200 sí 300, owó ti dé nìyẹn.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun gbà pé ìwà ọ̀daràn ni òun ń hú, ó ní ẹni tí ọwa òfin bá tẹ̀ kó lọ fojú winá òfin ni àmọ́ kò sí ojútùú sọ̀rọ̀ náà.

Fún ọjọ́ márùn-ún, BBC kò gbọ́ nǹkankan láti ọ̀dọ̀ Oluay àmọ́ nígbà tó di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ó pè.

Máàpù tó ń ṣe àfihàn ìrìnàjò láti Senegal sí Canary Islands

Oualy ṣàlàyé pé ọks ojú omi àwọn bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣàdédé gbóná, tí atẹ́gùn líle sì ń fẹ́, àwọn apẹja sọ fún awakọ̀ wa pé kí ó mórílé Morocco àmọ́ awakọ̀ náà ní tí òun kò bá sáré àwọn máa dé Spain ní aago mẹ́fà òwúrọ̀ ọjọ́ kejì.

Ó ní ó ku ọjọ́ kan kí àwọn de Canary Island ni éńgíìnì ọkọ̀ àwọn bàjẹ́ táwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ sí awakọ̀ àwọn, ó ní èyí ló mú kí awakọ̀ náà gbà sí àwọn èèyàn lẹ́nu, tó sì padà sí Senegal.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Oualy kò parẹ́ sínú ìrìnàjò rẹ̀ àmọ́ ó farapa .

Lẹ́yìn ọdún kan tó fi ṣe ìpalẹ̀mọ́ láti lọ fún ìrìnàjò náà, ó tún ti padà sí ẹsẹ̀ àárọ̀ rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀, tó sì ń kówó jọ láti fi ṣe ìrìnàjò mìíràn.

“Ó wù mí láti padà lọ. Ìgbàgbọ́ mi ni pé ibẹ̀ máa sàn fún mi. Bí mo bá kú náà, bó ṣe wu Ọlọ́run nìyẹn.”

Tí Oualy bá mórídé Yúróòpù, ó ṣeéṣe kí àwọn ẹbí rẹ̀ má ri fún ìgbà díẹ̀ lásán ni àmọ́ tó bá kú sínú odò, wọ́n ti pàdánù rẹ̀ láyé nìyẹn.