Akọni èèyàn ni ọmọbìnrin mi tó jáde láyé, Saidi Balogun sọ̀rọ̀ lórí ikú Zeenat Balogun

Oríṣun àwòrán, Saidi Balogun/Instagram
Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Saidi Balogun, ti ṣapejuwe ọmọbinrin rẹ, Zeenat Balogun to ku laipẹ yii gẹgẹ bii akọni eeyan.
Balogun sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita loju opo Instagram rẹ lọjọ Aiku.
Ni owurọ ọjọ Ẹti, ọjọ karun un, oṣu Kẹwaa yii ni ilumọọka oṣere naa kede iku ọmọ rẹ ninu atẹjade to fi lede loju opo Instagram rẹ.
Ninu atẹjade ti o fi lede loju opo Instagram rẹ lọjọ Aiku lorukọ idile Balogun ni o ti ki gbogbo ọrẹ, awọn akẹgbẹ rẹ ati gbogbo eeyan to kẹdun pẹlu idile rẹ lasiko ti ọmọ naa jade laye.
O ṣapejuwe ọmọbinrin naa gẹgẹ bi obinrin ogun to gbe igbe aye rẹ daadaa ti o si maa n kun fun ayọ nigbogbo igba.
''Zeenat jẹ ẹnikan ti kii gbagbọ wi pe oun ni le ni ijakulẹ ninu ohun kohun to ba n ṣe''
''Zeenat jẹ ẹnikan ti kii gbagbọ wi pe oun ni le ni ijakulẹ ninu ohun kohun to ba n ṣe.
Zeenat tun jẹ ọmọ kan to maa n kun fun ireti nigba gbogbo, o ni ọmọ naa gbọn bi obinrin to ti wa nile ọkọ.
Gbogbo eeyan ti Zeenat ba ni ibaṣepọ pẹlu ni o fi ifẹ han si nigba aye rẹ.
Awọn nkan wọnyii ni a maa fi ṣe iranti rẹ lẹyin ti o ti fi aye yii silẹ.
Ọjọ meji to ṣe pataki julọ laye ni ọjọ ti a bi wa saye ati ọjọ ti a ba ku.
Ṣugbọn ohun ti o ṣe pataki ni pe ki a gbe ile aye ṣe rere, Zeenat maa n gbiyanju lati ṣe ohun to dara ni gbogbo igba fun ẹbi rẹ atawọn eeyan,’’ ẹbi Balogun lo sọ bẹẹ ninu atẹjade ti Saidi fi lede loju opo Instgram rẹ.
Saidi tẹsiwaju ninu atẹjade ọhun lẹyin to sọ pe ọmọbinrin oun to doloogbe naa maa n sọ foun lọpọ igba wi pe ‘’ko dẹ wa ri bẹẹ oo, baba mi, amọ, mo maa yipada.’’
Agbaọjẹ oṣere naa ni ko si nnkan toun le yipada ninu iwa ọmọ oun to doloogbe.
O ni orukọ ọmọ naa maa n ro o ni gbogbo igba, tori o jẹ onirẹlẹ, olododo, o si tun ni omi aanu loju.
Ilumọọka oṣere naa sọ wi pe, Eledumare lo n fun ni lọmọ, oun naa si lo n gba a.
O wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ ọmọ naa si afẹfẹ rere.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post












