Ẹ má dìbò, kẹ́ ẹ́ sebẹ̀ l‘Ondo, èmi ni kí ẹ dìbò gómìnà fún, kí àyípadà rèrè le è wà - Agboola Ajayi

Àkọlé fídíò, Ondo Election: Olùdíje PDP ní àwọn èèyàn Ondo ni yóò sọ bóyá wọn fẹ́ bọ́ nínú ìyà
    • Author, Olumide Owaduge, Adedayo Okedare
    • Role, BBC Journalist
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Odu ni Ọlọla Alfred Agboola Ajayi ninu awọn oloselu nipinlẹ Ondo, kii se aimọ fawọn oloko nitori awọn ipa takuntakun to ti ko lagbo oselu.

Agboola Ajayi, to n du ipo gomina bii oludije fun ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ naa, lo ti jẹ igbakeji gomina tẹlẹ ni saa akọkọ isejọba Rotimi Akredolu.

Bakan naa lo ti jẹ Kanselọ alakoso ri, o tun jẹ alaga ijọba ibilẹ ri, to si tun ti lọ sile igibmọ asofin agba.

BBC Yoruba wa ba Agboola Ajayi sọrọ lati idi to se fẹ jẹ gomina ipinlẹ Ondo ati awọn ayipada tuntun to fẹ mu ba ipinlẹ naa.

Agboola Ajayi

"O yẹ ki ofin fun awọn igbakeji gomina ni ojuse to yẹ lati se nitori ọpọ ipinlẹ ni awọn gomina ati igbakeji wọn maa n ja tori ojuse"

Nigba to n salaye awọn iriri to ni lagbo oselu, Agboola Ajayi sọ awọn ipo to di di mu ati idi ti aawọ fi maa n wa laarin igbakeji gomina ati awọn gomina.

"Ti mo ba se gomina, maa se ju bi awọn atẹyinwa ti se, tori mo ri asiri rẹ daadaa.

Tori mo ti se igbakeji gomina tẹlẹ, o jẹ ki n mọ bi ipinlẹ Ondo se ri ati iyatọ to wa laarin gomina ati igbakeji rẹ.

O tun jẹ ki n mọ pe o yẹ kawọn asofin apapọ ni Abuja yẹ ki wọn se atunse si iwe ofin orilẹede Naijiria to da ipo igbakeji gomina silẹ.

O yẹ ki ofin fun awọn igbakeji gomina ni ojuse to yẹ lati se nitori ọpọ ipinlẹ ni awọn gomina ati igbakeji wọn maa n ja tori ojuse.

“Igbakeji gomina ti mo se jẹ ki n mọ bi ipinlẹ Ondo se ri ati iyatọ to wa laarin gomina ati igbakeji rẹ.

Mo ti se Kanselọ alakoso ri, mo se alaga kansu ri, mo lọ sile igbimọ agba, mo mọ gbogbo ayika wa ati ohun ti a le se."

Ajayi and Akeredolu

"Maa gba awọn olukọ sẹnu isẹ nitori nile ẹkọ miran, Tisa meji pere lo wa ni odidi ile ẹkọ kan ni agbegbe Ilaje"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agboola Ajayi tun salaye idi to se fẹ di gomina nipinlẹ Ondo.

"Mo fẹ lati di gomina ki n ran awọn eeyan ipinlẹ wa lọwọ lati yi aye wọn pada si rere.

Gbogbo eeyan lo mọ bawọn ajinigbe se n gbe wa nipinlẹ Ondo, wọn n gbe ọba, wn n gbe ijoye, mo fẹ fi opin si eleyi.

Bakan naa a tunbọ se agbende ọrọ aje wa nipinlẹ Ondo eyi ti yoo se gbọkan le.

Ko sibi ti owo ko si nipinlẹ yii, amọ maa se awọn ohun eelo amayedẹrun sipinlẹ yii, ki awọn to fẹ sowo ati ọrọ Aje le wa.

Ni Ilaje/Ẹsẹ Odo, a sun mọ okun pupọ, ti a si sunmọ Eko. Ti ibudo oju omi wa, ti a si ni ibudo ti wọn ti n ja ẹru, awọn eeyan ko ni maa lọ si Eko mọ lati ja ẹru.

Lori eto ẹkọ, lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ si girama, awọn ọmọ wa ko ni sanwo ile ẹkọ mọ ti mo ba di gomina, eto ẹkọ ni maa se.

A gba awọn olukọ si sẹnu isẹ nitori nile ẹk miran, Tisa meji pere lo wa ni odidi ile ẹk kan ni agbegbe Ilaje.

Awọn olukọ yii lo maa kọ kilaasi alakọbẹrẹ kinni, ikeji, ikẹta, ikẹrin, ikarun ati ikẹfa, bawo ni awọn akẹk yoo se yege ninu idanwo.

Maa tun pese awọn ohun elo ikẹkọ, ti awọn to n wa isẹ yoo si ri isẹ.

Mo ni agbekalẹ eto isejọba onikoko meje fun ipinlẹ Ondo ti mo ba di gomina."

Ajayi ati Olubayode

"Ibo ni wọn maa fi n san oore fun oloselu, ti wọn ba ni ijọba kan ko dara, a gbọdọ fi ibo yipada"

Agboola Ajayi wa sẹ lori ahesọ ọrọ kan to ni o ni baba isalẹ, to si rọ awọn eeyan nipinlẹ Ondo lati fi ibo yan oun bii gomina wọn.

"N ko ni baba isalẹ kankan, Ọlọrun ni baba isalẹ mi, mo kan n se temi bi Ọlọrun se ran mi ni.

Ko si ẹni to le sọ pe oun ni baba isalẹ oloselu fun mi, Ọlọrun nikan ni fun emi o.

Ibo ti a fẹ di yii, awọn eeyan gbọdọ maa fi ọwọ ara wọn tun iwa ara wọn se, wọn gbọdọ fi ọwọ ara wọn yan gomina to wu wọn.

Wọn gbọdọ mọ boya wọn si fẹ maa jẹ iya yii lọwọ abi wọn fẹ ko ara wọn kuro ninu iya, ibo la maa fi se.

Ibo ni wọn maa fi n san oore fun oloselu, ti wọn ba ni ijọba kan ko dara, a gbọdọ fi ibo yipada.

Ko dara ki wọn dibo, ki wọn ni awọn fẹ se ọbẹ, ohun ti ko ba oju mu ni, ohun to si sun wa de ibi ti a de bayii niyẹn.

Mo rọ awọn eeyan pe ki wọn jade, ki wọn mase lero pe awọn kan yoo ji ibo wọn tabi se ohunkohun si wọn.

Ki awọn eeyan wa gbadura pe ki lọrun tọ wa sọna. Mo si mọ pe emi ni wọn maa di ibo wọn fun tori wọn mọ ohun ti mo le se."