Èmi kò ní ṣe akótilétà ọmọ ọ̀dọ̀, tẹ́ ẹ bá dìbò fún mí gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo - Mimiko

Àkọlé fídíò, Èmi ò ní ṣe akótilétà ọmọ ọ̀dọ̀, tẹ́ ẹ bá dìbò fún mí gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo - Abas
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oludije sipo gomina ipinlẹ Ondo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party (ZLP), Dokita Abass Mimiko, ti sọ pe iṣejọba ti Naijiria ko ri iru rẹ ri ni oun yoo ṣe.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2024, ni idibo gomina yoo waye nipinl Ondo.

Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu BBC Yoruba, ni Dokita Abass Mimiko ti ṣalaye pe oun fẹ ṣe gomina ipinlẹ Ondo nitori a ti pese ounjẹ, omi ati eto iwosan to dara fun awọn mẹkunnu.

“Mẹkunnu o ri ounjẹ jẹ, wọn o ri omi mu, awọn akẹkọọ ko ri ẹkọ kọ, bẹẹni awọn oniṣẹ ọwọ ko ri iṣẹ sẹ nitori wọn ko ri owo.”

Dokita Mimiko sọ pe gbogbo nnkan ti oun wo niyii ti oun fi pinnu lati dije fun ipo gomina ninu eto idibo ti yoo waye ni ọdun 2024.

Abass Mimiko

Oríṣun àwòrán, Abass Mimiko

Àkọlé àwòrán, Abass Mimiko sọ pe lootọ ni ẹgbọn oun ti ṣe gomina ipinlẹ Onod ri, amọ oun ko nilo ontẹ rẹ lati di gomina

Lori bi awọn kan ṣe n bu ẹnu atẹ luu pe o ni oun ko nilo ontẹ ẹgbọn rẹ, Olusegun Mimiko, lati de ipo gomina ipinlẹ Ondo, o ni nnkan ti ọpọ n reti ni pe ki Olusegun Mimiko na ọwọ oun soke, ko si ke si gbogbo eniyan ipinlẹ Ondo lati dibo fun aburo rẹ.

Olusegun Mimiko ti fi igba kan jẹ gomina ipinlẹ Ondo laarin ọdun si

‘Iwa palapala ni mo ri eyi si.

‘Tẹgbọn-taburo la jẹ lootọ, amọ nipa ti oṣelu, kaluku n ṣe tirẹ ni.’

Dokita Abass Mimiko sọ pe ẹlomii ni ẹgbọn oun n ṣe atilẹyin fun lati di gomina, o ni amọ iyẹn o ni ki awọn ma jẹ ọmọ iya kan naa mọ.

Awọn ileri ti Dokita Abass Mimiko n ṣe fun ipinlẹ Ondo

Dokita Abass Mimiko ṣalaye pe lootọ ni awọn eeyan kan ṣọ pe oun ko ni iriri ninu iṣejọba, ‘lootọ ni, ṣugbọn ki wọn o lọ wo awọn ipa ti mo ni ni awọn ibi ti mo ti ṣiṣẹ ri’.

  • Ṣiṣe kan-n-ga omi igbalode (Borehole) si gbogbo ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Ondo
  • Dida iṣẹ silẹ fun gbogbo mẹkunnu
  • Ile kikọ fun awọn mẹkunnnu
  • Eto ilera fun awọn alaboyun
  • Eto iwosan ọfẹ fun awọn ọmọ wẹwẹ titi di ọmọ ọdun mẹfa
  • Eto ilera ọfẹ fun awọn agbalagba ti ọjọ ori wọn ti pe aadọrin ọ̀un soke
  • Dida awọn bọọsi ọfẹ pada lati maa ko awọn akẹkọọ lọ si ile ẹkọ wọn
  • Idagbasoke nnkan ọgbin, ati igbedide awọn nnkan alumọni ipinlẹ naa

O fi kun ọrọ rẹ pe ọkan to dara ati ero rere ni oun ni fun awọn eniyan ipinlẹ Ondo.

Bakan naa lo sọ pe oun ko ni i ni baba isalẹ kankan ti yoo maa ṣe idiwọ fun iṣakoso rere.