Makinde ní ìjọba ṣetán láti san N70,000 gẹ́gẹ́ bíi owó oṣù tó kéré jùlọ l'Oyo àmọ́ ìdúnàdúrà gbọdọ̀ wáyé

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti kede pe ijọba oun yoo san N70,000 ti Aarẹ Bola Tinubu buwọlu gẹgẹ bi owo oṣu tuntun oṣiṣẹ to kere julọ lorilẹede Naijiria.
Makinde ni ijọba yoo bẹrẹ si ni san owo naa lẹyin ti ọrọ atunṣe lori owo oṣu ba ti ni iyanju tan.
Ọrọ yii jẹyọ ninu atẹjade kan ti oludamọran gomina ipinlẹ Oyo lori eto iroyin, Ọgbẹni Sulaimon Olanrewaju, fi sita.
Bakan naa ni gomina ipinlẹ Oyo tun kede wi pe N25,000 owo iranwọ ti ijọba n san fawọn oṣiṣẹ ati N15,000 fawọn oṣiṣẹ fẹyinti yoo tẹsiwaju si fun oṣu mẹta mii.
O ni sisun sisan owo iranwọ naa ṣiwaju ni ṣe pẹlu idunadura ti yoo waye laarin ijọba atawọn oṣiṣẹ nipa atunṣe lori owo oṣu.
Gomina Makinde sọ pe ijọba oun yoo da sisan owo iranwọ fawọn oṣiṣẹ duro, kete ti ijọba atawọn oṣiṣẹ ba ti sọ asọyepọ tan lori ọrọ owo oṣu tuntun.
Makinde ni ‘’idunadura yoo bẹrẹ bayii lori ọrọ owo oṣu tuntun, a si ti ṣetan lati san N70,000 gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.
Amọ, ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati ijọba yoo jọ jokoo sọ asọyepọ lori owo oṣu tuntun naa.
Makinde to lo anfaani naa lati ki awọn olukọ lori ayajọ ọjọ awọn olukọ eyi to waye lọjọ Abamẹta ti i ṣe ọjọ karun un oṣu Kẹwaa ọdun 2024 yii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















