Omíyalé ṣọsẹ́ ní ìpínlẹ̀ Ondo, ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò

Oríṣun àwòrán, Ajibola Omotayo
Ọpọlọpọ dukia olowo iyebiye, ninu eyi ti awọn ọkọ ati ile wa, ni wọn bajẹ leyin ojo arọrọda kan to rọ lọjọ Ẹti ni ijọba ibilẹ iwọ-orun Ondo nipinlẹ Ondo.
Ojo naa bẹrẹ ni ago mẹta irọlẹ ti o si ṣe kẹrẹkẹrẹ bẹrẹ si ni i ṣarajọ debi pe gbogbo oju odo, oju agbara ati oju popo bẹrẹ si ni i kun.
Awọn agbegbe ti iṣẹlẹ naa kan lawọn agbegbe bii Opopna Ita-Nla, Oke Odunwo, Oke-Idera, Iluyemi, Oluwabamikole, Odojomu, Bethlehem, Gani Fawehinmi, Iranlowo, Ife garage, St. Andrews ati Ife Road.
Ọkan lara awọn olugbe ilu naa sọ pe agbegbe Ita-Nla ni omiyale naa ti lagbara julọ nibi ti o ni omi agbara ti bo ori ọpọlọpọ ọkọ, Ọkada, awọn ile itaja, Ile igbe titi kan awọn dukia olowo nla miran.

Oríṣun àwòrán, Ajibola Omotayo
Ṣugbọn emi kankan ko sọnu ninu ijamba naa titi di asiko yi.
Awọn olugbe ilu naa sọpe awọn oju agbara to di lawọn agbegbe ti iṣẹlẹ yii ti waye lo sakọba fun ijamba naa, eyi ti ko jẹ ki agbara ri ọna kọja to mu ki agbara naa ya si aarin igboro.
Awọn Olugbe naa kesi ijọba lati dide fun iranwọ wọn nitori ọpọlọpọ awọn onisowo lo farakasa ijamba yii, bi wọn ṣe padanu ọpọlọpọ ọja olowo iyebiye lasiko omiyale naa.
Wọn ni ijọba nilo lati ko awọn oju agbara ilu Ondo lati le yẹra fun iṣẹlẹ omiyale eyi to le sakoba fun ọrọ-aje awọn ara ilu lọjọ iwaju.
Kí ni ìjọba sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà?

Oríṣun àwòrán, Screenshot/ ajibola omotayo
Ijọba Ipinlẹ Ondo ti ba Osemawe tilu Ondo Ọba Victor Kiladejo ati gbogbo olugbe ilu naa kẹdun lori iṣẹlẹ omiyale to waye lọjọ Ẹti.
Gomina Lucky Orimisan Aiyedatiwa ti paṣẹ ki gbogbo awọn eniyan tó wa lagbegbe ibi ti iṣẹlẹ tí waye kuro lagbegbe naa lati le yẹra fun irufẹ iṣẹlẹ yii lọjọ iwaju, bi wọn ṣe pasẹ fun gbogbo awọn ajọ ijọba to n risi iṣẹlẹ pajawiri ati omiyale lati bọ soju isẹ ni kíákíá lati le madinku ba akoba ti ijmba naa yoo se.
Saaju ni Kọmisana to n bojuto ọrọ ayika ati agbegbe Oyeniyi Oseni ninu atejade ti sọ pe ijọba Ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ isẹ lati ko awọn oju agbara ni ilu Ondo lati bi Ọsẹ meji sẹyin papa julọ lawọn agbegbe ti omiyale naa ti waye.

Oríṣun àwòrán, Screnshot/ Ajibola Omotayọ
Oseni sọpe iwadii ti fi han pe wọn gbọdọ pakitimọra lati la awọn oju agbara lawọn oriko miran ki aye le gba agbara lati kọja lai si wahala kan bio ti wu o mọ.
Kọmisana naa sọ pe bii awọn eniyan se n kọ ile si oju agbara lagbegbe Fagun lo tubọ ṣe akoba fun iṣẹlẹ yi,bi o ṣe sọpe ki kọ ile soju agbara jẹ ohun ti ko bojumu ti wọn yoo si gbe igbese to lagbara lori rẹ.
Oseni fi da awọn olugbe agbegbe naa loju pe awọn ọkọ to n ṣiṣẹ naa yoo tẹsiwaju lati ma ko awọn oju agbara to ṣe koko n'ilu Ondo lati le yẹra fun irufẹ iṣẹlẹ yii lọjọ iwaju.















