Wo ohun tó ń ṣokùnfà ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi àti ọ̀nà láti dẹ́kun rẹ̀

Aworan oju omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Iṣẹ idoola ẹmi si n lọ lọwọ nibi ijamba ọkọ oju omi to ṣẹlẹ niluu Gbajibo ni Jebba nipinlẹ Niger.

Ọga agba ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Niger, Abdullahi Baba Arah ṣalaye pe awọn ero inu ọkọ oju omi naa n rinrin ajo lati ilu Mundi lọ si Gbajibo fun ayẹyẹ Mauludi ni ọkọ oju omi ti wọn wa ninu rẹ fi doju de.

O ni awọn ọmọde at'awọn obinrin lo pọju ninu awọn ero ọhun.

Ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ijamba naa ṣẹlẹ nigba ti ọkọ oju omi to ko ero bi ọdunrun un doju de loju agbami.

Ijọba ipinlẹ Niger ti fidi rẹ múlẹ pe aadọjọ eeyan l'awọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ti doola emi wọn bayii.

Ijọba ni wọn tun ti oku ọgbọn eeyan mii yọ bayii yatọ si mejidinlogun ti wọn kọkọ yọ tẹlẹ.

Ijamba ọkọ oju omi ti n wọpọ bayii ni Naijiria eyi to si n mu ọpọ ẹmi lọ nigba kugba to ba ti ṣẹlẹ.

Idi niyii ti a ṣe fẹ wo ohun to n ṣokunfa ijamba ọkọ oju omi ninu iroyin yii.

Nnkan mẹrin to n ṣokunfa ijamba ọkọ oju omi

Aworan ọkọ oju omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọgaagba ajọ NEMA to n ri si isẹlẹ pajawiri lẹkun aringbungbun Naijiria, Bshia Idris Garga ti sọ pe oriṣiiriṣii nnkan lo n ṣokunfa ijamba ọkọ ojumi.

Amọ, o ṣalaye wi pe koko mẹrin kan wa ninu wọn to maa n saba ṣokunfa ijamba ọkọ oju omi ni Naijiria.

Apọju ẹru kiko

Ọgaagba ajọ NEMA sọ pe apọju ẹru wa lara awọn nkan to maa n saba fa ijamba ọkọ oju omi.

Awọn akọṣẹmọṣẹ nipa iṣẹlẹ pajawiri ti sọ pe apọju ẹru maa n da ọkọ oju omi nigba mii.

Wọn ni ẹru gan an maa n pọ ju ero ninu ọkọ oju omi lọ nigba miran.

Apọju ero ninu ọkọ oju omi

Aworan ero ninu ọkọ oju omi

Oríṣun àwòrán, Others

Ọgaagba NEMA tun sọ pe apọju ero naa wa lara ohun to maa n ṣokunfa ijamba ọkọ oju omi.

O ṣalaye wi pe ọpọ ọkọ oju omi lo maa n ko ero tọ pọ ju agbara ọkọ wọn lọ nigba mii.

Ọkọ oju omi ti ko dara to

Ara ohun to maa n ṣokunfa ijamba ọkọ oju omi ni Naijiria gẹgẹ bi ọga NEMA ṣe sọ ni awọn ọkọ omi ti ko danganjia to.

Ọgaagba NEMA ni ọpọ ọkọ oju omi tawọn eeyan kan n gbe sori omi ni awọn ti wọn ṣe wọn ko tẹle ilana kikan ọkọ oju omi lọna igbalode.

Ọpọ awakọ oju omi ko ni iriri to

Ọgbẹni Garga tun sọ pe ọkan gboogi lara awọn ohun to n ṣokunfa ijamba ọkọ oju omi ni aini iriri ọpọ awọn awakọ oju omi jẹ.

O ni ọpọ to n wa ọkọ oju omi lorilẹede Naijiria ni wọn ko ni iriri to yẹ lati maa wa ọkọ naa.

Wo awọn ohun to le dena ijamba ọkọ oju omi

Ọgaagba NEMA tun sọ awọn ọna ti adinku fi le ba ijamba ọkọ oju omi to n ṣẹlẹ lera lera lorilẹede Naijiria.

Idasilẹ ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ oju omi

Ọgbẹni Garga sọ pe o maa dara ti ijọba ba le ṣe idasilẹ ajọ kan ti yoo maa mojuto igbokegbodo ọkọ oju omi.

O ni iru ajọ yii to ba n ṣakoso irin ajo lori omi lo le mọ awọn ọkọ oju omi to ba ti ni iṣoro to le ṣokunfa ijamba lori omi.

Lilo ọkọ oju omi to dara

Ọgaagba ajọ NEMA sọ pe lara ọna to le dẹkun ijamba ọkọ oju omi ni lilo ọkọ oju omi to dara wa.

O ni eyi yoo dẹkun gbigbe awọn ọkọ oju omi ti ko dara to soju omi eyi ti ọpọ awọn eeyan n ṣe.

Titẹle ofin nipa ikun omi

Ọgbẹni Garga sọ pe o ṣe pataki ki awọn ọlọpaa ti wọn maa mojuto ikun omi lati maa ṣiṣẹ wọn daadaa lọna to ba ofin mu.

O ni o yẹ ki wọn maa duro lori ẹsẹ wọn nigba kugba ti o ba lewu lati gbe ọkọ sori omi.

Idanilẹkọọ loorekoore

Ọga ajọ NEMA ni o yẹ ki idanilẹkọọ maa wa fawọn to n wa ọkọ oju omi loorekoore.

O ni eyi yoo jẹ ki wọn maa ṣọra ṣe lẹnu iṣẹ wọn.

Ṣiṣe ọna lawọn igberiko

Eleyii to tun dabi rẹ ni pe ọna ijọba ni lati ṣe ọna si ọpọlọpọ igberik.

Ọgbẹni Garga sọ pe ai sọna lọpọ igberiko lo jẹ kawọn eeyan maa wọ oju omi lọ si ibi ti wọn n lọ.

O rọ ijọba apapọ, ti ipinlẹ ati ijọba ibilẹ lati wa nnkan ṣe si ọrọ naa.