Ihò Eléérú, ibi tí àwọn àgbàgbà ìwáṣẹ̀ ìlú Isaarun ti ṣẹ̀ wá
Ihò Eléérú, ibi tí àwọn àgbàgbà ìwáṣẹ̀ ìlú Isaarun ti ṣẹ̀ wá
Ni ilu Saarun ni ipinlẹ Ondo, iho abẹ apata kan wa ti wọn n pe ni Iho eleeru.
Gẹgẹ bi ohun ti awọn eeyan ilu naa sọ, nibẹ ni awọn babanla wọn ti maa n dana ni igba iwasẹ ti wọn si ti n gbe igbe aye wọn.
Oju araye ṣi si agbegbe yii lẹyin ti awọn onimọ kan ṣe awari awọn ohun kan to jọ egungun ninu iho kan ni ilu Aṣarun eleyii ti wọn fi fi idi rẹ mulẹ pa awọn eeyan kan ti gbe ninu iho naa ri lọpọlọpọ ọdun sẹyin.
BBC News Yoruba ṣe abẹwo si ilu Asarun ati iho eleeru yii lati wo bi o ṣe rii ati iru igbe aye ti awọn ẹni iwaṣẹ gbe nibẹ.







