Àìṣaájò tó ló ń fìyà jẹ ọ̀pọ̀ ọmọ Yorùbá lónìí - Ọba Aje Ọbatala Agbaye

Àkọlé fídíò, Ìyàtọ̀ láàrin babaláwo àti oníṣègùn
Àìṣaájò tó ló ń fìyà jẹ ọ̀pọ̀ ọmọ Yorùbá lónìí - Ọba Aje Ọbatala Agbaye

Ọpọ eeyan ni ko mọ pe iyatọ wa laarin balawo ati oniṣegun ti wọn maa n ro pe ọkan naa ni wọn.

BBC Yoruba pade Ọba Aje Ọbatala agbaye, Ọba S.K. Akande niluu Porto Novo lorilẹede Olominira Benin ẹni to ṣalaye iyatọ to wa laarin babalawo ati oniṣegun.

Ọba Aje ni ‘’babalawo yatọ si oniṣegun, ati wi pe Ifa ni babalawo fi ṣe agba oniṣegun.

Ki babalawo to le ṣe nnkan kan, yoo da Ifa sori ẹ, nigba ti oniṣegun gbọdọ da owo ẹyọ lati le mọ ohun to fẹ ṣe lori nkan ti eeyan ba gbe wa sọdọ rẹ.’’

Ọba Aje ni babalawo lo ni etutu, amọ, oniṣegun lo ni ki a ja ewe ja egbo lati fi ṣe itọju eeyan.

Kinni atunbọtan awọn babalawo to n ṣe ogun ika?

Ọba Ajẹ ṣalaye pe ‘’awọn ti wọn jẹ eeyan buruku ninu awọn babalawo nio, oniṣegun nio, gbogbo wọn ni yoo kẹsan ohun ti wọn ṣe.

Ṣugbọn o dabi ẹni pe o ti n ye ọpọlọpọ eeyan bayii.

Ko sẹni to maa gbẹmi eeyan ti maa sọ pe oun fi gbe ẹlomiran dide ti ko ni pada sunkun rẹ lọjọ ọla.

Gbogbo awọn ti wọn ba n ṣiṣẹ ibi ki wọn ma gbagbe wi pe ẹsan n bọ lọjọ kan.

Ọba Aje sọrọ lori ọrọ aje Naijiria to n ṣojojo

Ọba Aje ni lootọọ ni ọrọ aje orilẹede Naijiria dori kodo, amọ, bibọ aje le jẹ ọna kan gboogi lati wa ojutuu si iṣoro to n koju Naijiria.

‘’Nnkan ti a jogun lọwọ awọn baba wa ti wọn n fi ọlaju ati ẹsin n gba danu mọ wa lọwọ n ṣe akoba pupọ.

Ọpọ eeyan ti wọn ba ni ko sin gbẹrẹ tabi fi nnkan fọ ẹkọ mu lo maa sọ pe awọn ko le ṣe e.

Eyi dẹ jẹ nnkan to n fiya jẹ ọpọlọpọ ọmọ Yoruba tori wọn o ka aṣa Yoruba kan mu.

Gbogbo awọn eeyan wa ti wọn fẹnu tẹnbẹlu awọn nkan tawọn baba fi silẹ ni iya n jẹ.