Ilé ẹjọ́ ní kí orí adé l'Osun lọ máa gba atẹ́gùn lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kuje

Aworan ile ẹjọ ati ade oba ni ilẹ Yoruba

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ile ẹjọ giga to n joko niluu Abuja, lọjọ Aje, palaṣẹ pe ki ori ade kan nipinlẹ Osun, Oba Tafeeq Osunmakinde lọ maa gba atẹgun lọgba ẹwọn Kuje fun ẹsun wiwa goolu ọna to lodi si ofin.

Adajọ Emeka Nwite lo gbe idajọ naa kalẹ lẹyin ti ori ade naa, ẹni to jẹ Obawore ti ife tuntun ni aarin gbogbo ijọba Ife nipinlẹ Osun, foju ba ile ẹjọ pẹlu eeyan mẹrin mii lori ẹsun wiwa goolu ọna aitọ.

Awọn afurasi yooku to wa pẹlu Ọba alade naa ni, Sheu Mustapha, Sabiru Hashim, Danbaba Ibrahim ati Ade Olap Global Resources Limited.

Agbẹjọro ijọba apapọ lo pe ẹjọ naa pẹlu nọmba idanimọ FHC/ABJ/CR/426/2024, to si fẹsun kan eeyan marun un lori bi wọn se n wa goolu ni ilana to lodi si ofin ni agbegbe Ogunlepo niluu Lege, nijọba ibilẹ Odigbo, nipinlẹ Ondo.

Ẹwẹ, awọn afurasi baa sọ fun ile ẹjọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn ka si wọn lẹsẹ.

Agbẹjọro awọn olujẹjọ, Vincent Ododo rawọ ẹbẹ si ile ẹjọ lati gba beeli awọn afurasi naa, ti agbẹjọro ijọba ko si tako sugbọn o ni ki ile ẹjọ ri daju pe awọn afurasi naa yọju si ile ẹjọ ni gbakugba ti w\ọn ba ranṣẹ si wọn.

Adajọ Nwite gba pe ki wọn gba beeli awọn olujẹjọ pẹlu N20 ati oniduro kọọkan.

Bakan naa ni adajọ tun gba iwe irinajo wọn silẹ pẹlu aworan wọn

Adajọ wa ni ki awọn afurasi wa ni ọgba ẹwọn Kuje titi wọn yoo fi ri san beeli wọn

O wa sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹsan an ọdun 2024.