'Ọdún yìí ni ọmọ mi fẹ́ ṣe ìgbéyàwó kí ikú tó pa á lójijì nínú ìjàmbá tánkà agbépo tó gbiná'

Aisha Usman, iya Adamu Usman to ku ninu ijamba ọkọ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ikú já ọmọ mi gbà lọ́wọ́ mi lásìkò tó ń múra ìgbéyàwó

Ìyá ọ̀kan lára àwọn èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàm̀bá iná ọkọ̀ agbépo tó gbiná ní ìpínlẹ̀ Niger lọ́jọ́ Àìkú fi ẹdùn ọkàn rẹ̀ hàn bó ṣe ń bá BBC News Pidgin sọ̀rọ̀.

Ìyá náà sọ̀rọ̀ nípa àwọn èròńgbà ọmọ rẹ̀ kí ikú tó ja gbà mọ́ ọn lọ́wọ́.

Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹsàn-án ni ìṣẹ̀lẹ̀ làlúrí náà sáwọn èèyàn ìjọba ìbílẹ̀ Lapai-Agaie, ìpínlẹ̀ Niger tí èèyàn 61 sì bá ìjàm̀bá náà lọ.

Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Nàìjíríà, NEMA ní èèyàn 61 ló kù tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn màálù náà sì tún ṣòfò.

NEMA ní ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn náà jóná kọjá mímọ̀, táwọn èèyàn mẹ́jọ sì wà nílé ìwòsàn níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.

Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Niger, NSEMA ni ọkọ̀ agbépo àti ọkọ̀ ńlá tó gbé èrò àti àwọn màálù ló kọlu ara wọn.

Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàm̀bá okọ̀ náà wáyé lójú wọn ní ọ̀nà tí kò dára níbi tí ìjàm̀bá náà ti wáyé dá kún ìjàm̀bá ọ̀hún.

Aisha Usman ní ọmọ òun, Adamu Usman tó jáde láyé náà ni ọmọ tó ń tọ́jú òun àti ẹbí òun láti ìgbà tí ọkọ òun ti jáde láyé.

“Inú ìjàm̀bá iná náà ni mo pàdánù ọmọ mi sí. Kò pẹ́ púpọ̀ tí bàbá rẹ̀ kú, mo sì tún ti pàdánù ọmọ mi báyìí,” Aisha sọ bó ṣe bú sẹ́kún.

Ìjàm̀bá iná náà tún ṣàkóbá fún àwọn ọlọ́jà tó ń bọ̀ láti agbègbè Babba ní ìjọba ìbílẹ̀ Katcha.

Àwọn tó bá ìjàm̀bá iná náà lọ ní wọ́n ti sin gẹ́gẹ́ bí àjọ NSEMA ṣe sọ.

Tanka epo to jona

Bákan náà ni àwọn ìyàwó ọkọ kan náà, Muhammadu Audu náà ń ṣe ìdárò ọkọ wọn tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú ìjàm̀bá náà.

Wọ́n ní ìyàlẹ́nu ló ń jẹ́ fún àwọn pé ọkọ àwọn, tó ń gbọ́ bùkátà àwọn, kò sí láyé mọ́.

“Àdánwò ńlá ni èyí jẹ́ ládọ̀tọ̀ Ọlọ́run. A ò ní èrò kan yàtọ̀ sí nǹkan tí Ọlọ́run bá ṣe. Ó fi àwọn ọmọ òrukàn sílẹ̀ fún wa,” ọ̀kan lára àwọn ìyàwó, Hadishetu Audu sọ.

Kí ìjọba bá wa tún ọ̀nà ṣe

Baálẹ̀ ìlú Babba, Muhammad Usman rọ ìjọba láti ṣe àtúnṣe ọ̀nà tí kò dára, tó ní ìgbàgbọ́ pé òhun ló fa ìjàm̀bá náà.

Ó ní ọmọ ìlú òun mẹ́ta, tí àwọn méjì kò ì tíì gbé ìyàwó nínú wọn, ló pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàm̀bá náà.

“Mi ò lè sọ irú ìrora tí àwọn èèyàn wà báyìí, ọ̀nà tí kò dára ló jẹ́ ka pàdánù àwọn èèyàn wà.”

Usman àtàwọn èèyàn míì ń ké sí ìjọba láti ṣe àtúnṣe ọ̀nà tí wọ́n ní ìjọba ti ń kọ́ láti ogún ọdún sẹ́yìn.

Ó ti di èèyàn 59 báyìí tó jóná níbi táńkà agbépo àti ọkọ̀ ńlá akẹ́rù tó gbiná

Aworan tanka to n jona ni Niger

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ni bayii, o ti di eeyan mọkandinlọgọta to jona ninu ijamba tanka agbepo ati ọkọ akẹru nla to gbina laarọ ọjọ Aiku nipinlẹ Niger.

Agbẹnusọ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ naa, Ọgbẹni Ibrahim Hussaini, sọ fun BBC wi pe o ṣee ṣe ki iye awọn to ku ninu ìṣẹlẹ naa tun pọ si.

"Enikan to tun ṣẹṣẹ ku ninu awọn to farapa yanayana lo jẹ k'awọn to ti ku ninu ijamba yii di mọkandinlọgọta.

O ṣee ṣe ki a si tun ri oku awọn eeyan mii sii bi iṣẹ idoola ẹmi ti n tẹsiwaju," Hussaini lo sọ bẹẹ.

Agbẹnusọ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri naa fikun ọrọ rẹ pe ọpọ awọn to ku ni wọn ti sin bayii.

Ọgbẹni Hussaini sọ pe "ijamba ọkọ to buru julọ ni ọpọlọpọ ọdun ni eleyii jẹ."

O fikun ọrọ rẹ pe ijọba ipinlẹ Niger lo n sanwo ile iwosan fun itọju gbogbo awọn to farapa nibi ijamba naa.

Táńkà agbépo àti ọkọ̀ ńlá akẹ́rù gbiná, èèyàn 48 jóná, ọ̀pọ̀ màálù kú

Ko din ni eeyan mejidinlaadọta to jona ninu iṣẹlẹ ọkọ tanka agbepo to gbina nipinlẹ Niger laarin gbungbun orilẹede Naijiria lana ọjọ Aiku, ọjọ kẹjọ oṣu Kẹsan an ọdun 2024 yii.

Iṣẹlẹ yii ni a gbọ pe o ṣẹlẹ lẹyin ti tirela agbepo kọlu ọkọ nla akẹru kan to ko ẹran maalu ati atawọn ero.

Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Niger ṣalaye pe awọn ọkọ mejeeji naa kọlu ara wọn ni nnkan bi ago mejila abọ oru ọjọ Aiku.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ajọ naa sọ pe lẹyin ti wọn kọlu ara wọn tan ni awọn ọkọ naa gbina.

Ọga agba ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Niger, Abdullahi Baba-arah, sọ pe ajọ naa ko awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi lọ sibi iṣẹlẹ ọhun lẹyin to ṣẹlẹ tan.

Ọgbẹni Baba-arah sọ pe ijamba ọkọ yii tun ṣakoba fawọn ọkọ mii naa yatọ si tanka agbepo ati ọkọ nla to ko maalu ti wọn jọ kọlu ara wọn.

Fọto lati ibi ti ijamba naa ti waye ṣafihan bi ọkọ meji ṣe jona raurau ti ọpọ maalu si ku.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi to ba ileeṣẹ iroyin Reuters sọrọ ṣalaye pe bawọn ṣe n gbiyanju lati yọ awọn eeyan nibi ijamba ọkọ naa lawọn n gbiyanju lati yọ awọn ẹran maalu to ti ku ti wọn si ti ha sinu ọkọ naa.

Ileeṣẹ iroyin ipinlẹ Niger ti fidi rẹ mulẹ pe oju kan naa ni wọn maa sin gbogbo eeyan to ba iṣẹlẹ ọhun si.

Gomina Umaru Bago ipinlẹ Niger ti ranṣẹ ibanikẹdun sawọn ẹbi awọn eeyan to ku ninu iṣẹlẹ naa.

Gomina ni nnkan to bani lọkan jẹ gidi gan an ni iṣẹlẹ ọhun.

Ijamba tanka agbepo wọpọ ni Naijiria eyi ti ọpọ gbagbọ wi pe o n ṣẹlẹ tori aisi ọna to dara to.