Kò sí àrídájú pé owó epo bẹntiróòlù yóò wálẹ̀ ta bá bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé epo láti ọ̀dọ̀ Dangote - NNPCL

Oríṣun àwòrán, Others
Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ epo bẹntiróòlù ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìyẹn Nigeria National Petroleum Company Limited (NNPCL) ti ní kò sí àrídájú pé àdínkù yóò bá owó epo bẹntiróòlù tí àwọn bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé epo láti ilé ìfọpo Dangote.
Ní ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹsàn-án ni NNPCL ní àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní gba epo láti ilé iṣẹ́ Dangote náà.
Agbẹnusọ NNPCL, Olufemi Soneye nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ní ọjà àgbáyé ló máa ń ṣe atọ́nà iye tí àwọn iléeṣẹ́ tó ń fọ epo máa ta ọjà wọn tó fi mọ́ iléeṣẹ́ ti Dangote náà.
Ó ní kò sí àrídájú pé àdínkù máa bá owó epo bẹntiróòlù nígbà tí àwọn bá bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé epo láti ọ̀dọ̀ Dangote.
Ọ̀rọ̀ Soneye yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn kan ti ń sọ lórí ayélujára pé ó ṣeéṣe kí owó epo ti wálẹ̀ NNPCL bá ti ń gbé epo lọ́dọ̀ Dangote.
Bákan náà ni àwọn kan ní NNPCL ń gbèrò láti jẹ gàba lórí epo tó bá ń jáde láti iléeṣẹ́ náà.
Àtẹ̀jáde náà kọminú lórí àtẹ̀jáde kan tí àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn Mùsùlùmí, Muslim Rights Concern (MURIC) fi síta pé NNPCL ń gbèrò láti bá iṣẹ́ ilé ìfọpo ó jẹ́.
Wọ́n ní MURIC sọ pé àlékún owó epo bẹntiróòlù tí Dangote ṣe láìpẹ́ yìí jẹ́ ojúnà láti dènà Dangote láti ta epo rẹ ni owó péréte.














