Kí ló fàá tí àwọn aráàlú fi ń ṣe ìwọ́de tako Olóòtú ìjọba tuntun?

Aworan awọn oluwọde ni France

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọpọ eeyan lo ti tu sita kaakiri orilẹede France lati se iwọde tako bi wọn se fa oludije ọwọ ọtun Michel Barnier silẹ gẹgẹ bii Olootu ijọba, lẹyin ti eto idibo waye, to si jẹ pe apa alaafia lo bori ọpọ awọn ijoko ni ile igbimọ aṣofin.

Iwọde naa ti waye ni awọn ilu bi Paris, Marseille, Nantesm Nice ati Starsbourg.

Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ati awọn ẹgbẹ oṣelu apa alaafia, ti wọn n binu pe oludije ti wọn fa kalẹ fun olootu ijọba ni Aarẹ Emmanuel Macron kọ lati tẹwọgba.

Barnier, oṣiṣẹ EU tẹlẹ, sọ pe oun setan lati da ijọba tuntun silẹ pẹlu awọn oloṣelu kaakiri orilẹede France, ti ko si ni yọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako silẹ.

O le ni iwọde 130 to waye, ti eyi to lagbara ju si waye ni aarin gbogbo olu ilu Paris ni ọjọ Ṣatide.

Jean-Luc Mélenchon darapọ mọ iwọde naa niluu Paris , to sọrọ sit pe “Fun ijọba awarawa, ẹ fopin si iditẹgbajọba Macron.”

Ariwo titẹ oju ẹtọ ijọba awarawa mọlẹ ni ọpọ awọn oluwọde naa n pariwo ati jiji ibo.

Awọn ẹgbẹ oṣelu apa alaafia ni inu bi nitori oludije wọn, Lucie Castets ti Aarẹ Macron wọgile, ẹni to ni pe ko ri atilẹyin ile igbimọ aṣofin gba.

Barnier, ẹni to lo ọjọ Ṣatide rẹ pẹlu awọn ọmọ orukan ni awọn ile iwosan niluu Paris sọ fun awọn eleto ilera pe ijọba rẹ ko ni ṣe iṣẹ iyanu.

Pẹlu gbogbo iwọde naa to n waye, olootu ijọba tuntun gbajumọ bi yoo se da ijọba tuntun silẹ.