Ṣé lóòótọ́ ni Iléeṣẹ́ ìfọpo rọ̀bì abẹ́lé yóò mú adikun bá iye owó epo?

Aworan ileeṣẹ ifọpo

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lo n tiraka lati tẹwọgba afikun owo jala epo ti ajọ to n risi epo rọbi NNPCL kede lọjọ Isẹgun lati N617 lọ N897 naira.

Ikede yii lo waye ni ọjọ kaana ti ileeṣẹ ifọpo Dangote kede pe awọn ti bẹrẹ si ni ma gbe epo rọbi sita bẹrẹ lati inu oṣu kẹsan an.

Ileeṣẹ ifọpo Dangote lo jẹ aladani, eyi to jẹ ti Aliko Dangote, ọkunrin keji to lowo ju ni Afrika. Ileeṣẹ naa bẹrẹ iṣẹ ni oṣu akọkọ ọdun 2024 sugbọn ninu oṣu kẹsan an yii ni wọn gbe epo wọn sita, ti wọn si kede pe awọn ti setan lati gbe epo naa silẹ fun tita.

Bi ọrọ nipa afikun epo rọbi se n lọ lọwọ, awọn araalu kan to ba BBC sọrọ pe awọn ni igbagbọ pe ileeṣẹ ifọpo Dangote yoo mu adikun ba iye owo epo rọbi.

“Eyi lo fa ti awọn nla kan ni ẹka epo rọbi se n tako ileeṣẹ ifọpo Dangote nitori wọn mọ pe to ba ti bẹrẹ si ni ma pese epo, okowo wọn yoo ja wa lẹ.” Agaba Enenche, araalu ti BBC ba pade ni ile epo NNPC niluu Abuja ṣalaye.

Ki ni NNPCL ati Dangote ko fẹnu ko si?

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ NNPCL, Olufemi Soneye fi lede ni ọjọ Ṣatide, NNPC ni ko si aridaju pe adikun yoo ba owo epo rọbi pẹlu bi wọn se ti gbaradi lati ma gbe lati ileeṣẹ ifọpo Dangote.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe NNPCL yoo bẹrẹ si ni ma gbe epo rọbi ni ileeṣẹ naa bẹrẹ lati ọjọ Kẹdogun oṣu kẹsan an.

Soneye ni iye ti owo epo lati eyikeyi ileeṣẹ ifọpo pẹlu ileeṣẹ Dangote ni yoo da lori agbara ọja agbaye

O ni ko si aridaju kankan pe owo epo rọbi yoo walẹ rara ti NNPCL ba bẹrẹ si ni ra epo rọbi ni ẹsẹ kuku, ti wọn sẹda lorilẹede Naijiria.

“Eyikeyi ileeṣẹ ifọpo ti a ba ti gbe epo, ko ba jẹ ileeṣẹ ifọpo Dangote ni iye owo rẹ da lori agbara ọja agbaye.”

Bakan naa ni Soneye ni iroyin ẹlẹjẹ ni to ni NNPCL n gbiyanju lati sọ ileeṣẹ ifọpo Dangote di ileeṣẹ kan ti yoo pase epo ti wọn yoo si tọju bọ bi wọn se pese epo naa.

O sọ eyi lati pese idahun si ẹsun ti ẹgbẹ Musulumi lorilẹede Naijiria, MURIC fi kan NNPCL pe n fi oju tẹnbẹ lo ileeṣẹ ifọpo Danjote.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ki ni awọn nnkan ti yoo sọ iye ti owo epo yoo jẹ ?

Nitori Naijiria n gbe epo wọle lati oke okun, awọn wọnyi ni yoo sọ iye ti epo yoo jẹ.

  • Iye ti wọn n ta epo rọbi lagbaye.
  • Pasipaarọ owo laarin orilẹede
  • Iye ti wọn fi pelo rẹ
  • Iye owo ti wọn fi gbe wọle si orilẹede
  • Owo igbeọja wọle
  • Iye owo ti wọn yoo fi gbe de ipinlẹ kọọkan

Ni gbogbo awọn nnkan wọnyi, eyi ti ko ni nnkan pẹlu ileeṣẹ ifọpo Dangote ni iye ti wọn fi gbe wọle ati owo igbeọja wọle nitori wọn pese epo naa lorilẹede Naijiria sugbọn awọn owo yooku ni o jẹ ti gbogbo agbaye. Seun Oworu ṣalaye.

“Bi o ṣe wa bayii, iye ti epo ba de ni N1,100 fun jale epo kan. Bi wọn se n ta epo ni N800 si N900 fihan pe ijọba ti pese ohun iranlọwọ diẹ pẹlu bi ida aadọta.

Ẹwẹ, Oworu ni ijọba orilẹede ti gba lati ma ta ohun elo fun epo rọbi fun ileeṣẹ Dangote ni owo naira, wọn tun le se adehun pẹlu rẹ lati ta epo rọbi fun wọn ni naira, eyi ti yoo yọ wahala pasipaarọ owo pẹlu ti oke okun, ati pe boya epo Dangote le walẹ ju ti awọn yooku lọ.

Epo yoo wa, o kan le wọn si

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Dokita Okey Okere , onimọ nipa okowo sọ fun BBC pe bi NNPCL se jẹ onibara ti Ileeṣẹ ifọpo Dangote ni lo jẹ ipenija nla nitori awọn ni yoo ma ta fun awọn yooku.

“Eyi ni mu ki NNPCL jẹ ileeṣẹ epo nikan, bo ti lẹ jẹ wọn ni ijọba ti yọ wọ kuro ni ileeṣẹ naa, a mọ pe ijọba si niọwọ nibẹ, ti yoo si tun bọ ma siṣẹ gẹgẹ bii ẹka ileeṣẹ ijọba.

“Ti ẹ ba lọ gbọkan le pe ọkọ nla ni yoo ma lọ lati Kano lọ Eko, lati Kaura lọ Namoda ati kaakiri orilẹede Naijiria lati ra epo lati ileeṣẹ ifọpo Dangote , ti yoo si tun gbe pada pẹlu ọna wa ti ko da, pẹlu bi awọn ọlọpaa se n gbe riba loju opopona, awọn ajinigbe ati awọn buburu mii to n waye loju opopona. N ko mọ bi bi iye owo epo se fẹ walẹ ni Naijiria.

“Fun eyi mo n reti pe a o ri iyipada paapa nipa kudiẹkudiẹ owo naira nitori a ko ni ma sare kiri pe a fẹ gbe epo wọle. Sugbọn n kọ mọ pe boya se nnkan pẹlu ọwọngogo. Ọwọngogo yoo si wa fun igba diẹ nitori n ko le gbe ara le NNPC lati mojuto riri pe epo wa kaakiri lati ja owo epo walẹ