Ṣó o Láyà: Ibrahim Chatta náà kópa nínú ìdánwò tó dá lórí àṣà àti èdè Yorùbá
Ṣó o Láyà: Ibrahim Chatta náà kópa nínú ìdánwò tó dá lórí àṣà àti èdè Yorùbá
Agba lo toro lọ, ọba lo to eyin eerin fọn ni tootọọ.
Ohun lo difa fun agba oṣere tiata Yoruba, Ibrahim Chatta, to gbarada lori eto Ṣo o laya lori ikanni BBC Yoruba.
Odu ni Chatta ninu ka fi ede Yoruba dara tabi ka fi ede Yoruba powe.
Koda, ti a ba n sọ nipa awọn to le sọ Yoruba ti wọn si le fa komookun rẹ yọ, ọkan gboogi ni Chatta jẹ.
A beere awọn ibeere to ni ṣe pẹlu ede Yoruba lọwọ rẹ, gẹgẹbi ẹni to n gbe aṣa ati ede Yoruba ga ninu awọn sinima rẹ.
Ka ma parọ, Ibrahim Chatta gbiyanju pupọ. Ẹyin gan ẹ funra maa ri ninu fọnran yii.
Nibẹ lo ti dahun awọn ibeere lọkan o jọkan eyi to nii ṣe pẹlu ede Yoruba, aṣa ati iṣe wa.
O fẹẹ jẹ wi pe gbogbo ibeere ti a beere lọwọ oṣere yii ni o dahun tan.






