Ohun tó fa awuyewuye nípa ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tí Osimhen fẹ́ darapọ́ mọ́ rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Ian Williams
- Role, BBC Sport Africa
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Awin ti Victor Osimhen gba lọ si Galatasaray lo ṣee ṣe ko fopin si akoko rẹ pẹlu Napoli.
Ni oṣu mejila sẹyin, agbabọọlu Naijiria jẹ ọkan ninu awọn agbabọọlu to n sana ni agbaye, lẹyin to lewaju Gli Azzurri si ife ẹyẹ akọle Serie A lati ọdun 33.
Ọpọ ero lo tu sita lati ki kaabọ sinu ẹgbẹ agbabọọlu Galatasaray
Osimhen, 25, ni ibi ti oun wa bayii dara ju ibi ti oun ti bọ lọ nitori awọn nnkan to ti la kọja lni bi oṣu diẹ sẹyin.
Sugbọn bawo ni ọrọ yii ṣe de ibi to wa yii?
Spalletti, Scudetto ati agbabọọlu Afrika
Osimhen darapọ mọ Napoli lati Lille ni Oṣu Keje ọdun 2020 pẹlu adehun toto £ 73m ($ 96m), eyi to jẹ ki o jẹ agbabọọlu Afirika to gbowolori julọ ni gbogbo igba.
O gba awọn mẹwaa wọle ni saa akokoọ ṣaaju iyipada akọnimọgba Gennaro Gattuso ti Luciano Spalletti si rọpo rẹ.
Labẹ Spalletti, Osimhen gba awọn mejidinlogun wọlw ni saa keji rẹ ko to gba bọọlu wọ awọn ni igba mọkanlelọgbọn ni gbogbo idije ti Napoli kopa, ti wọn si tun gba ife ligi ni saa ọdun 2022-23, eyi to jẹ akọkọ iru rẹ lati ọdun 1990.
Osimhen pari saa naa gẹgẹ bi agbabọọlu to mi awọn julọ ni Serie A , ti dibo fun un gẹgẹ bi agbabọọlu to dara ju nilẹ Afrika ni Oṣu Keji ọdun 2023 – saaju ọjọ diẹ ko tọwọ bọ iwe adehun tuntun, pẹlu owo to ju £10m ($ 13m) lọ ni ọdun kan, Napoli gbe igbesẹ lati daabobo dukia wọn.
“Napoli ko mojuto ọrọ yii ni saa to kọja nigba ti wọn fun Osimhen ni adehun mi,” Oniroyin ere idaraya Ilu Italia Daniele Verri sọ.
Verri gbagbọ pe o yẹ ki Osimhen ti “fi ẹgbẹ naa silẹ lẹsẹkẹsẹ” lẹyin adehun tuntun, eyi ti o wa pẹlu owo itusilẹ £ 113m ($ 148m).
“O ti kọja ọdun kan bayi ti wọn ba gbogbo nnkan yii jẹ.”
Spalletti jade, Conte wọle

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkan ninu awọn idi ti Spalletti fi pinnu lati lọ kuro lẹyin to gba Scudetto.
Laisi Spalletti, Napoli ko le tun ṣe aṣeyọri naa, ti wọn si pari si ipo kẹwaa.
Osimhen, gbiyanju lati mi awọn mẹtadinlogun fun ẹgbẹ agbabọọlu naa sugbọn ko kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ nitori o farapa , to si tun kopa ninu idije ife ẹyẹ adulawọ pẹlu orilẹede Naijiria.
Bi o ṣe kopa yii ni ko dun mọ onimọ nipa bọọlu afẹsẹgba ni Ilu Italia James Horncastle, ẹni to gbagbọ pe Osimhen ko to owo ti wọn gbe le lori.
"Mo ro pe eyi ni ohun nla ni saa to kọja - ṣe o le ṣe iru kan to se tẹlẹ ni saa ti wọn gba ligi? Ko ṣe bẹ, ti mo ro pe eyi jẹ iṣoro gidi nigba ti awọn ẹgbẹ agbabọọlu n wa agbabọọlu yii ni ọdun yii, "o sọ fun Euro League.
Leyin ti wọn se ayipada olukọni lẹyin ti wọn ligi, Napoli yan Antonio Conte ni Oṣu Karun, ti olukọni Juventus, Inter Milan ati Chelsea tẹlẹ ko si fi akoko sofo lati gbe awọn igbesẹ kan
O gbe igbesẹ lati mu agbabọọlu Romelu Lukaku wa lati Chelsea, ti wọn si yọ Osimhen kuro ninu ẹgbẹ agbabọọlu naa, ti wọn si fun eeyan miiran ni nọmba ẹyin rẹ.
Agbabọọlu orilẹede Naijiria tẹlẹri Peter Odemwingie jẹ ọkunrin kan ti o mọ nipa ki agbabọọlu fẹ kuro ni kilọbu rẹ
Bẹẹ ba gbagbe o fẹ kuro ni ẹgbẹ agbabọọlu West Bromwich Albions lọ si Queen Park Rangers
“Bọọlu afẹsẹgba loni ni iṣowo rẹ pọ ipa ere bọọlu gan” o sọ fun BBC Sport Africa, o fikun pe o ṣee ṣe ki Osimhen banujẹ pupọ.
Pẹlu Conte ati Alakoso Napoli Aurelio de Laurentiis ti Verri ṣe apejuwe bi “eniyan alagidi”, ti gbogbo awọn ẹgbẹ si n wa ojutu bayii.
Ki lo sẹlẹ pẹlu lilọ si Chelsea?
Pẹlu bii ọpọlọpọ ẹgbẹ agbabọọlu ti ṣe ifẹ han si Osimhen, kii ṣe ọpọlọpọ wọn ni wọn dẹnu ọrọ kọ Osimhen. Paris St Germain ṣe, ṣugbọn ko le fẹnu ko lori owo pẹlu Napoli.
Pẹlu bi agbabọọlu orilẹ-ede Naijiria se pinnu lati ma gba owo-oṣu to keke, ti De Laurentiis si ni oun gẹ gba gbogbo lati ra .
Chelsea, naa fi ifẹ han si Osimhen pẹlu erongba pe yoo ja owo oṣu rẹ walẹ ki okowo karakata agbabọọlu to pari.
Pẹlu gbogbo igbiyanju Chelsea, wọn ri Osimhen mu wa si Stamford Bridge
Ala Osimhen ni lati gba bọọlu ni ligi Premier League ni ọjọ kan, ṣugbọn ni bayi awọn aṣayan rẹ ti n dinku.
Saudi Arabia nko?
Irin-ajo miiran ti o ṣeeṣe ki Osimhen ri ni lilọ si ligi Saudi Pro League lati darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Al-Ahli.
Pẹlu bi Napoli se setan lati tẹ diẹ, wọn fẹnu ko pẹlu Al-Ahli pẹlu adehun owo £ 60m ($ 78.6m) – sugbọn o ya ni lẹnu nigba ti De Laurentiis tun gbe owo le owo lati ra Osimhen.
O tumọ si pe lakoko ti ẹgbẹ Osimhen ni idunnu pẹlu owo osu, Al-Ahli ni lati lọ fun agbabọọlu mi ti o din owo £ 40m ($ 52.4m) lati Brentford's Ivan Toney.
Bii bi ọrọ nipa lilọ Saudi Osimhen ko han tara, aṣoju rẹ ni sọrọ ke lilọ Saudi ko ki n se erongba agbabọọlu naa.
“O (Osimhen) kii ṣe apo kan lati gbe lọ si ọna jijin lati wa aye fun awọn woli tuntun. Victor ni a yan gẹgẹ agbabọọlu to da ju ni ilẹ Afirika, ipo kẹjọ ni Ballon d’Or, o tun ni ohun ọpọlọpọ lati ṣe ni Europe.”















