Omíyalé ń bọ̀ ní ìpínlẹ̀ méje láìpẹ́ – Ìjọba àpapọ̀ kìlọ̀

Oríṣun àwòrán, getty images
Ijọba apapọ ti sọ pe o ṣeeṣe ki ojo rọ fun ọjọ marun un gbako, eyii ti yoo fa iṣẹlẹ omiyale ni ipinlẹ mokanlelogun.
Ijọba tun mẹnuba awọn ipinlẹ meje mii ti ọrọ naa ṣeeṣe ko kan.
Awọn ipinlẹ meje naa ni Benue, Kogi, Anambra, Delta, Imo, Rivers ati Bayelsa.
Ẹka to n ri si ọrọ omiyale ni ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si ọrọ ayika lo fi ọrọ naa lede.
O kilọ fun awọn ilu kekeke to wa lagbegbe adagun odo Benue ki wọn ṣọra gidi.
Gẹgẹ bii ohun ti ajọ naa sọ, ojo ọhun yoo fa omiyale lati ọjọ kẹrin si ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹsan an, ọdun 2024.
Awọn ipinlẹ ti ọro naa kan
Awọn ipinlẹ ti ọrọ ọhun yoo kan ree;
- Adamawa (Mubi, Shelleng, Demsa, Numan, Song, Wuro Bokki, Natubi, Mayo Belwa, Jimeta, Gbajili, Ganye, Farkumo, Abba Kumbo)
- Benue (Udoma, Ugbokpo, Ugbokolo, Ukpiam, Otobi, Otukpo, Mbapa, Makurdi, Gbajimba, Gogo, Abinsi)
- Bauchi (Azare, Jama’are, Itas, Misau, Tafawa-Balewa)
- Kogi (Ugwalawo, Idah, Ibaji, Wara, Omala, Bassa, Ajaokuta)
- Borno (Biu, Maiduguri, Briyel)
- Nasarawa (Ado, Mararaba, Udeni, Rukubi, Ajima, Odogbo)
- Gombe (Nafada, Gombe, Bajoga)
- Kwara (Kosubosu, Kaiama)
- Jigawa (Dutse, Gumel, Ringim)
- Oyo State (Kishi)
- Kaduna (Kachia, Zaria, Kauru, Jaji)
- Edo (Udochi, Agenebode)
- Kano Sumaila, Kunchi, Karaye, Gwarzo, Bebeji, Tudun wada)
- Katsina (Bakori, Bindawa, Funtua, Jibia , Kaita, Katsina, Daura)
- Kebbi (Ribah, Argungu, Gwandu, Yelwa, Saminaka, Jega, Bunza)
- Plateau (Mangu)
- Niger (Ibi, New Bussa, Mashegu, Kontagora, Lavun, Rijau, Magama, Lapai, Katcha, Bida)
- Sokoto (Isa, Makira, Gagawa, Shagari, Silame, Goronyo)
- Taraba (Ngaruwa, Serti, Yorro, Natubi, Mutum biyu, Kwata kanawa, Lau, Kambari, Jalingo, Gun-gun Bodel, Gassol, Garkowa, Bandawa, Beli, Bolleri, Mayo Renewo, Duchi)
- Yobe (Geidam, Potiskum, Dapchi, Damaturu)
- Zamfara (Bukkuyum, Gummi, Kaura Namoda, Shinkafi, Maradun)
Ẹwẹ, ajọ to n ri si isẹlẹ pajawiri, NEMA, ti ke si awọn ipinlẹ ni aringbungbun ati guusu Naijiria lati maa mura de iṣẹlẹ omiyale to ṣeeṣe ko waye laipẹ.
Ajọ naa tun kilọ fun gbogo awọn to n da idọti si oju gọta to n di ọna omi lati dẹkun ṣiṣẹ bẹẹ.
NEMA lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Manzo Ezekiel, fi lede.
O tun kilọ fun awọn araalu lati ṣọra fun gbigba oju ọna ti agbara wa.
Lẹyin naa lo rọ awọn to n gbe lagbagbe ti wọn darukọ lati sọra, ki wọn si ṣe awọn ohun to yẹ ki wọn ma baa faragba ninu iṣẹ omiyale naa to n bọ.















