Ìyapa ẹnu lórí alága ẹgbẹ́ òṣèlú Labour láàrin Nenadi Usman àti Julius Abure

Nenadi Usman àti Julius Abure

Oríṣun àwòrán, NENADI USMAN/X/LABOUR PARTY NIGERIA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ní Nàìjíríà ti yan àwọn adelé tuntun.

Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fétó ìsúná Nàìjíríà, Nenadi Usman sì ni wọ́n yàn gẹ́gẹ́ bí alága ẹgbẹ́ níbi ìpàdé pàjáwìrì àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ òṣèlú náà tó wáyé ní ìlú Umuahia, ìpínlẹ̀ Abia tó wáyé lọ́jọ́ Kérin, oṣù Kẹsàn-án ọdún 2024.

Níbẹ̀ ni wọ́n ti kéde arábìnrin Usman àtàwọn méjìdínlọ́gbọ̀n mìíràn gẹ́gẹ́ bí alákòso tí yóò máa ṣe àmójútó ètò ẹgbẹ́ Labour Party.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn lóókọ lóókì ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ló kópa níbi ìpàdé náà tí gómínà ìpínlẹ̀ Abia, Alex Otti pè ọ̀hún.

Bẹ̀rẹ̀ láti orí Peter Obi, tó jẹ́ olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party níbi ètò ìdìbò tó kọjá, igbákejì rẹ̀, Yusuf Datti-Baba Ahmed, àwọn aṣòfin lẹ́ka ìjọba àpapọ̀ àti ìpínlẹ̀ ló péjú síbi ìpàdé náà.

Bákan náà ni àwọn olùdíje sípò gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú náà bíi Gbadebo Rhodes-Vivour ti ìpínlẹ̀ Eko, Chijoke Edeoga ti ìpínlẹ̀ Enugu, Athan Achonu ti ìpínlẹ̀ Imo, àwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nigeria Labour Congress, NLC àti Trade Union Congress, TUC, kò gbẹ́yìn níbi ìpàdé náà.

Àmọ́ agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, Obiora Ifoh nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta ní ìpàdé tí wọ́n ti yan àwọn adarí tuntun náà kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá.

Ìyapa ẹnu láàárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́

Àwòrán àwọn ọmọ ẹgbẹ́ lásìkò ìpàdé àpérò náà

Oríṣun àwòrán, LABOUR PARTY

Ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ní Nàìjíríà ti yan àwọn adarí tuntun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fétó ìsúná Nàìjíríà, Nenadi Usman sì ni wọ́n yàn gẹ́gẹ́ bí alága ẹgbẹ́ níbi ìpàdé pàjáwìrì àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ òṣèlú náà tó wáyé ní ìlú Umuahia, ìpínlẹ̀ Abia tó wáyé lọ́jọ́ Kérin, oṣù Kẹsàn-án ọdún 2024.

Níbẹ̀ ni wọ́n ti kéde arábìnrin Usman àtàwọn méjìdínlọ́gbọ̀n mìíràn gẹ́gẹ́ bí alákòso tí yóò máa ṣe àmójútó ètò ẹgbẹ́ Labour Party.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn lóókọ lóókì ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ló kópa níbi ìpàdé náà tí gómínà ìpínlẹ̀ Abia, Alex Otti pè ọ̀hún.

Bẹ̀rẹ̀ láti orí Peter Obi, tó jẹ́ olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party níbi ètò ìdìbò tó kọjá, igbákejì rẹ̀, Yusuf Datti-Baba Ahmed, àwọn aṣòfin lẹ́ka ìjọba àpapọ̀ àti ìpínlẹ̀ tó péjú síbi ìpàdé náà.

Bákan náà ni àwọn olùdíje sípò gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú náà bíi Gbadebo Rhodes-Vivour ti ìpínlẹ̀ Eko, Chijoke Edeoga ti ìpínlẹ̀ Enugu, Athan Achonu ti ìpínlẹ̀ Imo, àwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nigeria Labour Congress, NLC àti Trade Union Congress, TUC, kò gbẹ́yìn níbi ìpàdé náà.

Àmọ́ agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, Obiora Ifoh nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta ní ìpàdé tí wọ́n ti yan àwọn adarí tuntun náà kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá.

Kí ni òfin Labour Party sọ?

Peter Obi, Yusuf Datti-Baba Ahmed àti gómìnà ìpínlẹ̀ Abia, Alex Otti

Oríṣun àwòrán, ABIA STATE GOVERNMENT

Ìwé òfin ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ro ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ náà lágbára láti ṣàkóso gbogbo ètò tó bá jọ mọ́ ẹgbẹ́ náà.

Yàtọ̀ sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tí ẹgbẹ́ bá dìbò yàn, gbogbo àwọn gómìnà àti igbákejì rẹ̀ tí wọ́n bá wọlé ìbò lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ náà ni wọ́n ní àǹfàní láti jẹ́ ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́.

Àwọn agbára míì tí ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ ní ni:

  • Ní láti yanjú àáwọ̀ tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó bá kéré mú wá
  • Láti ṣàgbékalẹ̀ òfin fún ẹgbẹ́
  • Láti fẹnukò lórí ìpàdé àti àpérò

Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ni ìgbìmọ̀ tó tóbi jùlọ lẹ́yìn ìpàdé àpérò láti ṣàgbékalẹ̀ òfin fún ẹgbẹ́.

Níbi ìpàdé àpérò tó wáyé ní Umuahia ni wọ́n ti fún àwọn aláṣẹ tuntun náà ni gbèdéke àádọ́rùn-ún ọjọ́ láti fi ṣe ìpàdé àpérò ní gbogbo wọ́ọ̀dù, ìjọba ìbílẹ̀ àti ìpínlẹ̀ káàkiri Nàìjíríà ní ìgbáradì fún ìpàdé àpérò àpapọ̀ níbi tí wọ́n ti máa yan àwọn adarí tuntun.

Ohun tí Pat Utomi kọ sí ojú òpó rẹ̀

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT/X

Kí ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Labour Party míì ń sọ?

Lórí ayélujára, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Labour Party míì ti ń kan sáárá sí ẹgbẹ́ fún yíyan àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ náà.

Pat Utomi, ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ Labour tó jẹ́ kí Peter Obi darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà lọ́dún 2022 ní ìgbésẹ̀ ẹgbẹ́ láti yan àwọn adarí tuntun náà jẹ́ ọ̀nà láti mú ìgbà ọ̀tun bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Kennneth Okonkwo, tó jẹ́ agbẹnusọ tẹ́lẹ̀ fún ìpolongo ìbò Peter Obi kan sáárá sí Alex Otti fún bí ó ṣe pè fún àpérò náà.

Ó ní sẹ́nétọ̀ Nenadi Usman jẹ́ ọlọ́pọlọ pípẹ tí yóò yọ ẹgbẹ́ Labour Party kúrò nínú làásìgbò tó ń bá ẹgbẹ́ náà fínra.