Eré ìdárayá ló sọ wá di èèyàn láyé – Tọkọtaya àkàndá
- Author, Isaiah Akinremi
- Role, BBC Sport Africa
- Reporting from, Lagos
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Tọkọtaya ti wọn n ṣe ere idaraya ti sọ pe ere idaraya naa lo jẹ ki awọn jẹ eeyan.
Folashade Oluwafemiayo ati Tolulope Taiwo jẹ tọkọtaya to n ṣe ere idaraya, ti iyawo, iyẹn Folashade si ti gbe ogo orilẹede Naijiria ninu idije ere idaraya awọn akanda Paris 2024, lorilẹede France.
Folashade lo gba ipo kiiini ninu gbigbe irin kílógíráàmù mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún, eyii to mu ko gba ife ẹyẹ fun Naijiria ninu idije naa.
Gẹgẹ bii ohun ti tọkọtaya naa sọ, aisan polio lo sọ awọn mejeji di akanda lati kekere amọ ipenija naa ko da wọn duro lati jẹ eeyan loke eepẹ.
Bi tọkọtaya naa ṣe pade
Nigba to n ba BBC sọrọ, ọkọ Folashade sọ pe “elere idara akanda lemi naa.
“Igba ti mo pade iyawo mi, a lọ ṣe idanwo ere idaraya kan niluu Ibadan lọdun 2004.
“Nigba ti mo fẹ fẹ, ti mo pe iya mi, mo sọ fun wọn pe eeyan bii temi ni mo fẹ fẹ o... pe akanda bii temi naa ni.
“Mama mi sọ pe rara. O ni ta lo maa ran wa lọwọ ti a ba fẹra, mo ni Ọlọrun lo maa ran wa lọwọ, ṣugbọn titi di oni mi o kabamọ.
Iṣẹ nọọsi lo wu mi lati ibẹrẹ
Nigba ti Folashade n sọrọ, o ni iṣẹ nọọsi lo wu oun lati ibẹrẹ oun wa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, idẹyẹsi awọn eeyan ni ko jẹ ki oun pada ṣe iṣẹ nọọsi naa.
O ni oun lọ gba fọọmu ile ẹkọ awọn nọọsi amọ wọn sọ fun oun nibẹ pe oun ko nile ṣe iṣe naa latari ipoti oun wa.
Amọ ni bayii o ti sọ pe oun yoo pada lọ gba fọọmu naa nitori o wu oun lati ṣiṣẹ ọhun.
‘Kò sí nǹkan tí abarapá ń ṣe tí mi ò lè ṣe’

Folashade Oluwafemiayo jẹ́ ènìyàn kan tí eegun rẹ̀ le, tó sì máa ń fẹ́ láti ṣe àwọn nǹkan tó lágbára.
Obìnrin, ẹni ọdún mọ́kànlélógójì náà, wà lára àwọn tó gbégbá orókè jùlọ níbi ìdíje eré ìdárayá àwọn àkàndá méjì tó wáyé sẹ́yìn.
Ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, níbi ìdíje paralympics fáwọn àkàndá tó wáyé ní Tokyo, àwọn obìnrin ló gba mẹ́dàlì mẹ́fẹ́ẹ̀fà tí Nàìjíríà gbà nínú eré ìdárayá irin gbígbé níbi ìdíje náà.
Oluwafemiayo gba ipò kìíní nínú gbígbe irin kílógíráàmù mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún láti gba mẹ́dàlì náà fún Nàìjíríà.
Folashade Oluwafemiayo sọ fún BBC Sport Africa pé iṣẹ́ nọ́ọ̀sì ló wu òun láti ṣe àmọ́ ọ̀rẹ́ ẹbí àwọn kan tó jẹ́ àgbà nọ́ọ̀sì kọ̀ láti ran òun lọ́wọ́ látàrí bí òun ṣe jẹ́ àkàndá.
Ó ní kódà ẹni náà kọ̀ láti yẹ ìwé tòun fẹ́ fi kọ́ṣẹ́ náà wò.
Fún Oluwafemiayo, bí àwọn èèyàn ṣe máa ń dẹ́yẹ sí àwọn àkàndá jẹ́ ohun tó lágbára púpọ̀.
“Mo sun ẹkún kíkorò, ìyá gbìyànjú láti fọwọ́ lémi ní èjìká. Inú mi kò dùn, mo sì máa ń rò ó pé kò sí ayé fún àwa àkàndá, wọn ò lè dé ibi tí wọ́n bá fẹ́ lọ, wọn ò lè ṣe nǹkan tó bá wà lọ́kàn wọn.
“Ṣé nítorí mo jẹ́ jẹ àkàndá èèyàn ni mi ò ṣe lè ṣe iṣẹ́ nọ́ọ̀sì? Mo ṣì ní èròńgbà láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ nọ́ọ̀sì títí di àsìkò yìí.”
Polio àti Olùkọ́ni John
Folashade Oluwafemiayo pàdánù ẹsẹ̀ rẹ̀ nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mẹ́ta sọ́wọ́ àìsàn rọmọlápá rọmọlẹ́sẹ̀ (pólíò) ní ìlú Jos, ìpínlẹ̀ Plateau, ìlú tó gbé dàgbà.
Ó ṣàlàyé pé ẹsẹ̀ tí òun pàdánù náà mú kí ìgbà èwe nira fún òun nítorí ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń wu òun láti ṣe àmọ́ tí òun kò ní lè ṣe nítorí ẹsẹ̀ òun.
“Àwọn eré kan wà tí mà á fẹ́ ṣe àmọ́ nítorí tí mo jẹ́ àkàndá, mi ò ní lè ṣe wọ́n”
“Nǹkan tó máa ń dùn mí gidi ni pé kí n rí àwọn ẹgbẹ́ mi kó máa sáré tí èmi kò sì ní lè sáré bí i wọn àfi ki máa rá kòrò nílẹ̀.”
Ó ní ìgbé ayé òun yípadà nígbà tí mọ̀lẹ́bí òun kan sọ nípa eré ìdárayá àwọn àkàndá fún òun.
Ní ọdún 1999 ló bẹ́rẹ́ sí ní gbé irin ní pápá ìṣeré Rwang Pwam tí ìlú Jos bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi gbogbo ara sí iṣẹ́ náà níbẹ̀rẹ̀.
Ó sọ pé olùkọ́ni kan, John Oguntoye ló rí àrà tí òun lè dá, tó sì mú òun lórí lọ́rùn láti fara sí irin gbígbé náà.
“Lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tí mo lọ, mo gbé irin tó tó ìwọ̀n ọgọ́rin kílógíráàmù. Olùkọ́ni náà ní mo ní agbára gan àti pé mà á ṣe dada nínú eré ìdárayá náà.
“Àmọ́ nítorí ìnira tí mo rí níbẹ̀, mo sá, mi ò lọ ní ọjọ́ kejì àmọ́ Oguntoye kò fi mí sílẹ̀ kódà ó wámi wá sí ilé wa láti fún mi ìwúrí láti padà fún ìkọ́ni.
Pípadà láti máa lọ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ìpinnu tí Oluwafemiayo kò kábàámọ̀ rẹ̀ rárá.
Ó ní òun tẹ̀lé olùkọ́ni náà, òun sì bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àkàndá bíi tòun pàdé níbẹ̀, bí òun ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé irin nìyẹn.
Ní ọdún 2010 ló darapọ̀ mọ́ ikọ̀ àwọn àkánda eléré ìdárayá Nàìjíríà.
Ẹ̀sùn lílo egbògi olóró

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní ọdún 2012 ó kópa níbi ìdíje Olympic tí àwọn àkàndá ní ìlú London fún ìgbà àkọ́kọ́.
Níbi ìdíje náà ló ti fìtàn balẹ̀ pẹ̀lú ipò kejì tó gbé nínú ìdíje gbígbé irin oní kìlógíráàmù márùndínlọ́gọ́rin.
Ọdún kan lẹ́yìn náà ni wọ́n fi òfin dè é pé kò lè kópa nínú ìdíje eré ìdárayá fún ọdún méjì nígbà tí wọ́n ṣàwárí oògùn olóró furosemide lára rẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé lásìkò tí oyún kan bàjẹ́ lára òun ti wọ́n gbé òun dìgbàdìgbà lọ sí ilé ìwòsàn ni dókítà fún òun ní oògùn tí kò yẹ kó fún òun nítorí wọn kò ṣàlàyé fun wí pé òun máa ń ṣe eré ìdárayá.
Bákan náà ni kò ríbi kópa níbi Paralympics tọdún 2016 tó wáyé ní Rio de Janeiro nítorí oyún tó ní lásìkò náà.
Àmọ́ láti ìgbà tó ti padà sẹ́nu iṣẹ́ padà ló ti ń ṣe gudugudu méje pẹ̀lú yàyà mẹ́fà, tó sì ti gbé ipò kìíní nínú ìdíje Commonwealth àti Paralympics.
“Gbígbé ipò kìíní ní àwọn ìdíje yìí ní ìtumọ̀ sí mi gidi. Ó máa ń jẹ́ kí n rí ara rẹ̀ mi bíi ọ̀kan náà pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ mi tí kìí ṣe àkàndá.”
“Kò sí nǹkan tí abarapa le ṣe tí èmi náà kò lè ṣe”
Bí ó ṣe ń gbèrò láti tún ṣe bẹbẹ ní ìdíje Paralympics tọdún 2024 ní Paris, wọ́n ti kéde rẹ̀ bíi olórí ikọ̀ rẹ̀ fún Nàìjíríà níbi tí yóò ti máa díje ní ipele kílógíráàmù mẹ́rìndínláàdọ́rùn-ún, èyí tó pọ̀ jùlọ fún àwọn obìnrin.
Oluwafemiayo yóò máa wàákò pẹ̀lú Zheng Feifei ti China àti Nataliia Oliinyk ti Ukraine.
“Kìí ṣe nǹkan tó rọrùn rárá nítorí ìdíje tí mo lọ kẹ́yìn ní Tbilisi lágbára gan, Feifei àti Oliinyk ń gbèrò láti ri pé wọ́n gba ipò kìíní lọ́wọ́ mi, níṣe ni à ń gbé ẹnu tẹ̀lé ara wa.
‘Aago mẹ́ta òru ni mo máa ń jí’

Ní báyìí tó ti ń gbé ní ìpínlẹ̀ Eko, Oluwafemiayo máa ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní pápá ìṣeré ìjọba àpapọ̀ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ mìíràn bíi Bose Omolayo tòun náà ti léwájú ní ìdíje Paralympics lẹ́ẹ̀mejì.
Ó ní aago mẹ́ta òru ni òun ti máa ń jí láti lọ sí pápá ìṣeré fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nítorí ó jìnà sí ilé òun.
“Ọ̀kadà méjì ni mà á kọ́kọ́ gùn dé ibi tí mà á ti wọ ọkọ̀ tó máa gbé dé ibi tí mà á ti wọ ọkọ̀ dé pápá ìṣeré.”
Ó ní ìfarajìn àti àwọn àṣeyọrí tí òun ní jẹ́ ìwúrí fún àwọn ọmọ òun méjéèjì tí wọ́n sì máa ń darapọ̀ mọ́ òun tí òun bá ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nílé.
Ọkọ Oluwafemiayo, Tolu-Lope Taiwo náà jẹ́ àkàndá tí òun náà ń jòkòó sórí kẹ̀kẹ́ arọ náà díje níbi Paralympics 2012 àti 2016.
Ó ní ìyàwó òun máa ń ṣe ìwúrí fún òun àti pé inú òun máa ń dùn láti sọ fún àwọn èèyàn pé òun ni ìyàwó òun.
Oluwafemiayo ní èròńgbà òun ni láti jẹ́ ìwúrí fún ìran tó ń bọ̀ kí Nàìjíríà lè bà máa tẹ̀síwájú nínú ìdíje eré ìdárayá.
“Ó wù mí láti gbé ògo ilé mi, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Áfíríkà ga”
“Èyí kọ́ ni ìdíje tí mà á kópa níbẹ̀ kẹ́yìn, mo ṣì ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ láti kópa nínú ìdíje káàkiri àgbáyé.”










