Lẹ́yìn ìwọ́de Ọlọ́kadà àti Oníkẹ̀kẹ́, ìjọba Kwara gbé ọkọ̀ ọ̀fẹ́ kalẹ̀ f'áráàlú àti àjọ tí yóò rísí sísan owó oṣù tuntun fáwọn òṣìṣẹ́

Ijọba ipinlẹ Kwara ti bẹrẹ si ni pese ọkọ ọfẹ fawọn araalu ni ilu Ilorin ti o jẹ olu ilu ipinlẹ naa.
Igbesẹ yii lo n waye nitori iyansẹlodi tawọn onikẹkẹ ati ọlọkada ṣe lọjọbọ ni ilu Ilọrin.
Iyansẹlodi naa si lo da lori bi epo bẹntiroolu ṣe gbowo lori, tawọn ileepo si n ta jala epo bẹntiro ni ẹgbẹfa naira si aadoje naira.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ gomina Abdulrahman Abdulrasaq, Rafiu Ajakaye ṣe sọ, ijọba gbe awọn ọkọ ọfẹ naa kalẹ lati mu idẹkun ba araalu lasiko ọwọn gogo epo bẹntiroolu ati iyanṣẹlodi tawọn onikẹkẹ ati ọlọkada gunle.
Ajakaye, nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ ni ilu Ilọrin, to jẹ olu ilu fun ipinlẹ Kwara nikan ni eto naa yoo ti maa waye, nitori Ilorin ni ibi ti awọn eniyan pọ si julọ ni ipinlẹ Kwara.
O ṣalaye pe kii ṣe pe awọn ilu to ku to wa ni ipinlẹ Kwara ko ṣe pataki, o ni idi ti awọn fi pese eto naa sinu Ilọrin lasiko yii ko ṣẹyin pe ibẹ ni awọn oriko ileeṣẹ ijọba pọ si julọ ati pe ibẹ ni awọn eeyan ti maa n lọ si ọna to jina julọ.
Ìgbà wo ni ọkọ̀ ọ̀fẹ́ náà fi máa wà fún lílò àwọn aráàlú dà?
Rafiu Ajakaye tẹsiwaju pe “Ọpọ awọn ile ẹkọ, ile iṣẹ ijọba àti ti aladani lo pọ ni Ilorin ju awọn agbegbe yooku lọ.”
O sọ pe awọn ọkọ naa yoo wa ni gbagede, awọn ibi to jẹ orikusu tawọn awọn eniyan pọ si ati pe awọn eeyan mọ awọn ibi ti wọn ti maa n wọ awọn ọkọ naa nitori ijọba ko ṣẹṣẹ maa gbe awọn eto yii kalẹ nigba ti inilo ba wa fun.
Nigba to n dahun ibeere lori igba ti eto naa maa fi wa nilẹ da, Ajakaye ni "mi o le sọ pato igba ti ijọba yoo fi ṣe eyi.
Gẹgẹ bi mo ṣe sọ, eto idẹrun ni ijọba n ṣe e lati mu idẹrun ba awọn eniyan ni, paapaa julọ nitori pe o ṣe pataki lasiko ti awọn onikẹkẹ ati awọn ọlọkada daṣẹ silẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
"Ìjọba ti ń ṣiṣẹ́ láti ṣe àmúṣẹ owó oṣù tuntun to kere julọ fawọn osisẹ"
Lasiko iwọde àwọn ọlọ́kadà àti oníkẹ̀kẹ́ to waye, ni awọn òṣìṣẹ́ Kwara ti n kọminú pe owo ti àwọn fi ń wọ ọkọ lọ si ibiṣẹ pọ púpọ̀, ju iye ti àwọn n gba loṣu lọ.
Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, awọn òṣìṣẹ́ náà ni pẹ̀lú àlékún tó tún gorí iye epo bẹntiróòlù yìí, yóò nira fún àwọn láti rí oúnjẹ jẹ mọ́.
Ajakaye ninu esi rẹ si eyi ni lẹyin ti aarẹ buwọlu ofin owo oṣù osisẹ to kere ju naa ni ìjọba Kwara tí gbe igbimọ kalẹ lati wo bi wọn yóò ṣe àmúṣẹ rẹ̀.
"Ijọba Kwara ti gbe ajọ kan kalẹ ti Kọmiṣanna fun eto isuna ni Kwara jẹ alaga ajọ naa, a si ni awọn ọmọ ẹgbẹ òṣìṣẹ́ tó fi mọ awọn alẹnulọrọ lori ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́.
“Ajọ naa n ṣiṣẹ lọwọ, lẹyin igba ti wọn ba pari eto ati iwadii wọn, igbesẹ owo sísan yoo bẹrẹ.”
Bakan naa lo ni ijọba Kwara n reti atẹ lati fi san owo latọdọ ijọba apapọ lori ati san owo awọn oṣiṣẹ.
"Nitori yato si awọn ti yoo gba N70,000, owo awọn ọga naa yoo gbe pẹẹli, eyi ni awọn ajọ naa yoo sọ ti yoo gun rege, ki ijọba ati awọn oṣiṣẹ le pade loju kan
Àwọn ọlọ́kadà, kẹ̀kẹ́ da iṣẹ́ sílẹ̀ ní Ilọrin báwọn iléepo ṣe ń ta bẹntiro lítà kan ní ₦1,200

Awọn onikẹkẹ ati olọkada ni ilu Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara lọjọ Karun-un, oṣu Kẹsan-an ọdun 2024 lo ti bẹrẹ ifẹhonuhan lori ẹkunwo tuntun to ba epo bentiro tuntun ti ijọba ṣẹṣẹ kede.
Awọn ọlọkada ati kẹkẹ, to jẹ ohun elo tawọn eeyan ipinlẹ Kwara paapaa ilu Ilọrin maa n lo julọ lati fi lọ lati ibi kan bọ si ibomiran, pa kẹkẹ ati ọkada wọn ti, wọn si gbegi dina ki ọkọ tabi ọkada ma baa rọna gba kọja lawọn agbegbe to ṣe koko.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn ọlọkada ati onikẹkẹ naa ko kede pe awọn fẹ ṣe iwọde tabi Ifẹhonuhan yii sibẹ kaluku wọn lo duro ni ibudo ikero wọn, ti wọn si kọ lati ṣiṣẹ tabi gba ki awọn akẹgbẹ wọn miiran ṣiṣẹ.
Awọn agbegbe ti BBC News Yoruba sabẹwo si ti ifẹhonuhan ọhun ti waye ni opopona Gaa-Akanbi, Sango, Tanke, Unity, Maraba, Murtala, Gambari, Ipata, Garaji Offa ati awọn ibo mii.
Oun ti awọn olufẹhonuhan naa n sọ ni wi pe owo ti awọn n ra epo lati bii ọjọ meloo kan sẹyin ti ọwọn gaogo epo ti wa ko rọ awọn lọrun rara ṣugbọn awọn n fara da a
Wọn ni amọ o jẹ ohun to ka awọn laya lowurọ ọjọbọ ni pe niṣe ni awọn ile epo bẹrẹ si ni n ta epo ni ẹgbẹfa naira (N1,200) tawọn mii si n ta a ni aadoje naira (N1,300).
"A o ri owo fi ṣe nnkan mọ lẹyin ti a ba ra epo"

Ọkan ninu awọn onikẹkẹ, Hakeem Mustapha to n na opopona Tanke lati Ọja Ọba sọ di mimọ pe iya naa pọ ti ijọba n fi jẹ awọn nitori epo ni awọn n fi gbogbo owo tawọn ba pa ra.
O ṣalaye pe, ti awọn ba n ra epo ni N1,200 ni lita kan bayii, "elo ni a fẹ gbe ero ti yoo pe wa, a o si tun ra paati kẹkẹ ka ma wa sọ owo 'deliver' ojoojumọ.
“Iyawo ati awọn ọmọ wa nile, kini wọn fẹ ki a fi bọ wọn, ti ìjọba ko ba tete wa nnkan ṣe si ọrọ to wa nilẹ yii, nnkan ma le ju baiyi lọ, a o si ni sinmi.
"Ifẹhonuhan ti a n se lọwọ yii, a o gbero rẹ, a o si gbaṣẹ lọwọ awọn adari wa tori a o fẹ ki ẹnikẹni pana ẹ, bo ṣe ri lara wa la ṣe bẹrẹ rẹ lowurọ oni, eyi tumọ si pe ti ijọba o ba ṣe nnkankan lori ọwọn gogo epo ati ounjẹ yii, ohun ti yoo pada dalẹ, agbara ijọba o ni ka.
Ni Gaa-Akanbi, ẹlomiran to tun ba wa sọrọ, Jamiu Mukaila kọminu lori bi ijọba ko ṣe i tii bẹrẹ sisan owo oṣu to kere julọ ti ijọba apapọ buwọlu fawọn oṣiṣẹ.
Erongba Mukaila ni pe bi ijọba ba bẹrẹ si ni san owo yii fawọn oṣiṣẹ yoo tunbọ mu nnkan rọrun si ati pe awọn oniṣẹ ọwọ ati oniṣowo yoo jẹ nibẹ nitori awọn oṣiṣẹ maa ri owo ra nnkan.
"Ilu le koko, ijọba o ṣe amusẹ ileri wọn, N70,000 owo oṣiṣẹ to kere ju ni wọn fi ontẹ lu ṣugbọn wọn ko san-an.
“Ṣebi ti wọn ba san-an yoo kan awa oniṣẹ ọwọ naa ṣugbọn gbogbo eeyan ni ilu le mọ nitori ijọba kọ lati ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe.”
Gbogbo owo oṣu la fi n wọkọ lọ si ibiṣẹ - awọn ara ilu kọminu

Nigba ti BBC News Yoruba kan si alaga onikẹkẹ tẹka Unity, ọgbẹni Suleiman Onifitila sọ pe oun o mọ nnkan to n sẹlẹ nitori oun o pasẹ ifẹhonuhan bẹẹ si ni ọmọ ẹgbẹ kan o gbaṣẹ lọwọ oun ki wọn to bẹrẹ.
"Sugbọn alaga wa ni Kwara ti ransẹ pe gbogbo awọn alaga ẹka kọọkan lati pẹẹtu si awọn eniyan wa ki iṣẹ ba a le tẹsiwaju.
"Ni temi, ara n ni araalu, a o lagbara tojọba sugbọn a n rọ wọn ki wọn saanu wa ki nnkan o dẹ"
Bakan naa, araalu kan to jẹ oṣiṣẹ ijọba to bẹbẹ pe ka fi orukọ bo oun laṣiri sọ pe owo osu gan-an ko to wọ ọkọ lọ si ibisẹ mọ bayii.
O ni niṣe ni ọpọ ninu awọn ti pa mọto ti nitori owo epo le e dayan nigbese.
"Ni ijọba ana a n fi epo N5000 lọ ibisẹ lọsẹ, sugbọn bayii, agbara kaka ni N50,000 yoo fi to.
"A bẹ ijọba apapọ ki wọn tete gbe igbesẹ tori, ebi n pa awọn eeyan, nnkan ti ṣe awọn eeyan sara, aṣọ nikan ni wọn fi n gbe"
Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Kwara ti ko awọn ọkọ jade lati maa kiri inu igboro ilu Ilorin, ki wọn si maa gbe awọn araalu ni ọfẹ.
Ijọba ṣe eleyi lati mu irọrun ba awọn eniyan ati dẹkun laasigbo ni asiko ọwọn gogo epo yii.
















