Ọkùnrin tó yìnbọn fún ọkùnrin míì tó ká mọ́ orí ìbùsùn ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, wọ gàù

Oríṣun àwòrán, Ondo Police
Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá nípinlẹ Ondo safihan ọkunrin kan, Joseph Ajegba, ẹni tí ọwọ tẹ fun ẹsun pe o sina bolẹ fun ọkunrin kan to ka pẹlu ọrẹbinrin rẹ ni agbegbe Akoko ni ijọba ibilẹ guusu Akoko nipinlẹ Ondo
Afurasí, ẹni to jẹ pe ọdẹ ninu igbo ni yín ìbọn fun ọkùnrin ẹgbẹ rẹ, tí oun naa jẹ ọdẹ ni ẹsẹ nitori o ba ọrẹbinrin rẹ ni ajọsepọ.
Nigba to n safihan afurasi naa, Kọmisọna fun ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Ayobami Oladipupo ni oṣu to kọja ni ọwọ tẹ Joseph fun ẹsun naa.
"Iṣẹlẹ yii ni wọn fi to Ọlọpaa leti pe ẹni to fi ara kaasa ibọn yii lọ sile ọrẹbinrin rẹ, ẹni ti ko si ni ile ọkọ ni ile rẹ.
Ọkùnrin mii tí orúkọ rẹ n jẹ Joseph Ajegba, ẹni ọdun mejidinlogoji, ti oun naa n fẹ obìnrin yii, ba ba ọkunrin miran pade nibẹ nile ọrẹbinrin rẹ naa.
"O ba mi lọkan jẹ pupọ pe akẹgbẹ mi n ba ọrẹbinrin mi lopọ, ni mo se gbe ibọn fun"
Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá tẹsiwaju pe "Bi Joseph ṣe rí ọkùnrin mii lori ibusun ni afurasi naa gbe ìbọn fun lati oju ferese.
"Ọwọ tí tẹ afurasí naa pẹlu ìbọn ọwọ r,ẹ tí eeyan ti ìbọn ba si ti wa ni ile iwọsan níbi to ti n gba itọju."
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, afurasí naa ni o ba oun lọkan jẹ pupọ pe akẹgbẹ oun ba ọrẹbinrin oun sun.
"Mo lọ oko ọdẹ lẹyin ti mo mu igo ọtí diẹ sugbọn ọta tan ninu ìbọn mi, mo wa ni kí n lọ ile ololufẹ mi ni mo ba ilẹkun ni titi.
"Mo wa lọ oju ferese, bi mo ṣe si ni mo rí akẹgbẹ mi pẹlu ọrẹbinrin mi.
"Nítorí eyi ni mo fi lo ìbọn ọwọ mi."
Ọlọpa safihan afurasi to pa ọga rẹ ni Akure
Bakan naa ni ileeṣẹ Ọlọpaa tun safihan ọmọ ọdun mẹtadinlogun, Phillip Emmanuel ẹni tí wọn fẹsun kan pe o lọwọ ninu iku arabinrin kan, Deborah Adene.
Adene ni wọn ṣekupa si ile rẹ ni ilu Akure.
Gẹgẹ bii Kọmisọna ṣe salaye Emmanuel jẹ ọkan lara osisẹ oloogbe ko to jade laye.
"Ni ọjọ kẹdọgbọn oṣu keje ọdun 2024, Emmanuel ati Dẹrẹba oloogbe lẹdi apupọ lati ṣekupa oloogbe.
"Lẹyin ti wọn pa, wọn ji ATM, ti wọn si yọ owo toto ẹgbẹrun lọna ọgọta naira.
"Dẹrẹba ti salọ sugbọn owo yoo tẹ ni aipẹ.















