Ojú pópó lọ́jú pọ̀ torí ìlà gbọ́ọrọ láwọn iléepò bí ọ́wọ̀ngógó bẹntiró ṣe ń tẹ̀síwájú

Ni Naijiria, epo bẹntiro ti gbowo lori, bẹẹ naa ni ko tun si epo ọhun niluu.
Ajọ NNPC to n ko epo wọle si Naijiria ko to maa ta a fun awọn ileeṣẹ to n pin epo ka ti sọ pe gbese owo gọbọi kan ti oun jẹ, to fi mọ iye owo epo lagbaye lo ṣokunfa ọwọngogo epo naa.
Ọpọ araaalu ni ko ri aye lọ ibi iṣẹ oojọ wọn bayii latari bi ọpọ ọkọ ṣe to si awọn ile epo fun ọpọ wakati.
Ọpọ awakọ lo n lo aimọye wakati lati to ra epo bẹntiro, bẹẹ ni wọn tun n ra epo naa ni ọwọngogo
Bẹẹ ni ọrọ naa ri kaakiri Naijiria, paapaa niluu Eko to ni ọpọlọpọ ọkọ akero amọ ti awọn ọkọ naa ko le ṣiṣẹ latari airi epo ra.
Awọn eeyan kan to ba BBC sọrọ sọ pe ṣe lawọn n fi ẹsẹ rin ọna jinjin nitori iṣọro naa.
Ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni NNPC kede pe oun n gbe owo epo soke lati N580 si N897.
Awọn ile epo to jẹ ti NNPC ni owo epo rẹ kere julọ nigba ti owo epo awọn ile epo aladani wọn ju ti NNPC lọ.
Lọwọ yii, pupọ awọn awakọ lo n lo ọpọ wakati lati to fun epo bẹntiro, bẹẹ ni wọn tun n ra epo naa ni ọwọngogo.
Ni kete ti NNPC ba ti fi le owo epo naa ni awọn ile epo aladani yoo fi le owo tiwọn.
Ni bayii, N1,200 ni wọn n ta epo lawọn ipinlẹ bii Oyo, Ondo, Kano ati Kaduna.
Kaakiri Naijiria lawọn ibudokọ kan si ti kọsẹ latari pe awọn awakọ ko ri epo ra.
“Mo ri epo ra ni N950 nile epo kan ṣugbọn lawọn ibomii, N1,200 ni wọn n ta jala epo kan”
Niluu Abuja, pupọ ninu ile epo lo ṣilẹkun wọn ṣugbọn ero to wa lori ila lati ra epo fẹ ẹ pọ ju iye epo to wa lọ.
Ọkunrin ọlọkada kan niluu Kano sọ pe “pupọ awọn ile epo lo tilẹkun wọn nibi latari pe wọn fẹ fi kun owo epo.
“Mo ri epo ra ni N950 nile epo kan ṣugbọn lawọn ibomii, N1,200 ni wọn n ta jala epo kan.”
Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣiṣẹ, NLC ti sọ pe ijọba Tinubu dalẹ awọn latari bo ṣe yi ohun pada lori adehun to ni pẹlu wọn tẹlẹ nipa afikun owo epo naa.
Ọjọ akọkọ ti Tinubu gba ijọba Naijiria lo kede pe opin ti de ba owo afikun ori epo bẹntiro, lati ọjọ naa ni epo ti bẹrẹ si n wọn, ti ọwọngogo si gbode ni Naijiria.















