Àwọn wo ni 'Grey Wolves', kí nìdìí tí wọ́n ń fòfin dè wọ́n káàkiri orílẹ̀ èdè?

    • Author, Ege Tatlici and Selin Girit
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Subbed by Kateryna Khinkulova, Europe Hub

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Grey Wolves méjì tí wan ń ṣe àmì ìkíni ìkokò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ikọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú kan ní orílẹ̀ èdè Turkey, The Grey Wolves, ni òkìkí wọn ti ń tàn káàkiri àgbáyé, tó fi mọ́ àmì ọwọ́ ti wọ́n máa ń lò láti ṣe orí ìkokò.

Àmì ọwọ́ yìí ṣokùnfà awuyewuye ńlá níbi ìdíje bọ́ọ̀lù Euro 2024 nígbà tí agbábọ́ọ̀lù Merih Demiral, ọmọ orílẹ̀ èdè Turkey ṣe àmì ọwọ́ yìí lẹ́yìn tó gbá bọ́ọ̀lù sáwọ̀n níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí orílẹ̀ èdè rẹ̀ gbá pẹ̀lú Austria.

Góòlù méjì sí ẹyọ̀kan ni Turkey fi na Austria.

“A ò fi ààyè gba àmì àwọn alákatakítí Turkey ní àwọn pápá ìṣeré wa,” Mínísítà abẹ́nú orílẹ̀ èdè Germany, Nancy Faeser sọ nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sójú òpó X rẹ̀. UEFA fòfin de Demiral láti má kópa níní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ méjì lẹ́yìn rẹ̀.

Turkey fèsì padà pé ìwà ìdẹ́yẹsí ni Germany wù bí wọ́n ṣe bu ẹnu àtẹ́ lu àmì ìkokò tí Demiral ṣe.

Ààrẹ Turkey, Erdogan ní kò sí ẹni tó ń bi Germany léèrè ìdí tí àṣá ṣe wà lára aṣọ tí wọ́n ń wọ̀ fi gbá bọ́ọ̀lù tàbí tí àkùkọ ṣe wà lára aṣọ ti France.

Merih Demiral ní Euro 2024

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àmì ọwọ́ yìí ṣokùnfà awuyewuye ńlá níbi ìdíje bọ́ọ̀lù Euro 2024 nígbà tí agbábọ́ọ̀lù Merih Demiral, ọmọ orílẹ̀ èdè Turkey ṣe àmì ọwọ́ yìí lẹ́yìn tó jẹ góòlù

Lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Grey Wolves organization nìkan ló máa ń lo àmì náà láti fi kí èèyàn. Àwọn ọ̀dọ́ ẹgbẹ́ Nationalist Movement Party (MHP), tó jẹ́ abẹ́ṣinkáwọ́ ẹgbẹ́ ààrẹ Erdogan ló ní ẹgbẹ́ náà.

Germany kò fòfin de lílo àmì ọwọ́ ìkokò láti fi kí èèyàn tàbí ẹgbẹ́ Grey Wolves ní orílẹ̀ èdè náà àmọ́ Austria àti France kò fàyè gbà wọ́n rárá.

'Ẹgbẹ́ alákatakítí ètò òṣèlú'

“Nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ Grey Wolves ní Germany, ohun tí à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni ẹgbẹ́ àwọn èèyàn kan ní àdúgbò kan tàbí ilé oúnjẹ,” Burcu Ozcelik tó jẹ́ olùwádìí ní Royal United Services Institute (RUSI) sọ.

Ó wòye pé àwọn tí wọ́n ń rí ara wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ Grey Wolves ní Germany jẹ́ àwọn tó ní ìfarajìn sí ẹgbẹ́ náà lọ́nà kan tàbí òmíràn.

Iléeṣẹ́ tó ń rí sí ààbò ìwé òfin Germany (BfV) júwe Grey Wolves bíi ẹgbẹ́ àwọn alákatakítí tí wọ́n ní ọmọ ẹgbẹ́ tó tó 18,500 sí 20,000 ní orílẹ̀ èdè náà.

Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Turkey ni ẹ̀yà kéréje tó pọ̀ jùlọ ní Germany, bí àwọn ọmọ Tukey tó ń gbé ní Germany ṣe tó mílíọ̀nù mẹ́ta nínú mílíọ̀nù mẹ́rìnlélọ́gọ́rin àwọn èèyàn tó ń gbé ní Turkey.

Ọwọ́ tó ń ṣàfihàn àmì ìkíni ìkokò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Austria fòfin de lílo àmì ọwọ́ ìkokò lọ́dún 2019, tí France sì fòfin de gbogbo ètò Grey Wolves lọ́dún 2020

Akọròyìn Kemal Can ní àmì àti ìṣọ̀kan ṣe pàtàkì sáwọm ọmọ Turkey tó ń gbé ní Yúróòpù.

“Àwọn ẹlẹ́sìn Islam àtàwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Turkey tó wà ní Yúróòpù létò púpọ̀ tí wọ́n sì wà ní ìṣọ̀kan. Èyí máa ń kan àwọn ìjọba ilẹ̀ yúróòpù lóminú pé àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tó létò bẹ́ẹ̀ lè fa wàhálà nínú ìlú.”

“wọ́n fẹ́ gbé àwọn ètò láti kán ìyẹ́ wọn ní orílẹ̀ èdè wọn àti láwọn ìlú tó súnmọ́ wọn.”

Ìwà ipá

Láti nǹkan bíi ọdún 1970 ni orílẹ̀ èdè Turkey àti Yúróòpù ti máa ń fi ẹ̀sùn ìwà ìpáǹle kan àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Grey Wolves.

Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀sùn náà tó lágbára tí wọ́n fi kan Mehmet Ali Agca, tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Grey Wolves pé ó gbìyànjú láti dá ẹ̀mí Pope Jean Paul II légbodò lọ́dún 1981.

Wọ́n yìnbọn mọ́ olórí ìjọ àgùdà nígbà náà tó sì farapa.

Pope John Paul II àti Mehmet Ali Agca

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ní 1983, Pope John Paul II àti Agca pàdé ní ọgbà tí wọ́n fi sí
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Láti nǹkan bíi ọdún 1970 ni orílẹ̀ èdè Turkey àti Yúróòpù ti máa ń fi ẹ̀sùn ìwà ìpáǹle kan àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Grey Wolves.

Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀sùn náà tó lágbára tí wọ́n fi kan Mehmet Ali Agca, tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Grey Wolves pé ó gbìyànjú láti dá ẹ̀mí Pope Jean Paul II légbodò lọ́dún 1981.

Wọ́n yìnbọn mọ́ olórí ìjọ àgùdà nígbà náà tó sì farapa.

Ẹgbẹ́ náà lọ́wọ́ nínú àwọn ìjà ìgboro tó wáyé ní Turkey láàárín ọdún 1970 sí 1980 nígbà tí àwọn ọmọ náà ṣèkọlù sí ẹgbẹ́ mìíràn.

Bákan náà ni èrò wà pé Grey Wolves ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Turkish deep state, ikọ̀ tí ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n jẹ́ alágbára, tó lòdì sí ìjọba àwaarawa ní Turkey.

Ọ̀pọ̀ àwọn ìjà ìgboro ló ti wáyé ní àwọn ìlú orílẹ̀ èdè Yúróòpù, tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Grey Wolves sì lọ́wọ́ nínú rẹ̀.

Burcu Ozcelik ní àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí ló ń da ìbẹ̀rùbojo sọ́kàn àwọn èèyàn àti orílẹ̀ èdè lórí àwọn ẹgbẹ́ náà.

Ní Germany, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé awuyewuye wà lórí rẹ̀, Grey Wolves kìí ṣe ẹgbẹ́ tí ìjọba fòfin dè àmọ́ Austria fòfin de lílo àmì ìkokò lọ́dún 2019, tí France náà sì fòfin dé gbogb nǹkan tó jẹ mọ́ Grey Wolves lọ́dún 2020.

Lọ́dún 2021 ni wọ́n gba àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù nímọ̀ràn láti fi Grey Wolves sínú àwọn ẹgbẹ́ agbéṣùmọ̀mí.

Àwọn èèyàn tó ń ṣe àmì ìkokò níbi ìwọ́de kan ní Istanbul

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Turkey ní kò sí ẹgbẹ́ tó ń jẹ́ Grey Wolves àti pé fífi òfin de ìkíni pẹ̀lú àmì ìkokò jẹ́ ohun tí àwọn kò faramọ́

Àwọn awuyewuye tó ń wáyé lórí ẹgbẹ́ náà kọjá ilẹ̀ Yúróòpù nìkan.

Ní Azerbaijan, orílẹ̀ èdè tó ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Turkey, awuyewuye wáyé lórí Grey Wolves níbẹ̀ lórí ẹ̀sùn pé wọ́n lọ́wọ́ nínú ìdìtẹ̀gbàjọba kan láti gba ìjọba lọ́wọ́ Heydar Aliyev, ẹni tó jẹ́ bàbá ààrẹ tó wà lórí ipò báyìí, Ilham Aliyev lọ́dún 1995.

Olóòtú ìròyìn BBC News Azerbaijan, Könül Khalilova, ní Heydar Aliyev ri ẹgbẹ́ náà bí ìdúnkokò mọ́ ìjọba rẹ̀.

Èyí ló mu fòfin de Grey Wolves ní Azerbaijan, tí wọ́n sì pa olórí wọn lásìkò ìdìtẹ̀gbàjọba ọ̀hún.

Ní 2005, orílẹ̀ èdè Kazakhstan, tí òun náà ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Turkey lédè àti àṣà náà fòfin de Grey Wolves, tó sì kéde wọn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ agbéṣùmọ̀mí.

Turkey ní kò sí ẹgbẹ́ tó ń jẹ́ Grey Wolves àti pè àwọn kò faramọ́ bí wan ṣe fòfin de lílo àmì ìkokò láti fi máa kíra ẹni.

Lílo ìkokò gẹ́gẹ́ bí àmì

“Àmì ìkokò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àmì tó ṣe pàtàkì sáwọn èèyàn Turkey,” Ahmet Tasagil, Ọ̀jọ̀gbọ́n lẹ́ka èdè àti lítíréṣọ̀ Turkey ní ilé ẹ̀ka gíga fásitì Yeditepe sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn Anadolu.

Ó ní gbogbo àwọn ọmọ Turkey tó ń gbé ní ààrin gbùngbùn Asia ni wọ́n máa ń lo àmì yìí lásìkò sẹ́ńtúrì kẹrin àti karùn-ún.

Ó ní ìkokò túmọ́ sí ọgbọ́n inú, tó jẹ́ olùtọ́sọ́nà fún àwọn èèyàn Turkey.

Ìkokò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lásìkò Ottoman, ní ìparí sẹ́ńtúrì kọkàndínlógún, àmì ìkokò jẹ́ èyí tí wọ́n ń lò dáadáa ní Turkey, lórí owọ àtàwọn nǹkan míì.

Lílo àmì ìkokò gẹ́gẹ́ bí àmì ìkíni jẹ́ ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Ní ọdún 1990 ló bẹ̀rẹ̀ ní Azerbaijan lásìkò àwọn ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn gẹ́gẹ́ bí Könül Khalilova ṣe sọ.

“Àwọn ìwọ́de yìí wà lára àwọn nǹkan tó jẹ́ kí orílẹ̀ èdè náà gba òmìnira, tó sì pa Soviet Union run.

Ìgbàgbọ́ ni pé olùdásílẹ̀ Nationalist Movement Pasrty ní Turkey rí bí wọ́n ṣe ń lo àmì ìkokò yìí níbi ìwọ́de ní Azerbaijan lọ́dún 1992, tó sì ń ṣe àmúlò rẹ̀ fún Grey Wolves ní Turkey.

'Kìí ṣe àmì ìlú'

Àwọn obìnrin níbi ìwọ́de ìlú kan tí wan ń ṣe àmì ìkokò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kemal Can ní ọ̀pọ̀ àwọn olóṣèlú ní Turkey ń lo àmì ìkokò láti lè fi fa ojú àwọn ará ìlú mọ́ra láti lè dìbò fún wọn.

Àmọ́ síbẹ̀, wọn kò ì tíì gba ètò ìkíni wọlé gẹ́gẹ́ bí nǹkan tí orílẹ̀ èdè yóò máa lò.

Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Turkey ni wọ́n fẹ́ràn láti máa ṣàmúlò àwọn nǹkan tó jẹ́ ti wọn àti lílo àmì ìkokò àmọ́ síbẹ̀ wọn kò faramọ́ ẹgbẹ́ Grey Wolves.