Ipa wo ni ookòwò China ti ní lórí Áfíríkà àti ètò rẹ̀ fún adúláwọ̀ lọ́jọ́ iwájú?

Oríṣun àwòrán, EPA
- Author, Jeremy Howell
- Role, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Orilẹede China ti n dokowo pẹlu ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu owo dọla l'awọn orilẹede Afirika bi ogun ọdun bayii.
China ti n ṣe eleyi nipa eto FOCAC to ni ṣe pẹlu ibaṣepọ laarin orilẹede China ati ilẹ Afirika.
Ọdun mẹta mẹta ni ipade FOCAC yii maa n waye lati sọ asọtepọ lori bi China at'awọn orilẹede Afirika ṣe le jọ ṣiṣẹ papọ.
Ọjọru si ọjọ Ẹti ọsẹ yii ni ipade ti ọdun yii yoo waye nibi ti Aarẹ Xi Jinping yoo ti ba awọn olori orilẹede Afirika sọrọ.
Bawo ni okowo China ṣe lọ l'Afirika?

Orilẹede China ni olubadokowo to pọju nilẹ Afirika ni nnkan bi ogun ọdun sẹyin bayii.
Okowo to to $250bn ni China ṣe pẹlu awọn orilẹ-ede ilẹ Afirika lọdun 2022.
China lo $5bn lati dokowo ninu ọrọ aje ilẹ Afirika lori igbokegbodo ọkọ, iwakusa ati iba mọnamọna.
Ni bayii, ẹgbẹrun mẹta okowo ni orilẹede China ni l'Afirika bayii.
Bakan naa ni China ti ya awọn orilẹ-ede Afirika ni owo to to $134bn.
Eyi jẹ ida 20% ninu gbogbo gbese ti ilẹ Afirika n jẹ gbogbo agbaye.
Amọ, China ko maa ya awọn orilẹ-ede Afirika lowo bii ti tẹlẹ mọ, tori ọpọ ninu wọn ni ko maa da owo ti wọn ya pada gẹgẹ bi adehun ti wọn tọwọ bọ.

Ọmọwe Alex Vines ti ileeṣẹ Chatham House to wa niluu London sọ pe "China ti n ṣọra ya ilẹ Afirika lowo bayii."
China ko sa ba ya awọn orilẹede Afirika lowo lati ṣe ọna, reluwe ati ibudokọ oju omi mọ, ẹka ẹrọ ibaraẹnisọrọ, lilo itanṣan oorun fun nkan to n lo ina ati ọkọ to n lo ina ni wọn n gbaju mọ julọ bayii.
Iru ipa wo ni idokowo China ti ni lori ilẹ Afirika?
Lati ọdun 1999 ni orilẹede China ti bẹrẹ eto idokowo pẹlu awọn orilẹede Afirika.
Ọdun 2003 ni ajọ FOCAC bẹrẹ eyi to ti ni ibaṣepọ lori idokowo bayii laarin China ati orilẹede ati orilẹede Afirika mẹtalelaadọta.
Fun apẹẹrẹ, China ya orilẹede Angola ni ẹgbẹlẹgbẹ owo lati kọ nnkan amayedẹrun ni ireti lati gba epo rọbi pada.
Eto pese iṣẹ bi ẹgbẹrun laadọsan fawọn ọmọ orilẹede China ni Angola.

Ẹwe, Ọjọgbọn Tsang ti sọ pe awọn eeyan igberiko ko janfani ọpọ akanṣe iṣẹ ti China n ṣe l'Afirika.
"China maa n sa ba ko awọn ọmọ ilu wọn wa ṣiṣẹ ti wọn ba n ṣe ni Afrika.
Bakan naa ni ọpọ eeyan maa n sọ pe iṣẹ to ba ni wọn maa fawọn ọmọ se.
Angola n jẹ China ni $18bn, Zambia n jẹ owo to le ni $10bn, nigba ti Kenya n jẹ China ni $6bn, gẹgẹ bi Chatham ṣe sọ.
Gbogbo awọn orilẹede Afirika yii ni o nira fun lati da owo naa pada.
Ọpọ igba ni China ti sọ pe ki awọn orilẹede Afirika ti wọn ya lowo fi nnkan alumọni wọn da owo naa pada.
Adari banki ADB ilẹ Afirika, Akinwunmi Adesina sọ fun ileeṣẹ iroyin Associated Press wi pe ki wọn ye gba iru owo bayii.
Ọmọwe Vines sọ pe China maa n wa ọna lati yan orilẹede ti wọn ba ya lowo jẹ nigba mii.
Ki ni eto ti China ni fun Afirika lọjọ iwaju?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọdun mẹta mẹta ni ajọ FOCAC maa n ṣe agbekalẹ ati ifilọlẹ eto to ba ni fun Afirika.
Ọmọwe Shirley Ze Yu ti ile ẹkọ London School of Economics ni o se pataki lati ṣiṣẹ pọ pẹlu China gẹgẹ bi oludokowo pẹlu Afirika.
"To ba ya, ida ogoji ninu ọgọrùn gbogbo eeyan to wa laye yoo wa ni Afrika.
Tori naa, ọwọ Afirika ni ọwọ ilẹ Afirika ni eto ọrọ aje agbaye wa lọjọ iwaju," Ọjọgbọn Yu lo sọ bẹẹ.
Amọ, Ọmọwe Vines woye pe kii ṣe ọrọ okowo nikan ni China fẹ ṣe pẹlu Afirika, o ni ọwọ oṣelu naa wa nbẹ.
O fikun ọrọ rẹ pe China ti rọ awọn orilẹede to le ni aadọta lajọ iṣọkan agbaye UN pe ki wọn ma ri Taiwan gẹgẹ bi orilẹede.
Ọjọgbọn Tsang ni "a ti n ri ohun ti China n wa ni Afirika diẹ diẹ bayii.
O fẹ lo ipo lati le jẹ ki ẹnu rẹ ranlẹ ninu ajọ iṣọkan agbaye UN, o si n wa atilẹyin awon orilẹede Afirika."
Bakan naa ni Ọjọgbọn Tsang tun sọ pe ko si ibadọgba ninu ajọ FOCAC ti China n ṣagbatẹru rẹ.
O ni ẹni to ba gba pẹlu China nikan ni o maa ri oju rere China ni ajọ FOCAC, eyi to tumọ si pe ko sẹni to le tako erongba tabi eto ti China fẹ ṣe.















