Wo bí orílẹ́èdè China ṣe ń lo tẹlifísàn sátáláìtì láti fa ojú àwọn ọmọ ilẹ̀ Afirika mọ́ra

Awọn to n wo tẹlifiṣan
    • Author, Shawn Yuan
    • Role, BBC Global China Unit
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Awọn olori orilẹede ilẹ Afirika pejọ si ilu Beijing lọsẹ fun apero ilẹ Afirika ati orilẹede China.

Ọkan gboogi lara awon nnkan ti Aarẹ Xi Jinping China le sọ pe o jẹ nkan iwuri ni tẹlifisan satalaiti.

Ni bi ọdun mẹwaa sẹyin ni Aarẹ Xi sọ wi pe oun yoo gbe tẹlifisan satalaiti de ẹgbẹrun mẹwaa abule ni orilẹede Afirika mẹtalelogun.

Ni bayii, abule 9,600 ni tẹlifisan satalaiti ọhun ti de nilẹ Afirika.

Ileeṣẹ tẹlifisan satalaiti StarTimes ni ijọba China n lo lati ṣe iṣẹ naa.

BBC ṣe abẹwo si abule mẹrin lorilẹede Kenya lati wo bi ileeṣẹ tẹlifisan satalaiti yii ṣe múlẹ si ni orilẹede naa.

Ni abule Olasiti ti BBC ṣe abẹwo si ni a ti ri Nicholas Nguku ti o ti n wo àwọn elereje Kenya ti wọn n sare ni idije Olympics pẹlu ẹbi at'awọn ọrẹ rẹ.

O ni inu oun fun anfani toun ni lati wo Olympics lori telifisan eyi ti ko ri bẹẹ fun ọpọlọpọ ọdun.

Nicholas Nguku ati ẹbi at'awọn ọrẹ rẹ n wo idije Olympics papọ.
Àkọlé àwòrán, Nicholas Nguku ati ẹbi at'awọn ọrẹ rẹ n wo idije Olympics papọ.

Kii ṣe Nicholas nikan lo n janfani tẹlifisan yii ni Afirika, lati ọdun 2008 ti o ti de ilẹ Afirika, eeyan to le ni miliọnu mẹrindinlogun ni wọn n lo Star Times bayii ni Afrika.

Onwoye kan ni owo rẹ ti ko gara lo kọkọ jẹ ko f'ẹsẹ múlẹ.

Ni Kenya, owo tawon eeyan n san lori Star Times loṣu bẹrẹ lati $2.50 si $14.

Opo satalaiti n ṣafihan ami Star Times ati ami ileeṣẹ ijọba Kenya to n ri si eto iroyin ati ami eto iranwọ China.

Satalaiti StarTimes lori ile kan labule ni Kenya
Àkọlé àwòrán, Satalaiti StarTimes lori ile kan labule ni Kenya

Ọmọwe Angela Lewis to ti kọ oriṣiiriṣii iwe apilẹkọ lori Star Times sọ pe ileeṣẹ tẹlifisan naa n sọ rere nipa orilẹede China laarin awọn to wo o l'Afirika.

Ọfẹ ni awọn eeyan to n janfani eto tẹlifisan satalaiti yii gba a l'awọn igberiko.

Ọmọwe Lewis sọ pe igba akọkọ ree ti ọpọ olugbe igberiko l'Afirika yoo lanfaani si telifisan oni satalaiti.

To fi di akoko yii, ọfẹ si ni gbogbo ile iwosan ati ile ẹkọ to wa ni abule Ainomoi to fi mọ owo oṣooṣu t'awọn eeyan n san lori tẹlifisan satalaiti ni ẹkun guusu orilẹede Kenya.

Awọn eeyan lanfaani bayii lati wo ohun to n lọ lori telifisan nile iwosan ati l'awọn ile ẹkọ igberiko.

Amọ, awọn ọmọ Kenya kan to ba BBC sọrọ ṣalaye pe igba diẹ naa ni awọn fi gbadun wiwo Star Times lọfẹẹ.

Rose Chepkemoi ni "inu gbogbo wa kọkọ dun nigba ti eto naa bẹrẹ lọfẹẹ, amọ, nigba to ya lẹyin oṣu meloo kan, a bẹrẹ si ni maa sanwo lati wo tẹlifisan satalaiti naa.

A ni lati pati s'ẹgbẹ kan tori owo rẹ lọ."

Ọpọ awọn olugbe abule ti wọn ti janfani tẹlifisan Star Times laarin ọdun 2018 si 2020 ni wọn sọ fun BBC pe awọn dekun lati maa lo o tori owo rẹ pọ.

BBC kan si ileeṣẹ Star Times lati fesi si ọrọ naa, amọ, wọn ko tii fesi di akoko yii.

Lọdun 2014 ni Star Times ṣe ifilọlẹ ikanni kan ti pe orukọ rẹ ni ST Swahili ti awọn eeyan yoo maa wo eto ni ede Swahili nikan lori rẹ.

Bakan naa ni Star Times tun n ṣafihan awọn eto kan ni ede Chinese.

Ere bọọlu l'awọn eeyan maa n wo julọ

Ere bọọlu afẹṣẹgba l'awọn eeyan ilẹ Afirika maa n wo julọ.

Fun apẹẹrẹ, eeyan bii biliọnu meji lo wo idije Afcon 2023 lori tẹlifisan kaakiri agbaye.

Star Times ti ṣe idokowo lati maa le ṣafihan ere bọọlu liigi La Liga, Bundesliga ati ti idije Afcon bakan naa.

Amọ, ọpọ eeyan ni Kenya ko fẹran lati maa wo liigi La Liga bii idije Premier League.

Star Times n gbiyanju lati fa oju awọn eeyan mọra mipa gbigbe liigi La Liga lori tẹlifisan
Àkọlé àwòrán, Star Times n gbiyanju lati fa oju awọn eeyan mọra mipa gbigbe liigi La Liga lori tẹlifisan

Ọmọwe Dani Madrid-Morales to jẹ olukọ ni fasiti Sheffield gbagbọ pe Star Times ko tii mu ayípadà nla ba eto iroyin ni Afirika.

Ọpọ awọn eeyan igberiko lo sọ pe awọn fẹràn iroyin abẹle ju iroyin ilẹ okeere lọ.

Iṣẹ iwadii ti Ọmọwe Lewis ṣe laarin ọdun 2015 si 2019 fihan pe ọpọ iroyin lori Star Times ko mẹnu ba Ibasepo China ati Afrika.

Lati ilumọọka si ipo tawọn eeyan o ka kun mọ

Eto lati mu tẹlifisan satalaiti de ẹgbẹrun mẹwaa abule l'Afirika ti jẹ ki Star Times di ilumọọka.

China ti tun n ṣe ipade mi pẹlu awọn olori orilẹede Afirika bayii.

Ọmọwe Madrid-Morales sọ pe owo ti China ti na lori eto yii ko yii so eso rere.

Ọpọ awọn olugbe igberiko ti BBC ba sọrọ lo fi aidunnu wọn han lori owo oṣooṣu ati maa wo Star Times.